SAMUẸLI KEJI 20
20
Ọ̀tẹ̀ Ṣeba
1Aláìníláárí ẹ̀dá kan wà ní ààrin àwọn ará Giligali tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikiri, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Ọkunrin yìí fọn fèrè, ó ní,
“Kò sí ohun tí ó kàn wá pẹlu Dafidi,
a kò sì ní ìpín nílé ọmọ Jese.
Ẹ pada sí ilé yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.”#1A. Ọba 12:16; 2Kron 10:16
2Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada lẹ́yìn Dafidi, wọ́n tẹ̀lé Ṣeba. Ṣugbọn àwọn eniyan Juda tẹ̀lé Dafidi, ọba wọn, pẹlu ẹ̀mí òtítọ́, láti odò Jọdani títí dé Jerusalẹmu.
3Nígbà tí Dafidi pada dé ààfin rẹ̀ ní Jerusalẹmu, ó mú àwọn obinrin rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó fi sílẹ̀, pé kí wọ́n máa tọ́jú ààfin, ó fi wọ́n sinu ilé kan pẹlu olùṣọ́, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún wọn, ṣugbọn kò bá wọn lòpọ̀ mọ́. Ninu ìhámọ́ ni wọ́n wà, tí wọ́n ń gbé bí opó, títí tí wọ́n fi kú.#2Sam 16:22
4Lẹ́yìn náà, ọba sọ fún Amasa pé, “Pe gbogbo àwọn ọkunrin Juda jọ, kí o sì kó wọn wá sọ́dọ̀ mi láàrin ọjọ́ mẹta; kí ìwọ náà sì wá.” 5Amasa bá lọ kó àwọn eniyan Juda jọ, ṣugbọn kò dé títí àkókò tí ọba dá fún un fi kọjá. 6Ọba bá pe Abiṣai, ó ní, “Ìyọnu tí Ṣeba yóo kó bá wa yóo ju ti Absalomu lọ. Nítorí náà, kó àwọn eniyan mi lẹ́yìn kí o sì máa lépa rẹ̀ lọ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè gba àwọn ìlú olódi bíi mélòó kan kí ó sì dá wahala sílẹ̀ fún wa.” 7Gbogbo àwọn ọmọ ogun Joabu, ati àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun yòókù, tí wọ́n kù ní Jerusalẹmu bá tẹ̀lé Abiṣai láti lépa Ṣeba. 8Nígbà tí wọ́n dé ibi òkúta ńlá kan, tí ó wà ní Gibeoni, Amasa lọ pàdé wọn. Ẹ̀wù ọmọ ogun ni Joabu wọ̀; ó sán ìgbànú kan, idà rẹ̀ sì wà ninu àkọ̀ lára ìgbànú tí ó ti sán mọ́ ìbàdí. Bí Joabu ti rìn siwaju bẹ́ẹ̀ ni idà yìí bọ́ sílẹ̀. 9Ó bá bèèrè lọ́wọ́ Amasa pé, “Ṣé alaafia ni, arakunrin mi?” Ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbá Amasa ní irùngbọ̀n mú, bí ẹni pé ó fẹ́ fi ẹnu kò ó ní ẹnu. 10Amasa kò fura rárá pé idà wà ní ọwọ́ Joabu. Joabu bá gún un ní idà níkùn, gbogbo ìfun rẹ̀ tú jáde. Amasa kú lẹsẹkẹsẹ, láì jẹ́ pé Joabu tún gún un ní idà lẹẹkeji.
Joabu ati Abiṣai arakunrin rẹ̀ bá ń lépa Ṣeba lọ. 11Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Joabu dúró ti òkú Amasa, ó sì ń kígbe pé, “Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ti Joabu ati ti Dafidi tẹ̀lé Joabu.” 12Òkú Amasa, tí ẹ̀jẹ̀ ti bò, wà ní ojú ọ̀nà gbangba, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń kọjá, tí ó bá rí i ń dúró. Nígbà tí ọkunrin tí ó dúró ti òkú náà rí i pé gbogbo eniyan ní ń dúró, ó wọ́ òkú náà kúrò lójú ọ̀nà, sinu igbó, ó sì fi aṣọ bò ó. 13Nígbà tí ó wọ́ ọ kúrò lójú ọ̀nà tán, gbogbo àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí sá tẹ̀lé Joabu, wọ́n ń lépa Ṣeba lọ.
14Ṣeba la ilẹ̀ gbogbo ẹ̀yà Israẹli já, ó lọ sí ìlú Abeli ti Beti Maaka. Gbogbo àwọn ará Bikiri bá péjọ, wọ́n sì tẹ̀lé e wọnú ìlú náà. 15Àwọn ọmọ ogun Joabu bá lọ dó ti ìlú náà, wọ́n fi erùpẹ̀ mọ òkítì gíga sára odi rẹ̀ lóde, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ́ odi náà lábẹ́, wọ́n fẹ́ wó o lulẹ̀. 16Obinrin ọlọ́gbọ́n kan wà ninu ìlú náà, tí ó kígbe láti orí odi, ó ní, “Ẹ tẹ́tí, ẹ gbọ́! Ẹ sọ fún Joabu kí ó wá gbọ́! Mo ní ọ̀rọ̀ kan tí mo fẹ́ bá a sọ.” 17Joabu bá lọ sibẹ. Obinrin náà bèèrè pé, “Ṣé ìwọ ni Joabu?”
Joabu dáhùn pé, “Èmi ni.”
Obinrin náà ní, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí èmi, iranṣẹbinrin rẹ fẹ́ sọ.”
Joabu dá a lóhùn pé, “Mò ń gbọ́.”
18Obinrin yìí ní, “Nígbà àtijọ́, wọn a máa wí pé, ‘Bí ọ̀rọ̀ kan bá ta kókó, ìlú Abeli ni wọ́n ti í rí ìtumọ̀ rẹ̀.’ Lóòótọ́ sì ni, ibẹ̀ gan-an ni wọ́n tií rí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀. 19Abeli jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ìlú tí ó fẹ́ alaafia, tí ó sì jẹ́ olóòótọ́ jùlọ ní Israẹli. Ṣé o wá fẹ́ pa ìlú tí ó jẹ́ ìyá ní Israẹli run ni? Kí ló dé tí o fi fẹ́ pa nǹkan OLUWA run?”
20Joabu dáhùn pé, “Rárá o! Kò sí ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀. Kì í ṣe ìlú yìí ni mo fẹ́ parun. 21Ọkunrin kan, tí ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikiri, láti agbègbè olókè ti Efuraimu, ni ó ń dìtẹ̀ mọ́ Dafidi ọba. Bí o bá ti fa òun nìkan ṣoṣo kalẹ̀, n óo kúrò ní ìlú yín.”
Obinrin yìí bá dáhùn pé, “A óo ju orí rẹ̀ sílẹ̀ sí ọ, láti orí odi.” 22Obinrin yìí bá tọ gbogbo àwọn ará ìlú lọ, ó sì fi ọgbọ́n bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n bá gé orí Ṣeba, wọ́n jù ú sí Joabu láti orí odi. Joabu bá fọn fèrè ogun, gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì fi ìlú náà sílẹ̀, wọ́n pada sí ilé. Joabu bá pada lọ sọ́dọ̀ ọba, ní Jerusalẹmu.
Àwọn Adarí Àwọn Òṣìṣẹ́ ní Ààfin Dafidi
23Joabu ni balogun àwọn ọmọ ogun ní Israẹli. Bẹnaya ọmọ Jehoiada sì ní olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba. 24Adoramu ni olórí àwọn tí wọ́n ń kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́. Jehoṣafati ọmọ Ahiludi ni olùtọ́jú àwọn àkọsílẹ̀ ní ààfin ọba. 25Ṣefa ni akọ̀wé gbọ̀ngàn ìdájọ́ rẹ̀. Sadoku ati Abiatari ni alufaa. 26Ira, ará ìlú Jairi náà jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn alufaa Dafidi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
SAMUẸLI KEJI 20: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010