II. Sam 2:12-32

II. Sam 2:12-32 Bibeli Mimọ (YBCV)

Abneri ọmọ Neri, ati awọn iranṣẹ Iṣboṣeti ọmọ Saulu si jade kuro ni Mahanaimu lọ si Gibeoni. Joabu ọmọ Seruia, ati awọn iranṣẹ Dafidi si jade, nwọn si jọ pade nibi adagun Gibeoni: nwọn si joko, ẹgbẹ kan li apa ihin adagun, ẹgbẹ keji li apa keji adagun. Abneri si wi fun Joabu pe, Jẹ ki awọn ọmọkunrin dide nisisiyi, ki nwọn ki o si ta pọrọ́ niwaju wa. Joabu si wipe, Jẹ ki wọn ki o dide. Nigbana li awọn mejila ninu ẹya Benjamini ti iṣe ti Iṣboṣeti ọmọ Saulu dide, nwọn si kọja siha keji; mejila ninu awọn ọmọ Dafidi si dide. Olukuluku wọn si di ọmọnikeji rẹ̀ li ori mu, olukuluku si tẹ idà rẹ̀ bọ ẹnikeji rẹ̀ ni ihà: nwọn si jọ ṣubu lulẹ: nitorina li a si ṣe npe orukọ ibẹ na ni Helkatihassurimu, ti o wà ni Gibeoni. Ijà na si kan gidigidi ni ijọ na, a si le Abneri ati awọn ọkunrin Israeli niwaju awọn ọmọ Dafidi. Awọn ọmọ Seruia mẹtẹta si mbẹ nibẹ, Joabu, Abiṣai, ati Asaheli: ẹsẹ Asaheli si fẹrẹ bi ẹsẹ agbọnrin ti o wà ni pápa. Asaheli si nlepa Abneri; bi on ti nlọ kò si yipada si ọwọ ọtun, tabi si ọwọ́ osì lati ma tọ Abneri lẹhin. Nigbana ni Abneri boju wo ẹhin rẹ̀, o si bere pe, Iwọ Asaheli ni? On si dahùn pe, Emi ni. Abneri si wi fun u pe, Iwọ yipada si apakan si ọwọ́ ọtun rẹ, tabi si osì rẹ, ki iwọ ki o si di ọkan mu ninu awọn ọmọkunrin, ki o si mu ihamọra rẹ̀. Ṣugbọn Asaheli kọ̀ lati pada lẹhin rẹ̀. Abneri si tun wi fun Asaheli pe, Pada lẹhin mi, ẽṣe ti emi o fi lu ọ bolẹ? bawo li emi o ti ṣe gbe oju soke si Joabu arakunrin rẹ? Ṣugbọn o si kọ̀ lati pada: Abneri si fi òdi ọ̀kọ gun u labẹ inu, ọ̀kọ na si jade li ẹhin rẹ̀: on si ṣubu lulẹ nibẹ, o si kú ni ibi kanna; o si ṣe, gbogbo enia ti o de ibiti Asaheli gbe ṣubu si, ti o si kú, si duro jẹ. Joabu ati Abiṣai si lepa Abneri: õrun si wọ̀, nwọn si de oke ti Amma ti o wà niwaju Gia li ọ̀na iju Gibeoni. Awọn ọmọ Benjamini si ko ara wọn jọ nwọn tẹle Abneri, nwọn si wa di ẹgbẹ kan, nwọn si duro lori oke kan. Abneri si pe Joabu, o si bi i lere pe, Idà yio ma parun titi lailai bi? njẹ iwọ kò iti mọ̀ pe yio koro nikẹhin? njẹ yio ha ti pẹ to ki iwọ ki o to sọ fun awọn enia na, ki nwọn ki o dẹkun lati ma lepa ará wọn? Joabu si wipe, Bi Ọlọrun ti mbẹ, bikoṣe bi iwọ ti wi, nitotọ, li owurọ̀ li awọn enia na iba ti goke lọ, olukuluku iba ti pada lẹhin arakunrin rẹ̀. Joabu si fún ipè, gbogbo enia si duro jẹ, nwọn kò si lepa Israeli mọ, bẹ̃ni nwọn kò si tun jà mọ. Abneri ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si fi gbogbo oru na rìn ni pẹtẹlẹ, nwọn si kọja Jordani, nwọn si rìn ni gbogbo Bitroni, nwọn si wá si Mahanaimu. Joabu si dẹkun ati ma tọ Abneri lẹhin: o si ko gbogbo awọn enia na jọ, enia mọkandi-logun li o kú pẹlu Asaheli ninu awọn iranṣẹ Dafidi. Ṣugbọn awọn iranṣẹ Dafidi si lù bolẹ ninu awọn enia Benjamini; ati ninu awọn ọmọkunrin Abneri; ojì-di-ni-irin-wo enia li o kú. Nwọn si gbe Asaheli, nwọn si sin i sinu ibojì baba rẹ̀ ti o wà ni Betlehemu. Joabu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ fi gbogbo oru na rin, ilẹ si mọ́ wọn si Hebroni.

II. Sam 2:12-32 Yoruba Bible (YCE)

Abineri ọmọ Neri ati àwọn iranṣẹ Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, ṣígun láti Mahanaimu, lọ sí ìlú Gibeoni. Joabu, tí orúkọ ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Seruaya, ati àwọn iranṣẹ Dafidi yòókù lọ pàdé wọn níbi adágún Gibeoni. Àwọn tí wọ́n tẹ̀lé Joabu jókòó sí ẹ̀gbẹ́ kan adágún náà, àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Abineri náà sì jókòó sí òdìkejì. Abineri bá sọ fún Joabu pé, “Jẹ́ kí àwọn bíi mélòó kan ninu àwọn ọmọkunrin láti ẹ̀gbẹ́ kinni keji bọ́ siwaju, kí wọ́n fi ohun ìjà dánrawò níwájú wa.” Joabu sì gbà bẹ́ẹ̀. Àwọn mejila bá jáde láti ẹ̀gbẹ́ kinni keji; àwọn mejila ẹ̀gbẹ́ kan dúró fún ẹ̀yà Bẹnjamini ati Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu, wọ́n sì bá àwọn iranṣẹ Dafidi mejila, tí wọ́n jáde láti inú ẹ̀yà Juda jà. Ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ẹ̀gbẹ́ kinni, dojú kọ ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ẹ̀gbẹ́ keji, wọ́n sì gbá ara wọn lórí mú. Ẹnìkínní ti idà rẹ̀ bọ ẹnìkejì rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́, àwọn mẹrẹẹrinlelogun ṣubú lulẹ̀, wọ́n sì kú. Ìdí nìyí tí wọ́n fi sọ ibẹ̀ ní Helikati-hasurimu. Ìtumọ̀ rẹ̀ ni “Pápá Idà”; ó wà ní Gibeoni. Ogun gbígbóná bẹ́ sílẹ̀ ní ọjọ́ náà, ṣugbọn àwọn eniyan Dafidi ṣẹgun Abineri ati àwọn eniyan Israẹli. Àwọn ọmọ Seruaya mẹtẹẹta, Joabu, Abiṣai, ati Asaheli, wà lójú ogun náà. Ẹsẹ̀ Asaheli yá nílẹ̀ pupọ, àfi bí ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín. Asaheli bẹ̀rẹ̀ sí lé Abineri lọ, bí ó sì ti ń lé e lọ, kò wo ọ̀tún, bẹ́ẹ̀ ni kò wo òsì. Abineri bá bojúwo ẹ̀yìn, ó bèèrè pé, “Asaheli, ṣé ìwọ ni ò ń lé mi?” Asaheli sì dá a lóhùn pé, “Èmi ni.” Abineri wí fún un pé, “Yà sí ọ̀tún, tabi sí òsì, kí o mú ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin, kí o sì kó gbogbo ìkógun rẹ̀.” Ṣugbọn Asaheli kọ̀, kò yipada kúrò lẹ́yìn rẹ̀. Abineri tún pe Asaheli, ó tún sọ fún un pé, “Pada lẹ́yìn mi, má jẹ́ kí n pa ọ́? Ojú wo ni o sì fẹ́ kí n fi wo Joabu ẹ̀gbọ́n rẹ?” Ṣugbọn Asaheli kọ̀, kò pada. Abineri bá sọ ọ̀kọ̀ ní àsọsẹ́yìn, ọ̀kọ̀ sì lọ bá Asaheli ní ikùn, ọ̀kọ̀ náà sì yọ jáde lẹ́yìn rẹ̀. Asaheli wó lulẹ̀, ó sì kú síbi tí ó ṣubú sí. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ti dé ibi tí Asaheli kú sí, ni wọ́n ń dúró. Ṣugbọn Joabu ati Abiṣai ń lé Abineri lọ, bí oòrùn ti ń lọ wọ̀, wọ́n dé ara òkè Ama tí ó wà níwájú Gia ní ọ̀nà aṣálẹ̀ Gibeoni. Àwọn ọmọ ogun yòókù láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini kó ara wọn jọ sẹ́yìn Abineri, wọ́n sì dúró káàkiri lórí òkè, pẹlu ìmúra ogun. Lẹ́yìn náà Abineri pe Joabu, ó ní, “Ṣé títí lae ni a óo máa ja ìjà yìí lọ ni? Àbí ìwọ náà kò rí i pé, bí a bá ja ogun yìí títí a fi pa ara wa tán, kò sí nǹkankan tí ẹnikẹ́ni yóo rí gbà, àfi ọ̀tá! Nígbà wo ni o fẹ́ dúró dà, kí o tó dá àwọn eniyan rẹ lẹ́kun pé kí wọ́n yé lépa àwọn arakunrin wọn?” Joabu bá dáhùn pé, “Ọlọrun mọ̀, bí o bá dákẹ́ tí o kò sọ̀rọ̀ ni, àwọn eniyan mi kì bá máa le yín lọ títí di òwúrọ̀ ọ̀la.” Joabu bá fọn fèrè ogun, láti fi pe àwọn eniyan rẹ̀ pada. Nígbà náà ni wọ́n tó pada lẹ́yìn àwọn eniyan Israẹli, tí wọ́n sì dáwọ́ ogun dúró. Gbogbo òru ọjọ́ náà ni Abineri ati àwọn eniyan rẹ̀ fi ń rìn pada lọ ní àfonífojì Jọdani, wọ́n kọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Gbogbo òwúrọ̀ ọjọ́ keji ni wọ́n sì fi rìn kí wọ́n tó pada dé Mahanaimu. Nígbà tí Joabu pada lẹ́yìn Abineri, tí ó sì kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ jọ, ó rí i pé, lẹ́yìn Asaheli, àwọn mejidinlogun ni wọn kò rí mọ́. Ṣugbọn àwọn eniyan Dafidi ti pa ọtalelọọdunrun (360) ninu àwọn eniyan Abineri. Joabu ati àwọn eniyan rẹ̀ bá gbé òkú Asaheli, wọ́n sì lọ sin ín sí ibojì ìdílé wọn ní Bẹtilẹhẹmu. Gbogbo òru ọjọ́ náà ni wọ́n fi rìn; ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ni wọ́n pada dé Heburoni.

II. Sam 2:12-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Abneri ọmọ Neri pẹ̀lú àwọn ọkùnrin ti Iṣboṣeti ọmọkùnrin Saulu kúrò ní Mahanaimu, wọ́n sì lọ sí Gibeoni. Joabu ọmọ Seruiah pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Dafidi jáde lọ láti lọ bá wọn ní adágún Gibeoni. Ẹgbẹ́ kan sì jókòó ní apá kan adágún, àti ẹgbẹ́ kejì ní apá kejì adágún. Nígbà náà, Abneri sọ fún Joabu pé, “Jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yìí ó dìde láti bá ara wọn jà níwájú wa.” Joabu sì dáhùn pé, “Ó dára, jẹ́ kí wọ́n ṣe é.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dìde sókè, a sì kà wọ́n sí ọkùnrin méjìlá fún Benjamini àti Iṣboṣeti ọmọ Saulu àti méjìlá fún Dafidi. Nígbà náà olúkúlùkù ọkùnrin gbá ẹnìkejì rẹ̀ mú ní orí, ó sì fi idà gún ẹnìkejì rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀ papọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ibẹ̀ ni Gibeoni ti à ń pè ni Helikatihu Hasurimu. Ogun náà ní ọjọ́ náà gbóná. Àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì ṣẹ́gun Abneri pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Israẹli. Àwọn ọmọkùnrin Seruiah mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni ó wà níbẹ̀: Joabu, Abiṣai àti Asaheli. Nísinsin yìí ẹsẹ̀ Asaheli sì fẹ́rẹ̀ bí ẹsẹ̀ èsúró tí ó wà ní pápá. Asaheli sì ń lépa Abneri, bí òun tí ń lọ kò sì yípadà sí ọ̀tún tàbí sí òsì láti máa tọ́ Abneri lẹ́yìn. Abneri bojú wo ẹ̀yìn rẹ̀, Ó sì béèrè pé, “Ṣé ìwọ Asaheli ni?” Ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” Nígbà náà, Abneri sọ fún un pé, “Yípadà sí ọ̀tún tàbí òsì; mú ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kí o sì bọ́ ìhámọ́ra rẹ.” Ṣùgbọ́n Asaheli kọ̀ láti dẹ́kun lílépa rẹ̀. Abneri tún kìlọ̀ fún Asaheli, “Dẹ́kun lílépa mi! Èéṣe tí èmi yóò fi lù ọ́ bolẹ̀? Báwo ni èmi yóò ti wo arákùnrin rẹ Joabu lójú?” Ṣùgbọ́n ó sí kọ̀ láti padà, Abneri sì fi òdì ọ̀kọ̀ gún un lábẹ́ inú, ọ̀kọ̀ náà sì jáde ní ẹ̀yìn rẹ̀: òun sì ṣubú lulẹ̀ níbẹ̀, ó sì kú ní ibi kan náà; ó sí ṣe gbogbo ènìyàn tí ó dé ibi tí Asaheli gbé ṣubú si, tí ó sì kú, sì dúró jẹ́. Joabu àti Abiṣai sì lépa Abneri: oòrùn sì wọ̀, wọ́n sì dé òkè ti Amima tí o wà níwájú Giah lọ́nà ijù Gibeoni. Àwọn ọmọ Benjamini sì kó ara wọn jọ wọ́n tẹ̀lé Abneri, wọ́n sì wá di ẹgbẹ́ kan, wọ́n sì dúró lórí òkè kan. Abneri sì pe Joabu, ó sì bi í léèrè pé, “Idà yóò máa parun títí láéláé bí? Ǹjẹ́ ìwọ kò ì tí ì mọ̀ pé yóò korò níkẹyìn? Ǹjẹ́ yóò ha ti pẹ́ tó kí ìwọ tó sọ fún àwọn ènìyàn náà, kí wọ́n dẹ́kun láti máa lépa arákùnrin wọn.” Joabu sì wí pé, “Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, bí kò ṣe bí ìwọ ti wí, nítòótọ́ ní òwúrọ̀ ni àwọn ènìyàn náà ìbá padà lẹ́yìn arákùnrin wọn.” Joabu sì fọ́n ìpè, gbogbo ènìyàn sì dúró jẹ́ẹ́, wọn kò sì lépa Israẹli mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì tún jà mọ́. Abneri àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì fi gbogbo òru náà rìn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì kọjá Jordani, wọ́n sì rìn ní gbogbo Bitironi, wọ́n sì wá sí Mahanaimu. Joabu sì dẹ́kun àti máa tọ Abneri lẹ́yìn: ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ, ènìyàn mọ́kàn-dínlógún ni ó kú pẹ̀lú Asaheli nínú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi. Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì pa nínú àwọn ènìyàn Benjamini: nínú àwọn ọmọkùnrin Abneri; òjì-dín-nírínwó ènìyàn. Wọ́n si gbé Asaheli wọ́n sì sin ín sínú ibojì baba rẹ̀ tí ó wà ní Bẹtilẹhẹmu. Joabu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ fi gbogbo òru náà rìn, ilẹ̀ sì mọ́ wọn sí Hebroni.