II. Sam 2

2
Wọ́n fi Dafidi Jọba Juda
1O si ṣe lẹhin eyi, Dafidi si bere lọwọ Oluwa, pe, Ki emi ki o goke lọ si ọkan ni ilu Juda wọnni bi? Oluwa si wi fun u pe, Goke lọ: Dafidi si wipe, niha ibo ni ki emi ki o lọ? On si wipe, Ni Hebroni.
2Dafidi si goke lọ si ibẹ ati awọn obinrin rẹ̀ mejeji pẹlu, Ahinoamu ara Jesreeli ati Abigaili obinrin Nabali ara Karmeli.
3Dafidi si mu awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti o wà lọdọ rẹ̀ goke, olukuluku ton ti ara ile rẹ̀: nwọn si joko ni ilu Hebroni wọnni.
4Awọn ọkunrin Juda si wá, nwọn si fi Dafidi jọba nibẹ lori ile Juda. Nwọn si sọ fun Dafidi pe, Awọn ọkunrin Jabeṣi Gileadi li o sinkú Saulu.
5Dafidi si ran onṣẹ si awọn ọkunrin Jabeṣi-Gileadi o si wi fun wọn pe, Alabukun fun li ẹnyin lati ọwọ́ Oluwa wá, bi ẹnyin ti ṣe õre yi si oluwa nyin, si Saulu, ani ti ẹ fi sinkú rẹ̀.
6Njẹ ki Oluwa ki o ṣe ore ati otitọ fun nyin: emi na yio si san ore yi fun nyin, nitori ti ẹnyin ṣe nkan yi.
7Njẹ ẹ si mu ọwọ́ nyin le, ki ẹ si jẹ ẹni-alagbara: nitoripe Saulu oluwa nyin ti kú, ile Juda si ti fi àmi-ororo yàn mi li ọba wọn.
Wọ́n fi Iṣiboṣẹti jọba Israẹli
8Ṣugbọn Abneri ọmọ Neri olori ogun Saulu si mu Iṣboṣeti ọmọ Saulu, o si mu u kọja si Mahanaimu;
9On si fi i jọba lori Gileadi, ati lori awọn ọmọ Aṣuri, ati lori Jesreeli, ati lori Efraimu, ati lori Benjamini, ati lori gbogbo Israeli.
10Iṣboṣeti ọmọ Saulu si jẹ ẹni ogoji ọdun nigbati o bẹrẹ si ijọba lori Israeli, o si jọba li ọdun meji. Ṣugbọn idile Juda ntọ̀ Dafidi lẹhin.
11Gbogbo ọjọ ti Dafidi fi jọba ni Hebroni lori ile Juda jẹ ọdun meje pẹlu oṣù mẹfa.
12Abneri ọmọ Neri, ati awọn iranṣẹ Iṣboṣeti ọmọ Saulu si jade kuro ni Mahanaimu lọ si Gibeoni.
13Joabu ọmọ Seruia, ati awọn iranṣẹ Dafidi si jade, nwọn si jọ pade nibi adagun Gibeoni: nwọn si joko, ẹgbẹ kan li apa ihin adagun, ẹgbẹ keji li apa keji adagun.
14Abneri si wi fun Joabu pe, Jẹ ki awọn ọmọkunrin dide nisisiyi, ki nwọn ki o si ta pọrọ́ niwaju wa. Joabu si wipe, Jẹ ki wọn ki o dide.
15Nigbana li awọn mejila ninu ẹya Benjamini ti iṣe ti Iṣboṣeti ọmọ Saulu dide, nwọn si kọja siha keji; mejila ninu awọn ọmọ Dafidi si dide.
16Olukuluku wọn si di ọmọnikeji rẹ̀ li ori mu, olukuluku si tẹ idà rẹ̀ bọ ẹnikeji rẹ̀ ni ihà: nwọn si jọ ṣubu lulẹ: nitorina li a si ṣe npe orukọ ibẹ na ni Helkatihassurimu, ti o wà ni Gibeoni.
17Ijà na si kan gidigidi ni ijọ na, a si le Abneri ati awọn ọkunrin Israeli niwaju awọn ọmọ Dafidi.
18Awọn ọmọ Seruia mẹtẹta si mbẹ nibẹ, Joabu, Abiṣai, ati Asaheli: ẹsẹ Asaheli si fẹrẹ bi ẹsẹ agbọnrin ti o wà ni pápa.
19Asaheli si nlepa Abneri; bi on ti nlọ kò si yipada si ọwọ ọtun, tabi si ọwọ́ osì lati ma tọ Abneri lẹhin.
20Nigbana ni Abneri boju wo ẹhin rẹ̀, o si bere pe, Iwọ Asaheli ni? On si dahùn pe, Emi ni.
21Abneri si wi fun u pe, Iwọ yipada si apakan si ọwọ́ ọtun rẹ, tabi si osì rẹ, ki iwọ ki o si di ọkan mu ninu awọn ọmọkunrin, ki o si mu ihamọra rẹ̀. Ṣugbọn Asaheli kọ̀ lati pada lẹhin rẹ̀.
22Abneri si tun wi fun Asaheli pe, Pada lẹhin mi, ẽṣe ti emi o fi lu ọ bolẹ? bawo li emi o ti ṣe gbe oju soke si Joabu arakunrin rẹ?
23Ṣugbọn o si kọ̀ lati pada: Abneri si fi òdi ọ̀kọ gun u labẹ inu, ọ̀kọ na si jade li ẹhin rẹ̀: on si ṣubu lulẹ nibẹ, o si kú ni ibi kanna; o si ṣe, gbogbo enia ti o de ibiti Asaheli gbe ṣubu si, ti o si kú, si duro jẹ.
24Joabu ati Abiṣai si lepa Abneri: õrun si wọ̀, nwọn si de oke ti Amma ti o wà niwaju Gia li ọ̀na iju Gibeoni.
25Awọn ọmọ Benjamini si ko ara wọn jọ nwọn tẹle Abneri, nwọn si wa di ẹgbẹ kan, nwọn si duro lori oke kan.
26Abneri si pe Joabu, o si bi i lere pe, Idà yio ma parun titi lailai bi? njẹ iwọ kò iti mọ̀ pe yio koro nikẹhin? njẹ yio ha ti pẹ to ki iwọ ki o to sọ fun awọn enia na, ki nwọn ki o dẹkun lati ma lepa ará wọn?
27Joabu si wipe, Bi Ọlọrun ti mbẹ, bikoṣe bi iwọ ti wi, nitotọ, li owurọ̀ li awọn enia na iba ti goke lọ, olukuluku iba ti pada lẹhin arakunrin rẹ̀.
28Joabu si fún ipè, gbogbo enia si duro jẹ, nwọn kò si lepa Israeli mọ, bẹ̃ni nwọn kò si tun jà mọ.
29Abneri ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si fi gbogbo oru na rìn ni pẹtẹlẹ, nwọn si kọja Jordani, nwọn si rìn ni gbogbo Bitroni, nwọn si wá si Mahanaimu.
30Joabu si dẹkun ati ma tọ Abneri lẹhin: o si ko gbogbo awọn enia na jọ, enia mọkandi-logun li o kú pẹlu Asaheli ninu awọn iranṣẹ Dafidi.
31Ṣugbọn awọn iranṣẹ Dafidi si lù bolẹ ninu awọn enia Benjamini; ati ninu awọn ọmọkunrin Abneri; ojì-di-ni-irin-wo enia li o kú.
32Nwọn si gbe Asaheli, nwọn si sin i sinu ibojì baba rẹ̀ ti o wà ni Betlehemu. Joabu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ fi gbogbo oru na rin, ilẹ si mọ́ wọn si Hebroni.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

II. Sam 2: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀