II. Sam 2:1-7
II. Sam 2:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe lẹhin eyi, Dafidi si bere lọwọ Oluwa, pe, Ki emi ki o goke lọ si ọkan ni ilu Juda wọnni bi? Oluwa si wi fun u pe, Goke lọ: Dafidi si wipe, niha ibo ni ki emi ki o lọ? On si wipe, Ni Hebroni. Dafidi si goke lọ si ibẹ ati awọn obinrin rẹ̀ mejeji pẹlu, Ahinoamu ara Jesreeli ati Abigaili obinrin Nabali ara Karmeli. Dafidi si mu awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti o wà lọdọ rẹ̀ goke, olukuluku ton ti ara ile rẹ̀: nwọn si joko ni ilu Hebroni wọnni. Awọn ọkunrin Juda si wá, nwọn si fi Dafidi jọba nibẹ lori ile Juda. Nwọn si sọ fun Dafidi pe, Awọn ọkunrin Jabeṣi Gileadi li o sinkú Saulu. Dafidi si ran onṣẹ si awọn ọkunrin Jabeṣi-Gileadi o si wi fun wọn pe, Alabukun fun li ẹnyin lati ọwọ́ Oluwa wá, bi ẹnyin ti ṣe õre yi si oluwa nyin, si Saulu, ani ti ẹ fi sinkú rẹ̀. Njẹ ki Oluwa ki o ṣe ore ati otitọ fun nyin: emi na yio si san ore yi fun nyin, nitori ti ẹnyin ṣe nkan yi. Njẹ ẹ si mu ọwọ́ nyin le, ki ẹ si jẹ ẹni-alagbara: nitoripe Saulu oluwa nyin ti kú, ile Juda si ti fi àmi-ororo yàn mi li ọba wọn.
II. Sam 2:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn èyí, Dafidi bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “OLUWA, ṣé kí ń lọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú Juda?” OLUWA sì dá a lóhùn pé, “Lọ.” Dafidi bá tún bèèrè pé, “Ìlú wo ni kí n lọ?” OLUWA ní, “Lọ sí ìlú Heburoni.” Dafidi bá mú àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji; Ahinoamu ará Jesireeli, ati Abigaili, opó Nabali, ará Kamẹli lọ́wọ́ lọ. Ó kó àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ pẹlu, ati gbogbo ìdílé wọn, wọ́n sì ń gbé àwọn ìlú tí wọ́n wà ní agbègbè Heburoni. Lẹ́yìn náà, àwọn ará Juda wá sí Heburoni, wọ́n fi òróró yan Dafidi ní ọba wọn. Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé àwọn ará Jabeṣi Gileadi ni wọ́n sin òkú Saulu, ó ranṣẹ sí wọn pé, “Kí OLUWA bukun yín nítorí pé ẹ ṣe olóòótọ́ sí Saulu ọba wa, ẹ sì sin òkú rẹ̀. Kí OLUWA fi ìfẹ́ ńlá ati òdodo rẹ̀ hàn fun yín. Èmi náà yóo ṣe yín dáradára, nítorí ohun tí ẹ ṣe yìí. Nítorí náà, ẹ mọ́kàn gírí kí ẹ sì ṣe akin; nítorí pé Saulu, oluwa yín ti kú, àwọn eniyan Juda sì ti fi òróró yàn mí gẹ́gẹ́ bí ọba wọn.”
II. Sam 2:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn àkókò yìí, Dafidi wádìí lọ́wọ́ OLúWA. Ó sì béèrè pé, “Ṣé èmi lè gòkè lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìlú Juda?” OLúWA sì wí pé, “Gòkè lọ.” Dafidi sì béèrè pé, “Ní ibo ni kí èmi kí ó lọ?” OLúWA sì dá a lóhùn pé, “Sí Hebroni.” Nígbà náà ni Dafidi gòkè lọ síbẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ méjì Ahinoamu ará Jesreeli, àti Abigaili obìnrin opó Nabali ti Karmeli. Dafidi sì mú àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, olúkúlùkù pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, wọ́n sì ń gbé ní Hebroni àti ìlú rẹ̀ mìíràn. Nígbà náà àwọn ọkùnrin ará Juda wá sí Hebroni, níbẹ̀ ni wọ́n ti fi ààmì òróró yan Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Juda. Nígbà tí wọ́n sọ fún Dafidi pé, àwọn ọkùnrin ti Jabesi Gileadi ni ó sin òkú Saulu, Dafidi rán oníṣẹ́ sí àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi láti sọ fún wọn pé, “OLúWA bùkún un yín fún fífi inú rere yín hàn sí Saulu ọ̀gá yín nípa sí sin ín. Kí OLúWA kí ó fi inú rere àti òtítọ́ fún un yín, èmi náà yóò sì san oore yìí fún un yín, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ mú ara yín le, kí ẹ sì ní ìgboyà, nítorí Saulu ọba yín ti kú, ilé Juda sì ti fi ààmì òróró yàn mí ní ọba lórí wọn.”