II. Sam 15:2-6
II. Sam 15:2-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Absalomu si dide ni kutukutu, o si duro li apakan ọ̀na ẹnu ibode: o si ṣe, bi ẹnikan ba ni ẹjọ ti o nfẹ mu tọ̀ ọba wá fun idajọ, a si pè e sọdọ rẹ̀, a si bi i pe, Ara ilu wo ni iwọ? on a si dahùn pe, Iranṣẹ rẹ ti inu ọkan ninu ẹya Israeli wá. Absalomu a si wi fun u pe Wõ, ọ̀ran rẹ sa dara, o si tọ: ṣugbọn ko si ẹnikan ti ọba fi aṣẹ fun lati yẹ ọ̀ran rẹ wò. Absalomu a si wipe, A ba jẹ fi mi ṣe onidajọ ni ilẹ yi! ki olukuluku ẹniti o ni ẹjọ tabi ọ̀ran kan ba le ma tọ̀ mi wa, emi iba si ṣe idajọ otitọ fun u. Bẹ̃ni bi ẹnikan ba si sunmọ ọ lati tẹriba fun u, on a si nawọ́ rẹ̀, a si dì i mu, a si fi ẹnu kò o li ẹnu. Iru iwà bayi ni Absalomu a ma hù si gbogbo Israeli ti o tọ̀ ọba wá nitori idajọ: Absalomu si fa ọkàn awọn enia Israeli sọdọ rẹ̀.
II. Sam 15:2-6 Yoruba Bible (YCE)
A máa jí ní òwúrọ̀ kutukutu, a sì dúró ní ẹ̀bá ọ̀nà, ní ẹnu ibodè ìlú. Nígbàkúùgbà tí ẹnikẹ́ni bá ń mú ẹjọ́ bọ̀ wá sọ́dọ̀ ọba, Absalomu á pe olúwarẹ̀ sọ́dọ̀, á bi í pé, “Níbo ni o ti wá?” Lẹ́yìn ìgbà tí ẹni náà bá sọ inú ẹ̀yà tí òun ti wá fún Absalomu tán, Absalomu á wí fún un pé, “Wò ó, ẹjọ́ rẹ tọ́, o sì jàre, ṣugbọn ọba kò yan ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí aṣojú rẹ̀, láti máa gbọ́ irú ẹjọ́ báyìí.” Absalomu á tún wá fi kún un pé, “A! Bí wọ́n bá fi mí ṣe adájọ́ ní ilẹ̀ yìí ni, bí ẹnikẹ́ni bá ní èdè-àìyedè kan pẹlu ẹlòmíràn, tabi tí ẹnìkan bá fẹ́ gba ohun tíí ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀, wọn ìbá máa tọ̀ mí wá, ǹ bá sì máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún wọn.” Bí ẹnikẹ́ni bá súnmọ́ Absalomu láti wólẹ̀, kí ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, Absalomu á tètè na ọwọ́ sí i, á gbá a mú, a sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu. Bẹ́ẹ̀ ni Absalomu máa ń ṣe sí gbogbo àwọn eniyan Israẹli, tí wọ́n bá kó ẹjọ́ wá sọ́dọ̀ ọba. Nítorí bí ó ti ń ṣe yìí, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n fẹ́ràn rẹ̀.
II. Sam 15:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Absalomu sì dìde ní kùtùkùtù, ó sì dúró ní apá kan ọ̀nà ẹnu ibodè: bí ẹnìkan bá ní ẹjọ́ tí ó ń fẹ́ mú tọ ọba wá fún ìdájọ́, a sì pè é sọ́dọ̀ rẹ̀, a sì bi í pé, “Ará ìlú wo ni ìwọ?” Òun a sì dáhùn pé, “ìránṣẹ́ rẹ ti inú ọ̀kan nínú ẹ̀yà Israẹli wá.” Absalomu yóò sì wí fún un pé, “Wò ó, ọ̀ràn rẹ ṣá dára, ó sì tọ́: ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ọba fi àṣẹ fún láti gbọ́ ọ̀ràn rẹ.” Absalomu a sì wí pé, “À bá jẹ́ fi mi ṣe onídàájọ́ ní ilẹ̀ yìí! Kí olúkúlùkù ẹni tí ó ní ẹjọ́ tàbí ọ̀ràn kan bá à lè máa tọ̀ mí wá, èmi ìbá sì ṣe ìdájọ́ òtítọ́ fún un.” Bẹ́ẹ̀ ni bí ẹnìkan bá sì súnmọ́ láti tẹríba fún un, òun a sì nawọ́ rẹ̀, a sì dìímú, a sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu. Irú ìwà báyìí ni Absalomu a máa hù sí gbogbo Israẹli tí ó tọ́ ọba wá nítorí ìdájọ́: Absalomu sì fi fa ọkàn àwọn ènìyàn Israẹli sọ́dọ̀ rẹ̀.