II. Sam 15:13-17
II. Sam 15:13-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnikan si wá rò fun Dafidi pe, Ọkàn awọn ọkunrin Israeli ṣi si Absalomu. Dafidi si wi fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o wà lọdọ rẹ̀ ni Jerusalemu pe, Ẹ dide, ẹ jẹ ki a salọ, nitoripe kò si ẹniti yio gbà wa lọwọ Absalomu: ẹ yara, ki a lọ kuro, ki on má ba yara le wa ba, ki o má si mu ibi ba wa, ki o má si fi oju idà pa ilu run. Awọn iranṣẹ ọba si wi fun ọba pe, Gẹgẹ bi gbogbo eyi ti oluwa wa ọba nfẹ, wõ, awa iranṣẹ rẹ ti mura. Ọba si jade, gbogbo ile rẹ̀ si tẹle e. Ọba si fi mẹwa ninu awọn obinrin rẹ̀ silẹ lati ma ṣọ ile. Ọba si jade, gbogbo enia si tẹle e, nwọn si duro ni ibikan ti o jina.
II. Sam 15:13-17 Yoruba Bible (YCE)
Oníṣẹ́ kan wá ròyìn fún Dafidi pé, “Ọkàn gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ti ṣí sí ọ̀dọ̀ Absalomu.” Dafidi bá sọ fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Jerusalẹmu pé, “A gbọdọ̀ sá lọ lẹsẹkẹsẹ, bí a kò bá fẹ́ bọ́ sọ́wọ́ Absalomu. Ẹ ṣe gírí, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo bá wa, yóo ṣẹgun wa, yóo sì pa ìlú yìí run.” Àwọn iranṣẹ rẹ̀ dáhùn pé, “Kabiyesi, ohunkohun tí o bá wí ni a óo ṣe.” Ọba bá jáde kúrò ní ìlú, gbogbo ìdílé rẹ̀, ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ṣugbọn ọba fi mẹ́wàá ninu àwọn obinrin rẹ̀ sílẹ̀ láti máa bojútó ààfin. Bí ọba ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ ti ń jáde kúrò ní ìlú, wọ́n dúró níbi ilé tí ó wà ní ìpẹ̀kun ìlú.
II. Sam 15:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹnìkan sì wá rò fún Dafidi pé, “Ọkàn àwọn ọkùnrin Israẹli ṣí sí Absalomu.” Dafidi sì wí fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wá lọ́dọ̀ rẹ̀ ni Jerusalẹmu pé, “Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a sálọ, nítorí pé kò sí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ Absalomu; ẹ yára, kí a lọ kúrò, kí òun má bá à yára lé wa bá, kí ó má sì mú ibi bá wa, kí ó má sì fi ojú idà pa ìlú run.” Àwọn ìránṣẹ́ ọba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí olúwa wa ọba ń fẹ́, wò ó, àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ti murá.” Ọba sì jáde, gbogbo ilé rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ọba sì fì mẹ́wàá nínú àwọn obìnrin rẹ̀ sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé. Ọba sì jáde, gbogbo ènìyàn sì tẹ̀lé e, wọ́n sì dúró ní ibìkan tí ó jìnnà.