II. Sam 15:13-14
II. Sam 15:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnikan si wá rò fun Dafidi pe, Ọkàn awọn ọkunrin Israeli ṣi si Absalomu. Dafidi si wi fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o wà lọdọ rẹ̀ ni Jerusalemu pe, Ẹ dide, ẹ jẹ ki a salọ, nitoripe kò si ẹniti yio gbà wa lọwọ Absalomu: ẹ yara, ki a lọ kuro, ki on má ba yara le wa ba, ki o má si mu ibi ba wa, ki o má si fi oju idà pa ilu run.
II. Sam 15:13-14 Yoruba Bible (YCE)
Oníṣẹ́ kan wá ròyìn fún Dafidi pé, “Ọkàn gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ti ṣí sí ọ̀dọ̀ Absalomu.” Dafidi bá sọ fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Jerusalẹmu pé, “A gbọdọ̀ sá lọ lẹsẹkẹsẹ, bí a kò bá fẹ́ bọ́ sọ́wọ́ Absalomu. Ẹ ṣe gírí, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo bá wa, yóo ṣẹgun wa, yóo sì pa ìlú yìí run.”
II. Sam 15:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹnìkan sì wá rò fún Dafidi pé, “Ọkàn àwọn ọkùnrin Israẹli ṣí sí Absalomu.” Dafidi sì wí fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó wá lọ́dọ̀ rẹ̀ ni Jerusalẹmu pé, “Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a sálọ, nítorí pé kò sí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ Absalomu; ẹ yára, kí a lọ kúrò, kí òun má bá à yára lé wa bá, kí ó má sì mú ibi bá wa, kí ó má sì fi ojú idà pa ìlú run.”