II. A. Ọba 6:15-23

II. A. Ọba 6:15-23 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigbati iranṣẹ enia Ọlọrun na si dide ni kùtukutu ti o si jade lọ, wõ, ogun yi ilu na ka, ati ẹṣin ati kẹkẹ́. Iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Yẽ! baba mi, awa o ti ṣe? On si dahùn wipe, Má bẹ̀ru: nitori awọn ti o wà pẹlu wa, jù awọn ti o wà pẹlu wọn lọ. Eliṣa si gbadura, o si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, là a li oju, ki o lè riran. Oluwa si là oju ọdọmọkunrin na; on si riran: si wò o, òke na kún fun ẹṣin ati kẹkẹ́-iná yi Eliṣa ka. Nigbati nwọn si sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá, Eliṣa gbadura si Oluwa, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, bù ifọju lù awọn enia yi. On si bù ifọju lù wọn gẹgẹ bi ọ̀rọ Eliṣa. Eliṣa si wi fun wọn pe, Eyi kì iṣe ọ̀na, bẹ̃ni eyi kì iṣe ilu na: ẹ ma tọ̀ mi lẹhin, emi o si mu nyin wá ọdọ ọkunrin ti ẹnyin nwá. O si ṣe amọ̀na wọn lọ si Samaria. O si ṣe, nigbati nwọn de Samaria ni Eliṣa wipe, Oluwa la oju awọn enia wọnyi, ki nwọn ki o lè riran. Oluwa si là oju wọn; nwọn si riran; si kiyesi i, nwọn mbẹ li ãrin Samaria. Ọba Israeli si wi fun Eliṣa, nigbati o ri wọn pe, Baba mi, ki emi ki o mã pa wọn bi? ki emi ki o mã pa wọn bi? On si dahùn pe, Iwọ kò gbọdọ pa wọn: iwọ jẹ pa awọn ti iwọ fi idà rẹ ati ọrun rẹ kó ni igbèkun? Gbe onjẹ ati omi kalẹ niwaju wọn, ki nwọn ki o jẹ, ki nwọn ki o si mu, ki nwọn ki o si tọ̀ oluwa wọn lọ. On si pèse ọ̀pọlọpọ onjẹ fun wọn; nigbati nwọn si ti jẹ, ti nwọn si ti mu tan, o rán wọn lọ, nwọn si tọ̀ oluwa wọn lọ. Bẹ̃ni ẹgbẹ́ ogun Siria kò tun wá si ilẹ Israeli mọ.

II. A. Ọba 6:15-23 Yoruba Bible (YCE)

Ní òwúrọ̀ kutukutu, nígbà tí iranṣẹ Eliṣa jáde sí ìta, ó rí i pé àwọn ọmọ ogun Siria ti yí ìlú náà po pẹlu ẹṣin ati àwọn kẹ̀kẹ́-ogun. Ó pada wọlé tọ Eliṣa lọ, ó sì kígbe pé, “Yéè, oluwa mi, kí ni a óo ṣe?” Eliṣa dáhùn pé, “Má bẹ̀rù nítorí pé àwọn tí wọ́n wà pẹlu wa ju àwọn tí wọ́n wà pẹlu wọn lọ.” Eliṣa bá gbadura pé kí OLUWA jọ̀wọ́ ṣí ojú rẹ̀, kí ó lè ríran. OLUWA ṣí iranṣẹ náà lójú, ó sì rí i pé gbogbo orí òkè náà kún fún ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun, iná sí yí Eliṣa ká. Nígbà tí àwọn ará Siria gbìyànjú láti mú un, ó gbadura pé kí OLUWA jọ̀wọ́ fọ́ àwọn ọkunrin náà lójú. OLUWA sì fọ́ wọn lójú gẹ́gẹ́ bí adura Eliṣa. Eliṣa tọ̀ wọ́n lọ, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ti ṣìnà; èyí kì í ṣe ìlú tí ẹ̀ ń wá, ẹ tẹ̀lé mi n óo fi ẹni tí ẹ̀ ń wá hàn yín.” Ó sì mú wọn lọ sí Samaria. Ní kété tí wọ́n wọ Samaria, Eliṣa gbadura pé kí OLUWA ṣí wọn lójú kí wọ́n lè ríran. OLUWA sì ṣí wọn lójú, wọ́n rí i pé ààrin Samaria ni àwọn wà. Nígbà tí ọba Israẹli rí wọn, ó bi Eliṣa pé, “Ṣé kí n pa wọ́n, oluwa mi, ṣé kí n pa wọ́n?” Eliṣa dáhùn pé, “O kò gbọdọ̀ pa wọ́n, ṣé o máa pa àwọn tí o bá kó lójú ogun ni? Gbé oúnjẹ ati omi kalẹ̀ níwájú wọn, kí wọ́n jẹ, kí wọ́n mu, kí wọ́n sì pada sọ́dọ̀ oluwa wọn.” Nítorí náà, ọba Israẹli pèsè oúnjẹ fún wọn lọpọlọpọ. Lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ, tí wọ́n sì ti mu, wọ́n pada sọ́dọ̀ oluwa wọn. Láti ọjọ́ náà ni àwọn ọmọ ogun Siria kò ti gbógun ti ilẹ̀ Israẹli mọ́.

II. A. Ọba 6:15-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run dìde ó sì jáde lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, ogun pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ wọn ti yí ìlú náà ká. “Yé è, olúwa mi! Kí ni kí àwa kí ó ṣe?” ìránṣẹ́ náà béèrè. “Má ṣe bẹ̀rù,” wòlíì náà dáhùn, “Àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa, wọ́n pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.” Eliṣa sì gbàdúrà, “OLúWA, la ojú rẹ̀ kí ó ba à lè ríran.” Nígbà náà OLúWA la ojú ìránṣẹ́ náà, ó sì wò, ó sì rí òkè ńlá tí ó kún fún ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ iná gbogbo yí Eliṣa ká. Bí àwọn ọ̀tá ṣe ń sọ̀kalẹ̀ wá níwájú rẹ, Eliṣa gbàdúrà sí OLúWA pé. “Bu ìfọ́jú lu àwọn ènìyàn wọ̀nyí,” OLúWA sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti béèrè. Eliṣa sọ fún wọn pé “Èyí kì í ṣe ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ni èyí kì í ṣe ìlú náà. Tẹ̀lé mi, èmi yóò mú u yín lọ sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin tí ẹ̀yin ń wá.” Ó sì sìn wọ́n lọ sí Samaria. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n wọ ìlú náà, Eliṣa wí pé, “OLúWA, la ojú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kí wọn kí ó lè ríran.” Nígbà náà OLúWA la ojú wọn, wọ́n sì ríran, wọ́n sì wà níbẹ̀, nínú Samaria. Nígbà tí ọba Israẹli rí wọn, ó béèrè lọ́wọ́ Eliṣa pé, “Ṣé kí èmi kí ó pa wọ́n, Baba mi? Ṣé kí èmi kí ó pa wọ́n?” “Má ṣe pa wọ́n,” ó dáhùn. “Ṣé ìwọ yóò pa àwọn ọkùnrin tí ìwọ mú pẹ̀lú idà rẹ tàbí ọrun rẹ? Gbé oúnjẹ àti omi síwájú wọn kí wọn kí ó lè jẹ kí wọn sì mu, nígbà náà kí wọn padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn.” Bẹ́ẹ̀ ni ó pèsè àsè ńlá fún wọn, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ tí wọ́n mu, ó sì rán wọn lọ, wọ́n sì padà sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ẹgbẹ́ láti Aramu dáwọ́ ìgbógunti ilẹ̀ Israẹli dúró.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa