II. A. Ọba 6:13-17
II. A. Ọba 6:13-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
On si wipe, Ẹ lọ iwò ibi ti on gbe wà, ki emi o le ranṣẹ lọ mu u wá. A si sọ fun u, wipe, Wò o, o wà ni Dotani. Nitorina li o ṣe rán awọn ẹṣin ati kẹkẹ́ ati ogun nla sibẹ: nwọn si de li oru, nwọn si yi ilu na ka. Nigbati iranṣẹ enia Ọlọrun na si dide ni kùtukutu ti o si jade lọ, wõ, ogun yi ilu na ka, ati ẹṣin ati kẹkẹ́. Iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Yẽ! baba mi, awa o ti ṣe? On si dahùn wipe, Má bẹ̀ru: nitori awọn ti o wà pẹlu wa, jù awọn ti o wà pẹlu wọn lọ. Eliṣa si gbadura, o si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, là a li oju, ki o lè riran. Oluwa si là oju ọdọmọkunrin na; on si riran: si wò o, òke na kún fun ẹṣin ati kẹkẹ́-iná yi Eliṣa ka.
II. A. Ọba 6:13-17 Yoruba Bible (YCE)
Ọba bá pàṣẹ pé, “Ẹ lọ wádìí ibi tí ó ń gbé, kí n lè ranṣẹ lọ mú un.” Nígbà tí wọ́n sọ fún un pé Eliṣa wà ní Dotani, ó rán ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun ati ẹṣin ati kẹ̀kẹ́-ogun lọ sibẹ. Ní òru ni wọ́n dé ìlú náà, wọ́n sì yí i po. Ní òwúrọ̀ kutukutu, nígbà tí iranṣẹ Eliṣa jáde sí ìta, ó rí i pé àwọn ọmọ ogun Siria ti yí ìlú náà po pẹlu ẹṣin ati àwọn kẹ̀kẹ́-ogun. Ó pada wọlé tọ Eliṣa lọ, ó sì kígbe pé, “Yéè, oluwa mi, kí ni a óo ṣe?” Eliṣa dáhùn pé, “Má bẹ̀rù nítorí pé àwọn tí wọ́n wà pẹlu wa ju àwọn tí wọ́n wà pẹlu wọn lọ.” Eliṣa bá gbadura pé kí OLUWA jọ̀wọ́ ṣí ojú rẹ̀, kí ó lè ríran. OLUWA ṣí iranṣẹ náà lójú, ó sì rí i pé gbogbo orí òkè náà kún fún ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun, iná sí yí Eliṣa ká.
II. A. Ọba 6:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Lọ, kí ẹ lọ wo ibi tí ó wà,” ọba pa á láṣẹ, “Kí èmi kí ó lè rán ènìyàn láti lọ mú un wá.” Ìròyìn padà wá. “Ó wà ní Dotani.” Nígbà náà ni ó rán àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ àti ogun ńlá tí ó le síbẹ̀. Wọ́n sì lọ ní alẹ́ wọ́n sì yí ìlú náà ká. Nígbà tí ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run dìde ó sì jáde lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, ogun pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ wọn ti yí ìlú náà ká. “Yé è, olúwa mi! Kí ni kí àwa kí ó ṣe?” ìránṣẹ́ náà béèrè. “Má ṣe bẹ̀rù,” wòlíì náà dáhùn, “Àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa, wọ́n pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.” Eliṣa sì gbàdúrà, “OLúWA, la ojú rẹ̀ kí ó ba à lè ríran.” Nígbà náà OLúWA la ojú ìránṣẹ́ náà, ó sì wò, ó sì rí òkè ńlá tí ó kún fún ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ iná gbogbo yí Eliṣa ká.