II. A. Ọba 4:1-17
II. A. Ọba 4:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
OBIRIN kan ninu awọn obinrin ọmọ awọn woli ke ba Eliṣa wipe, Iranṣẹ rẹ, ọkọ mi kú; iwọ si mọ̀ pe iranṣẹ rẹ bẹ̀ru Oluwa: awọn onigbèse si wá lati mu awọn ọmọ mi mejeji li ẹrú. Eliṣa si wi fun u pe, Kini emi o ṣe fun ọ? Wi fun mi, kini iwọ ni ninu ile? On si wipe, Iranṣẹbinrin rẹ kò ni nkankan ni ile, bikòṣe ikòko ororo kan. On si wipe, Lọ, ki iwọ ki o yá ikòko lọwọ awọn aladugbò rẹ kakiri, ani ikòko ofo; yá wọn, kì iṣe diẹ. Nigbati iwọ ba si wọle, ki iwọ ki o se ilẹ̀kun mọ ara rẹ, ati mọ awọn ọmọ rẹ, ki o si dà a sinu gbogbo ikòko wọnni, ki iwọ ki o si fi eyiti o kún si apakan. O si lọ kuro lọdọ rẹ̀, o si se ilẹ̀kun mọ ara rẹ̀ ati mọ awọn ọmọ rẹ̀, ti ngbe ikòko fun u wá; on si dà a. O si ṣe, nigbati awọn ikòko kún, o wi fun ọmọ rẹ̀ pe, Tun mu ikòko kan fun mi wá. On si wi fun u pe, Kò si ikòko kan mọ. Ororo na si da. Nigbana li o wá, o si sọ fun enia Ọlọrun na. On si wipe, Lọ, tà ororo na, ki o si san gbèse rẹ, ki iwọ ati awọn ọmọ rẹ ki o si jẹ eyi ti o kù. O si di ọjọ kan, Eliṣa si kọja si Ṣunemu, nibiti obinrin ọlọla kan wà; on si rọ̀ ọ lati jẹ onjẹ. O si ṣe, nigbakugba ti o ba nkọja lọ, on a yà si ibẹ lati jẹ onjẹ. On si wi fun ọkọ rẹ̀ pe, Sa wò o na, emi woye pe, enia mimọ́ Ọlọrun li eyi ti ngbà ọdọ wa kọja nigbakugba. Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki a ṣe yàrá kekere kan lara ogiri; si jẹ ki a gbe ibùsùn kan sibẹ fun u, ati tabili kan, ati ohun-ijoko kan, ati ọpá-fitila kan: yio si ṣe, nigbati o ba tọ̀ wa wá, ki on ma wọ̀ sibẹ. O si di ọjọ kan, ti o wá ibẹ̀, o si yà sinu yàrá na, o si dubulẹ nibẹ. On si wi fun Gehasi iranṣẹ rẹ̀ pe, Pè ara Ṣunemu yi. Nigbati o si pè e, o duro niwaju rẹ̀. On si wi fun u pe, nisisiyi, sọ fun u pe, Kiyesi i, iwọ ti fi gbogbo itọju yi ṣe aniyàn wa; kini a ba ṣe fun ọ? Iwọ nfẹ́ ki a sọ̀rọ rẹ fun ọba bi? tabi fun olori-ogun? On si dahùn wipe, Emi ngbe lãrin awọn enia mi. On si wipe, Njẹ kini a ba ṣe fun u? Gehasi si dahùn pe, Nitõtọ, on kò li ọmọ, ọkọ rẹ̀ si di arugbo. On si wipe, Pè e wá, nigbati o si ti pè e de, o duro li ẹnu-ọ̀na. On si wipe, Li akokò yi gẹgẹ bi igba aiye, iwọ gbé ọmọkunrin kan mọra. On si wipe, Bẹ̃kọ̀, oluwa mi, iwọ enia Ọlọrun, má ṣe purọ fun iranṣẹbinrin rẹ. Obinrin na si loyun, o si bi ọmọkunrin kan li akokò na ti Eliṣa ti sọ fun u, gẹgẹ bi igba aiye.

II. A. Ọba 4:1-17 Yoruba Bible (YCE)
Iyawo ọ̀kan ninu àwọn ọmọ àwọn wolii tọ Eliṣa lọ, ó sì sọ fún un pé, “Olúwa mi, iranṣẹ rẹ, ọkọ mi, ti kú, gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀, ó jẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù OLUWA nígbà ayé rẹ̀. Ẹnìkan tí ó jẹ lówó kí ó tó kú fẹ́ kó àwọn ọmọkunrin mi mejeeji lẹ́rú, nítorí gbèsè baba wọn.” Eliṣa bèèrè pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ? Sọ ohun tí o ní nílé fún mi.” Obinrin náà dáhùn pé, “N kò ní ohunkohun, àfi ìkòkò òróró kan.” Eliṣa sọ fún un pé, “Lọ yá ọpọlọpọ ìkòkò lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò rẹ. Lẹ́yìn náà, kí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ wọlé, nígbà tí ẹ bá sì ti ti ìlẹ̀kùn yín tán, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí da òróró náà sinu àwọn ìkòkò náà, kí ẹ sì máa gbé wọn sí ẹ̀gbẹ́ kan bí wọ́n bá ti ń kún.” Obinrin náà lọ sinu ilé rẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n sì ti ìlẹ̀kùn wọn; ó bá bẹ̀rẹ̀ sí da òróró náà sinu àwọn ìkòkò náà bí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ń gbé wọn wá. Nígbà tí gbogbo àwọn ìkòkò náà kún, obinrin náà bèèrè bóyá ìkòkò kù, àwọn ọmọ rẹ̀ sì dáhùn pé ó ti tán, òróró náà sì dá. Ó bá pada lọ sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wolii Eliṣa. Eliṣa wí fún un pé, “Lọ ta àwọn òróró náà kí o sì san gbèsè rẹ ninu rẹ̀, kí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ máa ná ìyókù.” Ní ọjọ́ kan Eliṣa lọ sí Ṣunemu, níbi tí obinrin ọlọ́rọ̀ kan ń gbé; obinrin náà sì pe Eliṣa wọlé kí ó wá jẹun. Láti ìgbà náà, ilé obinrin yìí ni Eliṣa ti máa ń jẹun ní Ṣunemu. Obinrin náà sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Mo wòye pé ọkunrin tí ó ń wá síbí yìí jẹ́ ẹni mímọ́ Ọlọ́run. Jẹ́ kí á ṣe yàrá kékeré kan sí òkè ilé wa, kí á gbé ibùsùn, tabili, àga ati fìtílà sibẹ, kí ó lè máa dé sibẹ nígbàkúùgbà tí ó bá wá síbí.” Ní ọjọ́ kan tí Eliṣa pada lọ sí Ṣunemu, ó wọ inú yàrá náà lọ láti sinmi. Ó bá rán Gehasi iranṣẹ rẹ̀ kí ó pe obinrin náà wá. Nígbà tí ó wọlé ó dúró níwájú Eliṣa. Eliṣa sọ fún Gehasi kí ó bèèrè lọ́wọ́ obinrin náà ohun tí ó fẹ́ kí òun ṣe fún un, fún gbogbo nǹkan tí ó ti ṣe fún àwọn. Ó ní, bóyá ó fẹ́ kí òun sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ọba ni tabi fún balogun? Obinrin náà dáhùn pé ààrin àwọn eniyan òun ni òun ń gbé. Eliṣa bá bèèrè lọ́wọ́ Gehasi pé, “Kí ni mo lè ṣe fún un nígbà náà?” Gehasi ní, “Kò bímọ, ọkọ rẹ̀ sì ti di arúgbó.” Eliṣa bá rán Gehasi kí ó pe obinrin náà wá. Nígbà tí ó dé, ó dúró ní ẹnu ọ̀nà. Eliṣa sọ fún un pé, “Níwòyí àmọ́dún, o óo fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọkunrin.” Obinrin náà dáhùn pé, “Háà! Oluwa mi, eniyan Ọlọrun ni ọ́, nítorí náà má ṣe parọ́ fún iranṣẹbinrin rẹ.” Ṣugbọn obinrin náà lóyún ó sì bí ọmọkunrin ní akoko náà ní ọdún tí ó tẹ̀lé e gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Eliṣa.
II. A. Ọba 4:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìyàwó ọkùnrin kan láti ara ẹgbẹ́ wòlíì sọkún tọ Eliṣa wá, “Ìránṣẹ́ rẹ ọkọ mi ti kú, ó sì mọ̀ wí pé ó bu ọlá fún OLúWA. Ṣùgbọ́n Nísinsin yìí onígbèsè rẹ̀ ti ń bọ̀ láti wá kó ọmọ ọkùnrin mi gẹ́gẹ́ bí ẹrú rẹ̀.” Eliṣa dá a lóhùn pé, “Báwo ni èmi ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́? Sọ fún mi; kí ni ìwọ ní ní ilé rẹ?” “Ìránṣẹ́ rẹ kò ní ohunkóhun níbẹ̀ rárá,” Ó wí pé, “àyàfi òróró kékeré.” Eliṣa wí pé, “Lọ yíká kí o sì béèrè lọ́wọ́ gbogbo àwọn aládùúgbò fún ìkòkò òfìfo. Má ṣe béèrè fún kékeré. Nígbà náà, lọ sí inú ilé kí o sì pa lẹ́kun dé ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin, dà òróró sínú gbogbo ìkòkò, gẹ́gẹ́ bí gbogbo rẹ̀ ti kún, kó o sí apá kan.” Ó sì fi sílẹ̀ lẹ́yìn náà ó ti ìlẹ̀kùn ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n gbé ìkòkò wá fún un ó sì ń dà á. Nígbà tí gbogbo ìkòkò náà kún, ó sọ fún ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ gbé òmíràn fún mi wá.” Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Kò sí ìkòkò tí ó kù mọ́.” Nígbà náà ni òróró kò dà mọ́. Ó sì lọ ó sì lọ sọ fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ó sì wí pé, “Lọ, ta òróró náà kí o sì san gbèsè rẹ. Ìwọ àti ọmọ rẹ kí ẹ máa sinmi lórí èyí tí ó kù.” Ní ọjọ́ kan Eliṣa lọ sí Ṣunemu. Obìnrin ọlọ́rọ̀ kan sì wà níbẹ̀, ẹni tí ó rọ̀ ọ́ kí ó dúró jẹun. Bẹ́ẹ̀ ni nígbàkúgbà tí ó bá ń kọjá lọ, ó máa ń dúró níbẹ̀ láti jẹun. Ó sọ fún ọkọ rẹ̀, “Mo mọ̀ pé ọkùnrin tí ó máa ń sábà wá sí ọ̀dọ̀ wa jẹ́ ọkùnrin mímọ́ Ọlọ́run. Jẹ́ kí a ṣe yàrá kékeré kan sórí ilé kí a sì gbé ibùsùn àti tábìlì oúnjẹ, àga kan àti fìtílà fún un. Nígbà náà ó lè dúró níbẹ̀ ní ìgbàkúgbà tí ó bá wá sọ́dọ̀ wa.” Ní ọjọ́ kan nígbà tí Eliṣa wá, ó lọ sí orí òkè ní yàrá rẹ̀ ó sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀. Ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Gehasi pé, “Pe ará Ṣunemu.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é wá, ó sì dúró níwájú rẹ̀. Eliṣa wí fún un pé, “wí fún un, ‘Ìwọ ti lọ ṣe gbogbo àníyàn iṣẹ́ ìhìnrere fún wa. Nísinsin yìí kí ni a lè ṣe fún ọ?’ ” “Ṣé a lè jẹ́ agbẹnusọ fún ọ ní ọ̀dọ̀ ọba tàbí olórí ogun?” “Kí ni a lè ṣe fún obìnrin yìí?” Eliṣa béèrè. Gehasi wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kò ní ọmọ, ọkọ rẹ̀ náà sì tún di arúgbó.” Nígbà náà Eliṣa wí pé, “Pè é,” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é, ó sì dúró ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà. Eliṣa sọ wí pé, “Ìwòyí ọdún tí ń bọ̀, ìwọ yóò fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọ.” “Bẹ́ẹ̀ kọ́, olúwa mi!” n kò fi ara mọ́ ọn. “Jọ̀wọ́, ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, ma ṣe ṣi ìránṣẹ́ rẹ lọ́nà!” Ṣùgbọ́n obìnrin náà lóyún ní ọdún kejì ní àkókò náà, ó bí ọmọ ọkùnrin kan, gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti sọ fún un.