2 Ọba 4:1-17

2 Ọba 4:1-17 YCB

Ìyàwó ọkùnrin kan láti ara ẹgbẹ́ wòlíì sọkún tọ Eliṣa wá, “Ìránṣẹ́ rẹ ọkọ mi ti kú, ó sì mọ̀ wí pé ó bu ọlá fún OLúWA. Ṣùgbọ́n Nísinsin yìí onígbèsè rẹ̀ ti ń bọ̀ láti wá kó ọmọ ọkùnrin mi gẹ́gẹ́ bí ẹrú rẹ̀.” Eliṣa dá a lóhùn pé, “Báwo ni èmi ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́? Sọ fún mi; kí ni ìwọ ní ní ilé rẹ?” “Ìránṣẹ́ rẹ kò ní ohunkóhun níbẹ̀ rárá,” Ó wí pé, “àyàfi òróró kékeré.” Eliṣa wí pé, “Lọ yíká kí o sì béèrè lọ́wọ́ gbogbo àwọn aládùúgbò fún ìkòkò òfìfo. Má ṣe béèrè fún kékeré. Nígbà náà, lọ sí inú ilé kí o sì pa lẹ́kun dé ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin, dà òróró sínú gbogbo ìkòkò, gẹ́gẹ́ bí gbogbo rẹ̀ ti kún, kó o sí apá kan.” Ó sì fi sílẹ̀ lẹ́yìn náà ó ti ìlẹ̀kùn ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n gbé ìkòkò wá fún un ó sì ń dà á. Nígbà tí gbogbo ìkòkò náà kún, ó sọ fún ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ gbé òmíràn fún mi wá.” Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Kò sí ìkòkò tí ó kù mọ́.” Nígbà náà ni òróró kò dà mọ́. Ó sì lọ ó sì lọ sọ fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ó sì wí pé, “Lọ, ta òróró náà kí o sì san gbèsè rẹ. Ìwọ àti ọmọ rẹ kí ẹ máa sinmi lórí èyí tí ó kù.” Ní ọjọ́ kan Eliṣa lọ sí Ṣunemu. Obìnrin ọlọ́rọ̀ kan sì wà níbẹ̀, ẹni tí ó rọ̀ ọ́ kí ó dúró jẹun. Bẹ́ẹ̀ ni nígbàkúgbà tí ó bá ń kọjá lọ, ó máa ń dúró níbẹ̀ láti jẹun. Ó sọ fún ọkọ rẹ̀, “Mo mọ̀ pé ọkùnrin tí ó máa ń sábà wá sí ọ̀dọ̀ wa jẹ́ ọkùnrin mímọ́ Ọlọ́run. Jẹ́ kí a ṣe yàrá kékeré kan sórí ilé kí a sì gbé ibùsùn àti tábìlì oúnjẹ, àga kan àti fìtílà fún un. Nígbà náà ó lè dúró níbẹ̀ ní ìgbàkúgbà tí ó bá wá sọ́dọ̀ wa.” Ní ọjọ́ kan nígbà tí Eliṣa wá, ó lọ sí orí òkè ní yàrá rẹ̀ ó sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀. Ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Gehasi pé, “Pe ará Ṣunemu.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é wá, ó sì dúró níwájú rẹ̀. Eliṣa wí fún un pé, “wí fún un, ‘Ìwọ ti lọ ṣe gbogbo àníyàn iṣẹ́ ìhìnrere fún wa. Nísinsin yìí kí ni a lè ṣe fún ọ?’ ” “Ṣé a lè jẹ́ agbẹnusọ fún ọ ní ọ̀dọ̀ ọba tàbí olórí ogun?” “Kí ni a lè ṣe fún obìnrin yìí?” Eliṣa béèrè. Gehasi wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kò ní ọmọ, ọkọ rẹ̀ náà sì tún di arúgbó.” Nígbà náà Eliṣa wí pé, “Pè é,” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é, ó sì dúró ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà. Eliṣa sọ wí pé, “Ìwòyí ọdún tí ń bọ̀, ìwọ yóò fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọ.” “Bẹ́ẹ̀ kọ́, olúwa mi!” n kò fi ara mọ́ ọn. “Jọ̀wọ́, ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, ma ṣe ṣi ìránṣẹ́ rẹ lọ́nà!” Ṣùgbọ́n obìnrin náà lóyún ní ọdún kejì ní àkókò náà, ó bí ọmọ ọkùnrin kan, gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti sọ fún un.