II. A. Ọba 19:8-13
II. A. Ọba 19:8-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃ni Rabṣake pada, o si ba ọba Assiria mba Libna jagun: nitoriti o ti gbọ́ pe o ti lọ kuro ni Lakiṣi. Nigbati o si gburo Tirhaka ọba Etiopia, pe, Kiyesi i, o jade wá lati ba ọ jagun; o si tun rán awọn onṣẹ si ọdọ Hesekiah wipe, Bayi li ẹnyin o sọ fun Hesekiah ọba Juda, wipe, Máṣe jẹ ki Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ gbẹkẹle ki o tàn ọ jẹ, wipe, A kì yio fi Jerusalemu le ọwọ ọba Assiria. Kiyesi i, iwọ ti gbọ́ ohun ti awọn ọba Assiria ti ṣe si gbogbo ilẹ, ni pipa wọn run patapata: a o ha si gbà iwọ bi? Oriṣa awọn orilẹ-ède ha gbà awọn ti awọn baba mi ti parun; bi Gosani, ati Harani, ati Resefu, ati awọn ọmọ Edeni ti o wà ni Telassari? Nibo li ọba Hamati, ati ọba Arpadi, ati ọba ilu Sefarfaimu, ti Hena, ati Ifa gbe wà?
II. A. Ọba 19:8-13 Yoruba Bible (YCE)
Rabuṣake gbọ́ pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi láti lọ jagun ní Libina, ó sì lọ sibẹ láti lọ rí i. Nígbà tí ọba Asiria gbọ́ pé Tirihaka, ọba Etiopia, ń kó ogun rẹ̀ bọ̀ láti bá òun jagun, ó ranṣẹ sí Hesekaya, ọba Juda, ó ní kí wọ́n sọ fún un pé, “Má jẹ́ kí Ọlọrun tí o gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ pé ọba Asiria kò ní fi ogun kó Jerusalẹmu. O ti gbọ́ ìròyìn ohun tí ọba Asiria ti ṣe sí àwọn tí ó ti bá jagun, pé ó pa wọ́n run patapata ni. Ṣé ìwọ rò pé o lè là? Àwọn baba ńlá mi ti pa àwọn ìlú Gosani, Harani, Resefu ati àwọn ọmọ Edẹni tí wọ́n wà ní Telasari run, àwọn ọlọrun wọn kò sì lè gbà wọ́n. Níbo ni ọba Hamati, ati ti Aripadi, ati ti Sefafaimu, ati ti Hena, ati ti Ifa wà?”
II. A. Ọba 19:8-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí olùdarí pápá gbọ́ wí pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi ó sì padà ó sì rí ọba níbi ti ó gbé ń bá Libina jà. Nísinsin yìí Sennakeribu sì gbọ́ ìròyìn wí pé Tirakah, ọba Etiopia ti Ejibiti wá ó sì ń yan jáde lọ láti lọ bá a jagun. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tún rán oníṣẹ́ sí Hesekiah pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí pé: “Sọ fún Hesekiah ọba Juda pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé kí ó tàn ó jẹ nígbà tí ó wí pé, ‘Jerusalẹmu a kò ní fi lé ọwọ́ ọba Asiria.’ Lóòótọ́ ìwọ ti gbọ́ gbogbo ohun tí ọba Asiria tí ó ṣe sí gbogbo àwọn ìlú, ó pa wọ́n run pátápátá. Ìwọ yóò sì gbàlà? Ṣé àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè tí a ti parun láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá mi gbà wọ́n là: òrìṣà Gosani, Harani Reṣefu àti gbogbo ènìyàn Edeni tí wọ́n wà ní Teli-Assari? Níbo ni ọba Hamati wa, ọba Arpadi, ọba ìlú Sefarfaimi, ti Hena, tàbí ti Iffa gbé wà?”