ÀWỌN ỌBA KEJI 19

19
Ọba Bèèrè Ìmọ̀ràn Lọ́wọ́ Aisaya
(Ais 37:1-7)
1Nígbà tí Hesekaya ọba gbọ́, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó bá lọ sinu ilé OLUWA. 2Ó rán Eliakimu ati Ṣebina ati àwọn àgbààgbà alufaa, tí wọ́n fi aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara wọn, lọ sọ́dọ̀ wolii Aisaya ọmọ Amosi. 3Wọ́n sì jíṣẹ́ Hesekaya ọba fún Aisaya pé, “Ọba sọ pé òní jẹ́ ọjọ́ ìrora, wọ́n ń fi ìyà jẹ wá, a sì wà ninu ìtìjú. A dàbí aboyún tí ó fẹ́ bímọ ṣugbọn tí kò ní agbára tó. 4Ọba Asiria ti rán Rabuṣake, olórí ogun rẹ̀ kan, láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí Ọlọrun alààyè. Kí OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn yìí, kí ó sì jẹ àwọn tí wọ́n sọ ọ́ níyà. Nítorí náà, gbadura fún àwọn eniyan wa tí wọ́n kù.”
5Nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ ọba fún Aisaya tán, 6ó ranṣẹ pada ó ní, “Ẹ sọ fún ọ̀gá yín pé OLUWA ní kí ó má jẹ́ kí iṣẹ́ tí ọba Asiria rán sí i pé OLUWA kò lè gbà á dẹ́rùbà á. 7Ó ní òun óo fi ẹ̀mí kan sinu rẹ̀, tí yóo mú kí ó sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ nígbà tí ó bá gbọ́ ìròyìn kan, òun óo sì jẹ́ kí wọ́n pa á nígbà tí ó bá dé ilẹ̀ rẹ̀.”
Àwọn Ará Asiria Tún Ranṣẹ Ìhàlẹ̀ Mìíràn
(Ais 37:8-20)
8Rabuṣake gbọ́ pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi láti lọ jagun ní Libina, ó sì lọ sibẹ láti lọ rí i. 9Nígbà tí ọba Asiria gbọ́ pé Tirihaka, ọba Etiopia, ń kó ogun rẹ̀ bọ̀ láti bá òun jagun, ó ranṣẹ sí Hesekaya, ọba Juda, ó ní kí wọ́n sọ fún un pé, 10“Má jẹ́ kí Ọlọrun tí o gbẹ́kẹ̀lé tàn ọ́ jẹ pé ọba Asiria kò ní fi ogun kó Jerusalẹmu. 11O ti gbọ́ ìròyìn ohun tí ọba Asiria ti ṣe sí àwọn tí ó ti bá jagun, pé ó pa wọ́n run patapata ni. Ṣé ìwọ rò pé o lè là? 12Àwọn baba ńlá mi ti pa àwọn ìlú Gosani, Harani, Resefu ati àwọn ọmọ Edẹni tí wọ́n wà ní Telasari run, àwọn ọlọrun wọn kò sì lè gbà wọ́n. 13Níbo ni ọba Hamati, ati ti Aripadi, ati ti Sefafaimu, ati ti Hena, ati ti Ifa wà?”
14Hesekaya ọba gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn iranṣẹ, ó kà á. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ilé OLUWA, ó tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú OLUWA. 15Ó gbadura pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ń gbé láàrin àwọn Kerubu, ìwọ nìkan ni Ọlọrun tí ń jọba lórí gbogbo ilẹ̀ ayé, ìwọ ni o dá ayé ati ọ̀run.#Eks 25:22 16Nisinsinyii, bojú wo ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wa; kí o sì gbọ́ bí Senakeribu ti ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ìwọ Ọlọrun alààyè. 17OLUWA, àwa mọ̀ pé ní òtítọ́ ni ọba Asiria ti pa ọpọlọpọ àwọn orílẹ̀-èdè run, ó sì ti sọ ilẹ̀ wọn di aṣálẹ̀. 18Ó ti dáná sun àwọn ọlọrun wọn; ṣugbọn wọn kì í ṣe Ọlọrun tòótọ́, ère lásán tí a fi igi ati òkúta gbẹ́ ni wọ́n, iṣẹ́ ọwọ́ ọmọ eniyan. 19Nisinsinyii OLUWA Ọlọrun wa, jọ̀wọ́ gbà wá lọ́wọ́ Asiria kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé lè mọ̀ pé ìwọ OLUWA nìkan ni ỌLỌRUN.”
Iṣẹ́ Tí Aisaya Rán sí Ọba
(Ais 37:21-38)
20Nígbà náà ni Aisaya ọmọ Amosi ranṣẹ sí Hesekaya ọba pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní: Mo ti gbọ́ adura rẹ nípa Senakeribu, ọba Asiria. 21Ohun tí OLUWA sọ nípa Senakeribu ni pé,
‘Sioni yóo fi ojú tẹmbẹlu rẹ,
yóo sì fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà;
Jerusalẹmu yóo fi ọ́ rẹ́rìn-ín.’
22Ta ni o rò pé ò ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí,
tí o sì fi ń ṣe ẹlẹ́yà?
Ta ni ò ń kígbe mọ́,
tí o sì ń wò ní ìwò ìgbéraga?
Èmi Ẹni Mímọ́ Israẹli ni!
23O rán oníṣẹ́ rẹ láti fi OLUWA ṣe ẹlẹ́yà,
o ní, ‘N óo fi ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun mi ṣẹgun àwọn òkè,
títí dé òkè tí ó ga jùlọ ní Lẹbanoni;
mo gé àwọn igi Kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀,
ati àwọn igi sipirẹsi rẹ̀ tí ó dára jùlọ,
Mo wọ inú igbó rẹ̀ tí ó jìnnà ju lọ,
mo sì wọ inú aṣálẹ̀ rẹ̀ tí ó dí jùlọ.
24Mo gbẹ́ kànga ní ilẹ̀ àjèjì,
mo sì mu omi rẹ̀;
ẹsẹ̀ àwọn jagunjagun mi ni ó sì gbẹ́ àwọn odò Ijipti.’
25“Ṣé o kò mọ̀ pé
ó pẹ́ tí mo ti pinnu àwọn nǹkan tí ó ń ṣẹlẹ̀ wọnyi ni?
Èmi ni mo fún ọ ní agbára
tí o fi sọ àwọn ìlú olódi di òkítì àlàpà.
26Nítorí náà ni àwọn tí wọn ń gbé inú àwọn ìlú olódi náà ṣe di aláìlágbára,
tí ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.
Wọ́n dàbí ìgbà tí atẹ́gùn gbígbóná ìlà oòrùn
bá fẹ́ lu koríko tabi ewéko tí ó hù ní orí òrùlé.
27Ṣugbọn kò sí ohun tí n kò mọ̀ nípa rẹ,
mo mọ àtijókòó rẹ, àtijáde rẹ
ati àtiwọlé rẹ, ati bí o ti ń ta kò mí.
28Mo ti gbọ́ ìròyìn ibinu rẹ ati ìgbéraga rẹ,
n óo fi ìwọ̀ kọ́ ọ nímú, n óo fi ìjánu bọ̀ ọ́ lẹ́nu,
n óo sì fà ọ́ pada sí ibi tí o ti wá.”
29Nígbà náà ni Aisaya sọ fún Hesekaya ọba pé, “Ohun tí yóo jẹ́ àmì fún ọ nípa àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ nìyí. Ní ọdún yìí ati ọdún tí ń bọ̀, ẹ óo jẹ àjàrà tí ó lalẹ̀ hù, ṣugbọn ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, ẹ óo le gbin ohun ọ̀gbìn yín, ẹ óo sì kórè rẹ̀, ẹ óo gbin ọgbà àjàrà, ẹ óo sì jẹ èso àjàrà rẹ̀. 30Yóo dára fún àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Juda. Wọn yóo dàbí irúgbìn tí gbòǹgbò rẹ̀ wọnú ilẹ̀ lọ tí ó sì ń so èso jáde. 31Àwọn eniyan yóo là ní Jerusalẹmu, àwọn eniyan yóo sì ṣẹ́kù ni Òkè Sioni, nítorí pé ìtara ni OLUWA yóo fi ṣe é.
32“Ohun tí OLUWA sọ nípa ọba Asiria ni pé, kò ní wọ inú ìlú yìí, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ta ọfà kankan sí i. Kò sí ọmọ ogun kan tí ó ní apata tí yóo wá sí ẹ̀bá ìlú náà, bẹ́ẹ̀ ni kò ní lè gbìyànjú láti gbógun tì í. 33Ọ̀nà tí ó gbà wá ni yóo gbà lọ láìwọ ìlú yìí nítorí èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. 34N óo gbèjà ìlú yìí, n óo sì dáàbò bò ọ́ nítorí ògo mi ati ìlérí tí mo ti ṣe fún Dafidi iranṣẹ mi.”
35Ní alẹ́ ọjọ́ náà ni angẹli OLUWA lọ sí ibùdó ogun Asiria, ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹsan-an lé ẹẹdẹgbaata (185,000) àwọn ọmọ ogun, wọn kú kí ilẹ̀ ọjọ́ keji tó mọ́. 36Senakeribu ọba Asiria bá pada sí Ninefe. 37Ní ọjọ́ kan níbi tí ó ti ń bọ oriṣa ninu ilé Nisiroku, oriṣa rẹ̀, ni Adirameleki ati Ṣareseri, àwọn ọmọ rẹ̀ bá fi idà pa á, wọ́n sì sá lọ sí ilẹ̀ Ararati. Esaradoni ọmọ rẹ̀ bá jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÀWỌN ỌBA KEJI 19: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀