II. A. Ọba 10:1-31
II. A. Ọba 10:1-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
AHABU si ni ãdọrin ọmọ ọkunrin ni Samaria. Jehu si kọwe, o si ranṣẹ si Samaria si awọn olori Jesreeli, si awọn àgbagba, ati si awọn ti ntọ́ awọn ọmọ Ahabu, wipe, Njẹ nisisiyi nigbati iwe yi ba ti de ọdọ nyin, bi o ti jẹpe, awọn ọmọ oluwa nyin mbẹ lọdọ nyin, ati kẹkẹ́ ati ẹṣin mbẹ lọdọ nyin, ilu olodi pẹlu ati ihamọra. Ki ẹ wò ẹniti o sàn jùlọ ati ti o si yẹ jùlọ ninu awọn ọmọ oluwa nyin, ki ẹ gbé e ka ori-itẹ́ baba rẹ̀, ki ẹ si jà fun ile oluwa nyin. Ṣugbọn ẹ̀ru bà wọn gidigidi, nwọn si wipe, Kiyesi i, ọba meji kò duro niwaju rẹ̀: awa o ha ti ṣe le duro? Ati ẹniti iṣe olori ile, ati ẹniti iṣe olori ilu, awọn àgbagba pẹlu, ati awọn olutọ́ awọn ọmọ, ranṣẹ si Jehu wipe, Iranṣẹ rẹ li awa, a o si ṣe gbogbo ohun ti o ba pa li aṣẹ fun wa; awa kì yio jẹ ọba: iwọ ṣe eyi ti o dara li oju rẹ. Nigbana ni o kọ iwe lẹrinkeji si wọn wipe, Bi ẹnyin ba ṣe ti emi, bi ẹnyin o si fi eti si ohùn mi, ẹ mu ori awọn ọkunrin na, awọn ọmọ oluwa nyin, ki ẹ si tọ̀ mi wá ni Jesreeli ni iwòyi ọla. Njẹ awọn ọmọ ọba, ãdọrin ọkunrin, mbẹ pẹlu awọn enia nla ilu na ti ntọ́ wọn. O si ṣe, nigbati iwe na de ọdọ wọn, ni nwọn mu awọn ọmọ ọba, nwọn si pa ãdọrin ọkunrin, nwọn si kó ori wọn sinu agbọ̀n, nwọn si fi wọn ranṣẹ si i ni Jesreeli. Onṣẹ kan si de, o si sọ fun u, wipe, nwọn ti mu ori awọn ọmọ ọba wá. On si wipe, Ẹ tò wọn li okiti meji ni atiwọ̀ ẹnu bodè, titi di owurọ̀. O si ṣe li owurọ̀, o si jade lọ, o si duro, o si wi fun gbogbo awọn enia pe, Olododo li ẹnyin: kiyesi i, emi ṣọ̀tẹ si oluwa mi, mo si pa a: ṣugbọn tani pa gbogbo awọn wọnyi? Njẹ ẹ mọ̀ pe, kò si ohunkan ninu ọ̀rọ Oluwa, ti Oluwa sọ niti ile Ahabu ti yio bọ́ silẹ, nitori ti Oluwa ti ṣe eyi ti o ti sọ nipa ọwọ Elijah iranṣẹ rẹ̀. Bẹ̃ni Jehu pa gbogbo awọn ti o kù ni ile Ahabu ni Jesreeli ati gbogbo awọn enia nla rẹ̀, ati awọn ibatan rẹ̀, ati awọn alufa rẹ̀, titi on kò fi kù ọkan silẹ fun u. On si dide, o si mbọ̀ o si wá si Samaria: bi o si ti wà nibi ile irẹ́run agutan li oju ọ̀na. Jehu pade awọn arakunrin Ahasiah ọba Juda, o si wipe, Tali ẹnyin? Nwọn si dahùn wipe, Awa arakunrin Ahasiah ni; awa si nsọ̀kalẹ lati lọ ikí awọn ọmọ ọba ati awọn ọmọ ayaba. On si wipe, Ẹ mu wọn lãyè, nwọn si mu wọn lãyè, nwọn si pa wọn nibi iho ile irẹ́run agùtan, ani ọkunrin mejilelogoji, bẹ̃ni kò si kù ẹnikan wọn. Nigbati o si jade nibẹ, o ri Jehonadabu ọmọ Rekabu mbọ̀wá ipade rẹ̀; o si sure fun u, o si wi fun u pe, Ọkàn rẹ ha ṣe dede bi ọkàn mi ti ri si ọkàn rẹ? Jehonadabu si dahùn wipe, Bẹ̃ni. Bi bẹ̃ni, njẹ fun mi li ọwọ rẹ. O si fun u li ọwọ rẹ̀; on si fà a sọdọ rẹ̀ sinu kẹkẹ́. On si wipe, Ba mi lọ ki o si wò itara mi fun Oluwa. Bẹ̃ni nwọn mu u gùn kẹkẹ́ rẹ̀. Nigbati o si de Samaria, o pa gbogbo awọn ti o kù fun Ahabu ni Samaria, titi o fi run u, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa ti o sọ fun Elijah. Jehu si kó gbogbo awọn enia jọ, o si wi fun wọn pe, Ahabu sìn Baali diẹ, ṣugbọn Jehu yio sìn i pupọ. Njẹ nitorina, ẹ pè gbogbo awọn woli Baali fun mi, gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati gbogbo awọn alufa rẹ̀; máṣe jẹ ki ọkan ki o kù; nitoriti mo ni ẹbọ nla iṣe si Baali: ẹnikẹni ti o ba kù, kì yio yè. Ṣugbọn Jehu fi ẹ̀tan ṣe e, nitori ki o le pa awọn olùsin Baali run. Jehu si wipe, Ẹ yà apejọ si mimọ́ fun Baali; nwọn si kede rẹ̀. Jehu si ranṣẹ si gbogbo Israeli; gbogbo awọn olùsin Baali si wá tobẹ̃ ti kò si kù ọkunrin kan ti kò wá. Nwọn si wá sinu ile Baali; ile Baali si kún lati ikangun ekini titi de ekeji. On si wi fun ẹniti o wà lori yará babaloriṣa pe, Kó aṣọ wá fun gbogbo awọn olùsin Baali. On si kó aṣọ jade fun wọn wá. Jehu si lọ, ati Jehonadabu ọmọ Rekabu sinu ile Baali, o si wi fun awọn olùsin Baali pe, Ẹ wá kiri, ki ẹ si wò ki ẹnikan ninu awọn iranṣẹ Oluwa ki o má si pẹlu nyin nihin, bikòṣe kìki awọn olùsin Baali. Nigbati nwọn si wọle lati ru ẹbọ ati ọrẹ-sisun, Jehu yàn ọgọrin ọkunrin si ode, o si wipe, Bi ẹnikan ninu awọn ọkunrin ti mo mu wá fi le nyin lọwọ ba lọ, ẹniti o ba jẹ ki o lọ, ẹmi rẹ̀ yio lọ fun ẹmi tirẹ̀. O si ṣe, bi a si ti pari ati ru ẹbọ sisun, ni Jehu wi fun awọn olùṣọ ati awọn olori-ogun pe, Wọle, ki ẹ si pa wọn; ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o jade. Nwọn si fi oju idà pa wọn; awọn olùṣọ ati awọn olori-ogun si gbé wọn sọ si ode, nwọn si wọ̀ inu odi ile Baali. Nwọn si kó awọn ere lati ile Baali jade, nwọn si sun wọn. Nwọn si wo ere Baali lulẹ, nwọn si wo ile Baali lulẹ, nwọn si ṣe e ni ile igbẹ́ titi di oni yi. Bayi ni Jehu pa Baali run kuro ni Israeli. Ṣugbọn Jehu kò kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ti o mu Israeli ṣẹ̀, eyinì ni, awọn ẹgbọ̀rọ malu wura ti o wà ni Beteli, ati eyiti o wà ni Dani. Oluwa si wi fun Jehu pe, Nitoriti iwọ ti ṣe rere ni ṣiṣe eyi ti o tọ́ li oju mi, ti o si ti ṣe si ile Ahabu gẹgẹ bi gbogbo eyiti o wà li ọkàn mi, awọn ọmọ rẹ iran kẹrin yio joko lori itẹ Israeli. Ṣugbọn Jehu kò ṣe akiyesi lati ma fi gbogbo ọkàn rẹ̀ rin ninu ofin Oluwa Ọlọrun Israeli: nitoriti kò yà kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ti o mu Israeli ṣẹ̀.

II. A. Ọba 10:1-31 Yoruba Bible (YCE)
Ahabu ní aadọrin ọmọkunrin tí wọn ń gbé Samaria. Jehu kọ ìwé ranṣẹ sí àwọn olórí ìlú ati àwọn àgbààgbà ati àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu, ó ní: “Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ọba, ẹ sì ní àwọn kẹ̀kẹ́ ogun, ẹṣin, ati àwọn ohun ìjà ati àwọn ìlú olódi ní ìkáwọ́ yín. Nítorí náà, ní kété tí ẹ bá gba ìwé yìí, ẹ fi èyí tí ó bá jẹ́ akọni jùlọ lára àwọn ọmọ ọba sí orí oyè, ẹ sì múra láti jà fún ilẹ̀ oluwa yín.” Ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n ní, “Ǹjẹ́ àwa lè bá Jehu, ẹni tí ó ṣẹgun ọba meji jà?” Nítorí náà, ẹni tí ó ń ṣe ìtọ́jú ààfin ati olórí ìlú pẹlu àwọn àgbààgbà ati àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu ranṣẹ sí Jehu, wọ́n ní: “Iranṣẹ rẹ ni wá, a sì ti ṣetán láti ṣe ohunkohun tí o bá pa láṣẹ. A kò ní fi ẹnikẹ́ni sórí oyè, ṣe ohunkohun tí o bá rò pé ó dára.” Jehu tún kọ ìwé mìíràn sí wọn, ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé ẹ wà lẹ́yìn mi, ẹ sì ṣetán láti tẹ̀lé àṣẹ mi, ẹ kó orí àwọn ọmọ ọba Ahabu wá fún mi ní Jesireeli ní àkókò yìí ní ọ̀la.” Àwọn aadọrin ọmọ Ahabu náà wà ní abẹ́ ìtọ́jú àwọn àgbààgbà ìlú Samaria. Nígbà tí wọ́n rí ìwé Jehu gbà, àwọn olórí Samaria pa gbogbo àwọn ọmọ Ahabu, wọ́n sì kó orí wọn sinu apẹ̀rẹ̀ lọ fún Jehu ní Jesireeli. Nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ fún Jehu pé wọ́n ti kó orí àwọn ọmọ Ahabu dé, ó pàṣẹ pé kí wọ́n kó wọn jọ sí ọ̀nà meji ní ẹnubodè ìlú, títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Jehu lọ sí ẹnubodè ìlú, ó sì sọ fún àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ pé, “Ẹ kò ní ẹ̀bi, èmi ni mo ṣọ̀tẹ̀ sí Joramu ọba, oluwa mi, tí mo sì pa á. Ṣugbọn ta ni ó pa àwọn wọnyi? Èyí fihàn dájú pé gbogbo ohun tí OLUWA sọ nípa ìdílé Ahabu yóo ṣẹ. OLUWA ti ṣe ohun tí ó ṣèlérí láti ẹnu Elija, wolii rẹ̀.” Jehu pa gbogbo àwọn ìbátan Ahabu tí wọn ń gbé Jesireeli ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ati àwọn alufaa; kò dá ọ̀kan ninu wọn sí. Jehu kúrò ní Jesireeli, ó ń lọ sí Samaria. Nígbà tí ó dé ibìkan tí wọ́n ń pè ní Bẹtekedi, níbi tí àwọn olùṣọ́ aguntan ti máa ń rẹ́ irun aguntan, ó pàdé àwọn ìbátan Ahasaya, ọba Juda, ó bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni yín?” Wọ́n dáhùn pé, “Ìbátan Ahasaya ni wá. Jesireeli ni à ń lọ láti lọ kí àwọn ọmọ ọba ati àwọn ìdílé ọba.” Jehu pàṣẹ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mú wọn láàyè. Wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n sì pa wọ́n ní ibi kòtò tí ó wà ní Bẹtekedi. Gbogbo wọn jẹ́ mejilelogoji, kò sì dá ọ̀kankan ninu wọn sí. Jehu tún ń lọ, ó pàdé Jehonadabu, ọmọ Rekabu, tí ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀. Lẹ́yìn tí Jehu kí i tán, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé ọkàn rẹ mọ́ sí mi bí ọkàn mi ti mọ́ sí ọ?” Jehonadabu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.” Jehu dáhùn, ó ní, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, fún mi ní ọwọ́ rẹ.” Ó bá na ọwọ́ sí Jehu, Jehu sì fà á sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. Ó ní, “Tẹ̀lé mi, kí o wá wo ìtara mi fún OLUWA.” Wọ́n sì jọ gun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ lọ sí Samaria. Nígbà tí wọ́n dé Samaria, Jehu pa gbogbo àwọn ìbátan Ahabu, kò sì fi ọ̀kankan ninu wọn sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ láti ẹnu Elija. Lẹ́yìn náà, Jehu pe gbogbo àwọn ará Samaria jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ahabu sin oriṣa Baali díẹ̀, ṣugbọn n óo sìn ín lọpọlọpọ. Nítorí náà, ẹ pe gbogbo àwọn wolii Baali ati àwọn tí ń bọ ọ́ ati àwọn alufaa rẹ̀ wá fún mi. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe aláìwá nítorí mo fẹ́ ṣe ìrúbọ ńlá sí Baali. Ẹnikẹ́ni tí kò bá wá, pípa ni a óo pa á.” Ṣugbọn Jehu ń ṣe èyí láti rí ààyè pa gbogbo àwọn olùsìn Baali run ni. Ó pàṣẹ pé, “Ẹ ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ìsìn Baali,” wọ́n sì kéde rẹ̀. Jehu ranṣẹ sí àwọn ẹlẹ́sìn Baali ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli; kò sí ẹnìkan ninu wọn tí kò wá. Gbogbo wọn lọ sinu ilé ìsìn Baali, wọ́n sì kún inú rẹ̀ títí dé ẹnu ọ̀nà kan sí ekeji. Jehu sì pàṣẹ fún ẹni tí ń tọ́jú ibi tí wọn ń kó aṣọ ìsìn pamọ́ sí pé kí ó kó wọn jáde fún àwọn tí ń bọ Baali. Lẹ́yìn èyí, Jehu ati Jehonadabu lọ sinu ilé ìsìn náà, ó ní, “Ẹ rí i dájú pé àwọn olùsìn Baali nìkan ni wọ́n wà níhìn-ín, ati pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ń sin OLUWA níbí.” Òun pẹlu Jehonadabu bá wọlé láti rú ẹbọ sísun sí Baali. Ṣugbọn Jehu ti fi ọgọrin ọkunrin yí ilé ìsìn náà po, ó sì ti pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn tí wọ́n wá jọ́sìn níbẹ̀. Ó ní ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ kí ẹnìkan lọ, pípa ni a óo pa á. Ní kété tí Jehu parí rírú ẹbọ sísun rẹ̀, ó pàṣẹ fún àwọn olùṣọ́ ati àwọn olórí ogun pé kí wọ́n wọlé, kí wọ́n sì pa gbogbo wọn; ẹnikẹ́ni kò si gbọdọ̀ jáde. Wọ́n bá wọlé, wọ́n fi idà pa gbogbo wọn, wọ́n sì wọ́ òkú wọn síta. Lẹ́yìn náà, wọ́n wọ inú ibi mímọ́ Baali lọ, wọ́n kó gbogbo àwọn ère tí wọ́n wà níbẹ̀ jáde, wọ́n sì sun wọ́n níná. Wọ́n wó àwọn ère ati ilé ìsìn Baali lulẹ̀, wọ́n sì sọ ibẹ̀ di ilé ìgbẹ́ títí di òní yìí. Bẹ́ẹ̀ ni Jehu ṣe pa ìsìn Baali run ní Israẹli. Ṣugbọn Jehu tẹ̀lé ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu, ọmọ Nebati, tí ó mú kí Israẹli bọ ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù, tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ó wà ní Bẹtẹli ati Dani. OLUWA sọ fún Jehu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí o ti ṣe èyí tí ó dára lójú mi, o ti ṣe ohun tí mo fẹ́ ṣe sí ilé Ahabu, tí o ṣe ohun tí ó wà lọ́kàn mi, àwọn ọmọ rẹ, títí dé ìran kẹrin, yóo máa jọba ní Israẹli.” Ṣugbọn Jehu kò kíyèsára kí ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀lé Òfin OLUWA Ọlọrun Israẹli; ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu tí ó mú kí Israẹli hù ni ó tẹ̀lé.
II. A. Ọba 10:1-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nísinsin yìí, Ahabu ṣì ní àádọ́rin ọmọkùnrin ní ìdílé rẹ̀ ní Samaria. Bẹ́ẹ̀ ni, Jehu kọ lẹ́tà, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Samaria: sí àwọn oníṣẹ́ Jesreeli, sí àwọn àgbàgbà àti sí àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu. Ó wí pé, “Ní kété tí lẹ́tà bá ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ ọ̀gá rẹ wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ sì ní àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹṣin, ìlú olódi kan pẹ̀lú ohun ìjà, yan èyí tí ó dára àti èyí tí ó níye jùlọ nínú àwọn ọmọkùnrin ọ̀gá à rẹ, kí o sì gbé e lé orí ìtẹ́ baba a rẹ̀. Nígbà náà, kí o sì jà fún ilé ọ̀gá à rẹ.” Ṣùgbọ́n ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì wí pé, “Tí ọba méjì kò bá le kojú ìjà sí i, báwo ni a ṣẹ le è ṣe é?” Bẹ́ẹ̀ ẹni tí ń ṣe olórí ilé, ẹni tí ń ṣe olórí ìlú ńlá, àwọn àgbàgbà àti àwọn olùtọ́jú náà rán iṣẹ́ yìí sí Jehu: “ìránṣẹ́ rẹ ni àwa jẹ́ pẹ̀lú, àwa yóò ṣe ohunkóhun tí o bá sọ. Àwa kì yóò yan ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí ọba; ìwọ ṣe ohunkóhun tí o rò pé ó dára jù lójú rẹ.” Nígbà náà ni Jehu kọ lẹ́tà kejì sí wọn, wí pé, “Tí ìwọ bá wà ní ìhà tèmi, tí o sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, mú orí àwọn ọmọkùnrin ọ̀gá à rẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi ní Jesreeli ní ìwòyí ọ̀la.” Nísinsin yìí, àwọn ọmọ-aládé àádọ́rin ọkùnrin, ń bẹ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ńlá ìlú náà tí ń tọ́ wọn. Nígbà tí ìwé náà dé ọ̀dọ̀ wọn, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí mú gbogbo àwọn ọmọ ọba tí gbogbo wọ́n jẹ́ àádọ́rin wọ́n sì pa gbogbo wọn. Wọ́n gbé orí wọn sí inú apẹ̀rẹ̀, wọ́n fi ránṣẹ́ sí Jehu ní Jesreeli. Nígbà tí ìránṣẹ́ náà dé, ó sọ fún Jehu, “Wọ́n ti gbé orí àwọn ọmọ ọba náà wá.” Nígbà náà Jehu pàṣẹ, “Ẹ tò wọ́n ní òkìtì méjì ní àtiwọ ẹnu ibodè ìlú ńlá títí di òwúrọ̀.” Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Jehu jáde lọ. Ó dúró níwájú gbogbo àwọn ènìyàn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin jẹ́ aláìjẹ̀bi. Èmi ni mo dìtẹ̀ sí ọ̀gá mi, tí mo sì pa á, ṣùgbọ́n ta ni ó pa gbogbo àwọn wọ̀nyí!? Nígbà yìí, kò sí ọ̀rọ̀ kan tí OLúWA ti sọ sí ilé Ahabu tí yóò kùnà. OLúWA ti ṣe ohun tí ó ṣèlérí nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Elijah.” Bẹ́ẹ̀ ni Jehu pa gbogbo ẹni tí ó kù Jesreeli ní ilé Ahabu, pẹ̀lúpẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin ìjòyè rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ àti àwọn àlùfáà rẹ̀, láì ku ẹni tí ó yọ nínú ewu fún un. Jehu jáde lọ, ó sì lọ sí ọ̀kánkán Samaria. Ní Beti-Ekedi tí àwọn olùṣọ́-àgùntàn. Jehu pàdé díẹ̀ lára àwọn ìbátan Ahasiah ọba Juda, ó sì béèrè, “Ta ni ẹ̀yin ń ṣe?” Wọ́n wí pé, “Àwa jẹ́ ìbátan Ahasiah, àwa sì ti wá láti kí ìdílé ọba àti ti màmá ayaba.” “Mú wọn láààyè!” ó pàṣẹ. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n mú wọn láààyè, wọ́n sì pa wọ́n ní ẹ̀bá kọ̀nga Beti-Ekedi, ọkùnrin méjìlélógójì. Kò sì fi ẹnìkan sílẹ̀ láìkù. Nígbà tí a sì jáde níbẹ̀, ó rí Jehonadabu ọmọ Rekabu ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀, ó sì súre fún un, ó sì wí fún pé, “Ọkàn rẹ ha ṣe déédé bí ọkàn mi ti rí sí ọkàn rẹ?” Jehonadabu dáhùn wí pé “Èmi wà.” “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀,” Jehu wí, “fún mi ní ọwọ́ ọ̀ rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe pẹ̀lú, Jehu sì fà á lọ́wọ́ sókè sọ́dọ̀ rẹ̀ nínú kẹ̀kẹ́. Jehu wí pé, “Wá pẹ̀lú mi; kí o sì rí ìtara mi fún OLúWA.” Nígbà náà ó jẹ́ kí ó gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Nígbà tí Jehu wá sí Samaria, ó pa gbogbo àwọn tí a fi kalẹ̀ ní ìdílé Ahabu; ó pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLúWA tí a sọ sí Elijah. Nígbà náà, Jehu kó gbogbo àwọn ènìyàn jọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ahabu sin Baali díẹ̀; ṣùgbọ́n Jehu yóò sìn ín púpọ̀. Nísinsin yìí, ẹ pe gbogbo àwọn wòlíì Baali jọ fún mi, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo àlùfáà rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọ̀kan kí ó kù, nítorí èmí yóò rú ẹbọ ńlá sí Baali. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti wá, kò ní wà láààyè mọ́.” Ṣùgbọ́n Jehu fi ẹ̀tàn ṣe é, kí ó lè pa àwọn òjíṣẹ́ Baali run. Jehu wí pé, “ẹ pe àpéjọ ní ìwòyí ọ̀la fún Baali.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kéde rẹ. Nígbà náà, Jehu rán ọ̀rọ̀ káàkiri Israẹli, gbogbo àwọn òjíṣẹ́ Baali sì wá: kò sí ẹnìkan tí ó dúró lẹ́yìn. Wọ́n kún ilé tí a kọ́ fún òrìṣà títí tí ó fi kún láti ìkangun èkínní títí dé èkejì. Jehu sì sọ fún olùṣọ́ pé, “Kí ó mú aṣọ ìgúnwà wá fún gbogbo àwọn òjíṣẹ́ Baali.” Bẹ́ẹ̀ ni ó mú aṣọ ìgúnwà jáde wá fún wọn. Nígbà náà, Jehu àti Jehonadabu ọmọ Rekabu lọ sí inú ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Baali. Jehu sì wí fún àwọn òjíṣẹ́ Baali pé, “Wò ó yíká, kí o sì rí i pé kò sí ìránṣẹ́ Ọlọ́run kankan pẹ̀lú yín níbí—kìkì òjíṣẹ́ Baali.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọ inú ilé lọ láti lọ rú ẹbọ àti ẹbọ sísun. Nísinsin yìí Jehu ti rán ọgọ́rin ọkùnrin sí ìta pẹ̀lú ìkìlọ̀ yìí: “Tí ẹnikẹ́ni nínú yín bá jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọkùnrin tí mo ń gbé sí ọwọ́ yín ó sálọ, yóò jẹ́ ẹ̀mí yín fún ẹ̀mí rẹ.” Ní kété tí Jehu ti parí ṣíṣe ẹbọ sísun, ó pàṣẹ fún àwọn olùṣọ́ àti àwọn ìjòyè: “Wọlé lọ, kí o sì pa wọ́n; Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó sálọ.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gé wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà. Àwọn olùṣọ́ àti ìjòyè ju ara wọn síta, wọ́n sì wọ inú ojúbọ ti ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Baali. Wọ́n gbé òkúta bíbọ náà jáde láti inú ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Baali, wọ́n sì jó o. Wọ́n fọ́ òkúta bíbọ ti Baali náà túútúú, wọ́n sì ya ilé òrìṣà Baali bolẹ̀. Àwọn ènìyàn sì ń lò ó fún ilé ìgbẹ́ títí di ọjọ́ òní. Bẹ́ẹ̀ ni Jehu pa sí sin Baali run ní Israẹli. Bí ó ti wù kí ó rí, Jehu kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, tí ó ṣokùnfà Israẹli láti dá—ti sí sin ẹgbọrọ màlúù wúrà ní Beteli àti Dani. OLúWA sì sọ fún Jehu pé, “Nítorí ìwọ ti ṣe dáradára ní ṣíṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú mi, tí o sì ti ṣe sí ilé Ahabu gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn mi, àwọn ọmọ ọ̀ rẹ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Israẹli títí dé ìran kẹrin.” Síbẹ̀ Jehu kò ṣe pẹ̀lẹ́ láti pa òfin OLúWA, Ọlọ́run Israẹli mọ́ pẹ̀lú tọkàntọkàn. Òun kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu èyí tí ó ṣokùnfà Israẹli láti dá.