AHABU si ni ãdọrin ọmọ ọkunrin ni Samaria. Jehu si kọwe, o si ranṣẹ si Samaria si awọn olori Jesreeli, si awọn àgbagba, ati si awọn ti ntọ́ awọn ọmọ Ahabu, wipe,
Njẹ nisisiyi nigbati iwe yi ba ti de ọdọ nyin, bi o ti jẹpe, awọn ọmọ oluwa nyin mbẹ lọdọ nyin, ati kẹkẹ́ ati ẹṣin mbẹ lọdọ nyin, ilu olodi pẹlu ati ihamọra.
Ki ẹ wò ẹniti o sàn jùlọ ati ti o si yẹ jùlọ ninu awọn ọmọ oluwa nyin, ki ẹ gbé e ka ori-itẹ́ baba rẹ̀, ki ẹ si jà fun ile oluwa nyin.
Ṣugbọn ẹ̀ru bà wọn gidigidi, nwọn si wipe, Kiyesi i, ọba meji kò duro niwaju rẹ̀: awa o ha ti ṣe le duro?
Ati ẹniti iṣe olori ile, ati ẹniti iṣe olori ilu, awọn àgbagba pẹlu, ati awọn olutọ́ awọn ọmọ, ranṣẹ si Jehu wipe, Iranṣẹ rẹ li awa, a o si ṣe gbogbo ohun ti o ba pa li aṣẹ fun wa; awa kì yio jẹ ọba: iwọ ṣe eyi ti o dara li oju rẹ.
Nigbana ni o kọ iwe lẹrinkeji si wọn wipe, Bi ẹnyin ba ṣe ti emi, bi ẹnyin o si fi eti si ohùn mi, ẹ mu ori awọn ọkunrin na, awọn ọmọ oluwa nyin, ki ẹ si tọ̀ mi wá ni Jesreeli ni iwòyi ọla. Njẹ awọn ọmọ ọba, ãdọrin ọkunrin, mbẹ pẹlu awọn enia nla ilu na ti ntọ́ wọn.
O si ṣe, nigbati iwe na de ọdọ wọn, ni nwọn mu awọn ọmọ ọba, nwọn si pa ãdọrin ọkunrin, nwọn si kó ori wọn sinu agbọ̀n, nwọn si fi wọn ranṣẹ si i ni Jesreeli.
Onṣẹ kan si de, o si sọ fun u, wipe, nwọn ti mu ori awọn ọmọ ọba wá. On si wipe, Ẹ tò wọn li okiti meji ni atiwọ̀ ẹnu bodè, titi di owurọ̀.
O si ṣe li owurọ̀, o si jade lọ, o si duro, o si wi fun gbogbo awọn enia pe, Olododo li ẹnyin: kiyesi i, emi ṣọ̀tẹ si oluwa mi, mo si pa a: ṣugbọn tani pa gbogbo awọn wọnyi?
Njẹ ẹ mọ̀ pe, kò si ohunkan ninu ọ̀rọ Oluwa, ti Oluwa sọ niti ile Ahabu ti yio bọ́ silẹ, nitori ti Oluwa ti ṣe eyi ti o ti sọ nipa ọwọ Elijah iranṣẹ rẹ̀.
Bẹ̃ni Jehu pa gbogbo awọn ti o kù ni ile Ahabu ni Jesreeli ati gbogbo awọn enia nla rẹ̀, ati awọn ibatan rẹ̀, ati awọn alufa rẹ̀, titi on kò fi kù ọkan silẹ fun u.
On si dide, o si mbọ̀ o si wá si Samaria: bi o si ti wà nibi ile irẹ́run agutan li oju ọ̀na.
Jehu pade awọn arakunrin Ahasiah ọba Juda, o si wipe, Tali ẹnyin? Nwọn si dahùn wipe, Awa arakunrin Ahasiah ni; awa si nsọ̀kalẹ lati lọ ikí awọn ọmọ ọba ati awọn ọmọ ayaba.
On si wipe, Ẹ mu wọn lãyè, nwọn si mu wọn lãyè, nwọn si pa wọn nibi iho ile irẹ́run agùtan, ani ọkunrin mejilelogoji, bẹ̃ni kò si kù ẹnikan wọn.
Nigbati o si jade nibẹ, o ri Jehonadabu ọmọ Rekabu mbọ̀wá ipade rẹ̀; o si sure fun u, o si wi fun u pe, Ọkàn rẹ ha ṣe dede bi ọkàn mi ti ri si ọkàn rẹ? Jehonadabu si dahùn wipe, Bẹ̃ni. Bi bẹ̃ni, njẹ fun mi li ọwọ rẹ. O si fun u li ọwọ rẹ̀; on si fà a sọdọ rẹ̀ sinu kẹkẹ́.
On si wipe, Ba mi lọ ki o si wò itara mi fun Oluwa. Bẹ̃ni nwọn mu u gùn kẹkẹ́ rẹ̀.
Nigbati o si de Samaria, o pa gbogbo awọn ti o kù fun Ahabu ni Samaria, titi o fi run u, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa ti o sọ fun Elijah.
Jehu si kó gbogbo awọn enia jọ, o si wi fun wọn pe, Ahabu sìn Baali diẹ, ṣugbọn Jehu yio sìn i pupọ.
Njẹ nitorina, ẹ pè gbogbo awọn woli Baali fun mi, gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, ati gbogbo awọn alufa rẹ̀; máṣe jẹ ki ọkan ki o kù; nitoriti mo ni ẹbọ nla iṣe si Baali: ẹnikẹni ti o ba kù, kì yio yè. Ṣugbọn Jehu fi ẹ̀tan ṣe e, nitori ki o le pa awọn olùsin Baali run.
Jehu si wipe, Ẹ yà apejọ si mimọ́ fun Baali; nwọn si kede rẹ̀.
Jehu si ranṣẹ si gbogbo Israeli; gbogbo awọn olùsin Baali si wá tobẹ̃ ti kò si kù ọkunrin kan ti kò wá. Nwọn si wá sinu ile Baali; ile Baali si kún lati ikangun ekini titi de ekeji.
On si wi fun ẹniti o wà lori yará babaloriṣa pe, Kó aṣọ wá fun gbogbo awọn olùsin Baali. On si kó aṣọ jade fun wọn wá.
Jehu si lọ, ati Jehonadabu ọmọ Rekabu sinu ile Baali, o si wi fun awọn olùsin Baali pe, Ẹ wá kiri, ki ẹ si wò ki ẹnikan ninu awọn iranṣẹ Oluwa ki o má si pẹlu nyin nihin, bikòṣe kìki awọn olùsin Baali.
Nigbati nwọn si wọle lati ru ẹbọ ati ọrẹ-sisun, Jehu yàn ọgọrin ọkunrin si ode, o si wipe, Bi ẹnikan ninu awọn ọkunrin ti mo mu wá fi le nyin lọwọ ba lọ, ẹniti o ba jẹ ki o lọ, ẹmi rẹ̀ yio lọ fun ẹmi tirẹ̀.
O si ṣe, bi a si ti pari ati ru ẹbọ sisun, ni Jehu wi fun awọn olùṣọ ati awọn olori-ogun pe, Wọle, ki ẹ si pa wọn; ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o jade. Nwọn si fi oju idà pa wọn; awọn olùṣọ ati awọn olori-ogun si gbé wọn sọ si ode, nwọn si wọ̀ inu odi ile Baali.
Nwọn si kó awọn ere lati ile Baali jade, nwọn si sun wọn.
Nwọn si wo ere Baali lulẹ, nwọn si wo ile Baali lulẹ, nwọn si ṣe e ni ile igbẹ́ titi di oni yi.
Bayi ni Jehu pa Baali run kuro ni Israeli.
Ṣugbọn Jehu kò kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ọmọ Nebati, ti o mu Israeli ṣẹ̀, eyinì ni, awọn ẹgbọ̀rọ malu wura ti o wà ni Beteli, ati eyiti o wà ni Dani.
Oluwa si wi fun Jehu pe, Nitoriti iwọ ti ṣe rere ni ṣiṣe eyi ti o tọ́ li oju mi, ti o si ti ṣe si ile Ahabu gẹgẹ bi gbogbo eyiti o wà li ọkàn mi, awọn ọmọ rẹ iran kẹrin yio joko lori itẹ Israeli.
Ṣugbọn Jehu kò ṣe akiyesi lati ma fi gbogbo ọkàn rẹ̀ rin ninu ofin Oluwa Ọlọrun Israeli: nitoriti kò yà kuro ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ti o mu Israeli ṣẹ̀.