II. Kor 9:6-12
II. Kor 9:6-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn eyi ni mo wipe, Ẹniti o ba funrugbin kiun, kiun ni yio ká; ẹniti o ba si funrugbin, pupọ, pupọ ni yio ká. Ki olululuku enia ki o ṣe gẹgẹ bi o ti pinnu li ọkàn rẹ̀; kì iṣe àfẹ̀kùnṣe, tabi ti alaigbọdọ má ṣe: nitori Ọlọrun fẹ oninudidun ọlọrẹ. Ọlọrun si le mu ki gbogbo ore-ọfẹ ma bisi i fun nyin; ki ẹnyin, ti o ni anito ohun gbogbo nigbagbogbo, le mã pọ̀ si i ni iṣẹ́ rere gbogbo: (Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, O ti fọnka; o ti fifun awọn talakà: ododo rẹ̀ duro lailai. Njẹ ẹniti nfi irugbin fun afunrugbin, ati akara fun onjẹ, yio fi irugbin fun nyin, yio si sọ ọ di pipọ fun irugbin, yio si mu eso ododo nyin bi si i.) Ẹnyin ti a ti sọ di ọlọrọ̀ ninu ohun gbogbo, fun ilawọ gbogbo ti nṣiṣẹ ọpẹ si Ọlọrun nipa wa. Nitori iṣẹ-iranṣẹ ìsin yi kò fi kun iwọn aini awọn enia mimọ́ nikan, ṣugbọn o tubọ pọ si i nipa ọ̀pọlọpọ ọpẹ́ si Ọlọrun
II. Kor 9:6-12 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ ranti pé ẹni tí ó bá fúnrúgbìn díẹ̀, díẹ̀ ni yóo kórè. Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn pupọ, pupọ ni yóo kórè. Kí olukuluku ṣe bí ó bá ti pinnu ninu ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹlu ìkanra, tabi àfipáṣe, nítorí onínúdídùn ọlọ́rẹ ni Ọlọrun fẹ́. Ọlọrun lè fun yín ní oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn, tí ẹ óo fi ní ànító ninu ohun gbogbo nígbà gbogbo. Ẹ óo sì tún ní tí yóo ṣẹ́kù fún ohun rere gbogbo. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ẹnìkan lawọ́, ó ń ta àwọn talaka lọ́rẹ, iṣẹ́ àánú rẹ̀ wà títí.” Ṣugbọn ẹni tí ó ń pèsè irúgbìn fún afunrugbin, tí ó tún ń pèsè oúnjẹ fún jíjẹ, yóo pèsè èso lọpọlọpọ fun yín, yóo sì mú kí àwọn èso iṣẹ́ àánú yín pọ̀ sí i. Ẹ óo jẹ́ ọlọ́rọ̀ ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ óo fi lè máa lawọ́ nígbà gbogbo. Ọpọlọpọ eniyan yóo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà tí a bá fún wọn ní ẹ̀bùn tí ẹ gbé kalẹ̀ nítorí ìlawọ́ yín. Nítorí kì í ṣe àìní àwọn onigbagbọ nìkan ni iṣẹ́ ìsìn yìí yóo pèsè fún, ṣugbọn yóo mú kí ọpọlọpọ eniyan máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun.
II. Kor 9:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n èyí ni mo wí pé: Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn kín ún, kín ún ni yóò ká; ẹni tí ó bá sì fúnrúgbìn púpọ̀, púpọ̀ ni yóò ká. Kí olúkúlùkù ènìyàn ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọkàn rẹ̀; kì í ṣe àfi ìkùnsínú ṣe, tàbí ti àìgbọdọ̀ má ṣe; nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ. Ọlọ́run sì lè mú kí gbogbo oore-ọ̀fẹ́ máa bí sí i fún yín; kí ẹ̀yin tí ó ní ànító ohun gbogbo, nígbà gbogbo, lè máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ rere gbogbo. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ pé: “Ó tí fọ́nká; ó ti fi fún àwọn tálákà; Òdodo rẹ̀ dúró láéláé.” Ǹjẹ́ ẹni tí ń fi irúgbìn fún afúnrúgbìn, àti àkàrà fún oúnjẹ, yóò fi irúgbìn fún un yín, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, yóò sì mú èso òdodo yín bí sí i. Bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ohun gbogbo, fún ìlawọ́ yín gbogbo tí ń ṣiṣẹ́ ọpẹ́ sí Ọlọ́run nípa wa. Nítorí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìsìn yìí kò kún ìwọ̀n àìní àwọn ènìyàn mímọ́ nìkan, ṣùgbọ́n ó túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọpẹ́ sí Ọlọ́run.