II. Kor 9:6-12
Ṣugbọn eyi ni mo wipe, Ẹniti o ba funrugbin kiun, kiun ni yio ká; ẹniti o ba si funrugbin, pupọ, pupọ ni yio ká. Ki olululuku enia ki o ṣe gẹgẹ bi o ti pinnu li ọkàn rẹ̀; kì iṣe àfẹ̀kùnṣe, tabi ti alaigbọdọ má ṣe: nitori Ọlọrun fẹ oninudidun ọlọrẹ. Ọlọrun si le mu ki gbogbo ore-ọfẹ ma bisi i fun nyin; ki ẹnyin, ti o ni anito ohun gbogbo nigbagbogbo, le mã pọ̀ si i ni iṣẹ́ rere gbogbo: (Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, O ti fọnka; o ti fifun awọn talakà: ododo rẹ̀ duro lailai. Njẹ ẹniti nfi irugbin fun afunrugbin, ati akara fun onjẹ, yio fi irugbin fun nyin, yio si sọ ọ di pipọ fun irugbin, yio si mu eso ododo nyin bi si i.) Ẹnyin ti a ti sọ di ọlọrọ̀ ninu ohun gbogbo, fun ilawọ gbogbo ti nṣiṣẹ ọpẹ si Ọlọrun nipa wa. Nitori iṣẹ-iranṣẹ ìsin yi kò fi kun iwọn aini awọn enia mimọ́ nikan, ṣugbọn o tubọ pọ si i nipa ọ̀pọlọpọ ọpẹ́ si Ọlọrun
II. Kor 9:6-12