II. Kor 7:2-11

II. Kor 7:2-11 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹ gbà wa tọkàntọkàn; a kò fi ibi ṣe ẹnikẹni, a kò bà ẹnikẹni jẹ, a kò rẹ́ ẹnikẹni jẹ. Emi kò sọ eyi lati da nyin lẹbi: nitori mo ti wi ṣãjú pe, ẹnyin wà li ọkàn wa ki a le jumọ kú, ati ki a le jumọ wà lãye. Mo ni igboiya nla lati ba nyin sọ̀rọ, iṣogo mi lori nyin pọ̀, mo kun fun itunu, mo si nyọ̀ rekọja ninu gbogbo ipọnju wa. Nitoripe nigbati awa tilẹ de Makedonia, ara wa kò balẹ, ṣugbọn a nwahalà wa niha gbogbo; ìja mbẹ lode, ẹ̀ru mbẹ ninu. Ṣugbọn ẹniti ntù awọn onirẹlẹ ninu, ani Ọlọrun, o tù wa ninu nipa didé Titu; Kì si iṣe nipa didé rẹ̀ nikan, ṣugbọn nipa itunu na pẹlu ti ẹ ti tù u ninu, nigbati o rohin fun wa ifẹ gbigbona nyin, ibanujẹ nyin, ati itara nyin fun mi; bẹni mo si tubọ yọ̀. Nitoripe bi mo tilẹ fi iwe mu inu nyin bajẹ, emi kò kãbámọ̀, bi mo tilẹ ti kabamọ rí: nitoriti mo woye pe iwe nì mu nyin banujẹ, bi o tilẹ jẹ pe fun igba diẹ. Emi yọ̀ nisisiyi, kì iṣe nitoriti a mu inu nyin bajẹ, ṣugbọn nitoriti a mu inu nyin bajẹ si ironupiwada: nitoriti a mu inu nyin bajẹ bi ẹni ìwa-bi-Ọlọrun, ki ẹnyin ki o maṣe tipasẹ wa pàdanù li ohunkohun. Nitoripe ibanujẹ ẹni ìwa-bi-Ọlọrun a ma ṣiṣẹ ironupiwada si igbala ti kì mu abamọ wá: ṣugbọn ibanujẹ ti aiye a ma ṣiṣẹ ikú. Kiyesi i, nitori ohun kanna yi ti a mu nyin banujẹ fun bi ẹni ìwa-bi-Ọlọrun, iṣọra ti o mu ba nyin ti kara to, ijirẹbẹ nyin ti tó, ani irunu, ani ibẹru, ani ifẹ gbigbona, ani itara, ani igbẹsan! Ninu ohun gbogbo ẹ ti farahan pe ara nyin mọ́ ninu ọran na.

II. Kor 7:2-11 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ fi wá sọ́kàn. A kò ṣẹ ẹnikẹ́ni. A kò ba ẹnikẹ́ni jẹ́. A kò sì rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ. Kì í ṣe pé mò ń fi èyí ba yín wí. Nítorí, bí mo ti sọ ṣáájú, ẹ ṣe ọ̀wọ́n fún wa tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí ó bá kan ti ikú, kí á jọ kú ni, bí ó bá sì jẹ́ ti ìyè, kí á jọ wà láàyè ni. Ọkàn mi balẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yín. Mò ń fi ọwọ́ yín sọ̀yà. Mò ti ní ìtùnú kíkún. Ninu gbogbo ìpọ́njú wa, mo ní ayọ̀ lọpọlọpọ. Nígbà tí a dé Masedonia, ọkàn wa kò balẹ̀ rárá. Wahala ni lọ́tùn-ún lósì, ìjà lóde, ẹ̀rù ninu. Ṣugbọn Ọlọrun tí ń tu àwọn tí ọkàn wọn bá rẹ̀wẹ̀sì ninu, ti tù wá ninu nígbà tí Titu dé. Kì í sìí ṣe ti dídé tí ó dé nìkan ni, ṣugbọn ó ròyìn fún wa, gbogbo bí ẹ ti dá a lọ́kàn le ati gbogbo akitiyan yín lórí wa, bí ọkàn yín ti bàjẹ́ tó fún ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ati bí ẹ ti ní ìtara tó fún mi. Èyí mú kí inú mi dùn pupọ. Bí ó bá jẹ́ pé ìwé tí mo kọ bà yín ninu jẹ́, n kò kábàámọ̀ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti kọ́ kábàámọ̀ pé ìwé náà bà yín lọ́kàn jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii mo láyọ̀. Kì í ṣe nítorí pé ó bà yín lọ́kàn jẹ́, ṣugbọn nítorí pé bíbà tí ó bà yín lọ́kàn jẹ́ ni ó jẹ́ kí ẹ ronupiwada. Nítorí ẹ farada ìbànújẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti fẹ́, kí ẹ má baà pàdánù nítorí ohun tí a ṣe. Ìbànújẹ́ tí eniyan bà faradà gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti fẹ́ a máa mú kí eniyan ronupiwada kí ó sì rí ìgbàlà, tí kò ní àbámọ̀ ninu. Ṣugbọn tí eniyan bá kàn ní ìbànújẹ́ lásán, ikú ni àyọrísí rẹ̀. Ṣé ẹ wá rí i bí ìbànújẹ́ tí ẹ faradà gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti fẹ́, ti yọrí sí fun yín? Ó mú kí ẹ fi ìtara mú ọ̀rọ̀ náà, kí ẹ sì jà fún ara yín. Ó mú kí inú bi yín sí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó mú ìbẹ̀rù wá sọ́kàn yín. Ó mú kí ẹ ṣe aájò mi. Ó mú kí ẹ ní ìtara. Ó mú kí ẹ rí i pé ẹ ṣe ẹ̀tọ́ ninu ọ̀ràn náà. Ní gbogbo ọ̀nà ẹ ti fihàn pé ọwọ́ yín mọ́ ninu ọ̀ràn náà.

II. Kor 7:2-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ gbà wá tọkàntọkàn; a kò fi ibi ṣe ẹnikẹ́ni, a kò ba ẹnikẹ́ni jẹ́, a kò rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ. Èmi kò sọ èyí láti dá a yín lẹ́bi; nítorí mo tí wí ṣáájú pé, ẹ̀yin wà nínú ọkàn wa kí a lè jùmọ̀ kú, àti kí a lè jùmọ̀ wà láààyè. Mo ní ìgboyà ńlá láti bá yín sọ̀rọ̀; ìṣògo mí lórí yín pọ̀; mo kún fún ìtùnú, mo sì ń yọ̀ rékọjá nínú gbogbo ìpọ́njú wa. Nítorí pé nígbà tí àwa tilẹ̀ dé Makedonia, ara wá kò balẹ̀, ṣùgbọ́n a ń pọ́n wá lójú níhà gbogbo, ìjà ń bẹ lóde, ẹ̀rù ń bẹ nínú. Ṣùgbọ́n ẹni tí ń tu àwọn onírẹ̀lẹ̀ nínú, àní Ọlọ́run, ó tù wá nínú nípa dídé tí Titu dé; Kì í sì i ṣe nípa dídé rẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n nípa ìtùnú náà pẹ̀lú tí ẹ ti tù ú nínú, nígbà tí ó ròyìn fún wa ìfẹ́ àtọkànwá yín, ìbànújẹ́ yín, àti ìtara yín fún mi; bẹ́ẹ̀ ní mo sì túbọ̀ yọ̀. Nítorí pé, bí mo tilẹ̀ ba inú yín jẹ́ nípa ìwé tí mo kọ èmi kò kábámọ̀ mọ́, bí mo tilẹ̀ ti kábámọ̀ tẹ́lẹ̀ rí; nítorí tí mo wòye pé ìwé mi mú yín banújẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún ìgbà díẹ̀. Èmi yọ̀ nísinsin yìí, kì í ṣe nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́, ṣùgbọ́n nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́ sí ìrònúpìwàdà: nítorí ti a mú inú yín bàjẹ́ bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, kí ẹ̀yin má ṣe ti ipasẹ̀ wa pàdánù ní ohunkóhun. Nítorí pé ìbànújẹ́ ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run a máa ṣiṣẹ́ ìrònúpìwàdà sí ìgbàlà tí kì í mú àbámọ̀ wá: ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ti ayé a máa ṣiṣẹ́ ikú. Kíyèsi i, nítorí ohun kan náà yìí tí a mú yin banújẹ́ fún bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, irú ìmúraṣíṣẹ́ tí ó mú jáde nínú yín, wíwẹ ara yín mọ́ ńkọ́, ìbànújẹ́ ńkọ́, ìpayà ńkọ́, ìfojúṣọ́nà ńkọ́, ìtara ńkọ́, ìjẹ́ni-níyà ńkọ́. Nínú ohun ààmì kọ̀ọ̀kan yìí ni ẹ̀yin ti fi ara yín hàn bí aláìlẹ́bi nínú ọ̀ràn náà.