Ẹ gbà wá tọkàntọkàn; a kò fi ibi ṣe ẹnikẹ́ni, a kò ba ẹnikẹ́ni jẹ́, a kò rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ. Èmi kò sọ èyí láti dá a yín lẹ́bi; nítorí mo tí wí ṣáájú pé, ẹ̀yin wà nínú ọkàn wa kí a lè jùmọ̀ kú, àti kí a lè jùmọ̀ wà láààyè. Mo ní ìgboyà ńlá láti bá yín sọ̀rọ̀; ìṣògo mí lórí yín pọ̀; mo kún fún ìtùnú, mo sì ń yọ̀ rékọjá nínú gbogbo ìpọ́njú wa.
Nítorí pé nígbà tí àwa tilẹ̀ dé Makedonia, ara wá kò balẹ̀, ṣùgbọ́n a ń pọ́n wá lójú níhà gbogbo, ìjà ń bẹ lóde, ẹ̀rù ń bẹ nínú. Ṣùgbọ́n ẹni tí ń tu àwọn onírẹ̀lẹ̀ nínú, àní Ọlọ́run, ó tù wá nínú nípa dídé tí Titu dé; Kì í sì i ṣe nípa dídé rẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n nípa ìtùnú náà pẹ̀lú tí ẹ ti tù ú nínú, nígbà tí ó ròyìn fún wa ìfẹ́ àtọkànwá yín, ìbànújẹ́ yín, àti ìtara yín fún mi; bẹ́ẹ̀ ní mo sì túbọ̀ yọ̀.
Nítorí pé, bí mo tilẹ̀ ba inú yín jẹ́ nípa ìwé tí mo kọ èmi kò kábámọ̀ mọ́, bí mo tilẹ̀ ti kábámọ̀ tẹ́lẹ̀ rí; nítorí tí mo wòye pé ìwé mi mú yín banújẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún ìgbà díẹ̀. Èmi yọ̀ nísinsin yìí, kì í ṣe nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́, ṣùgbọ́n nítorí tí a mú inú yín bàjẹ́ sí ìrònúpìwàdà: nítorí ti a mú inú yín bàjẹ́ bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, kí ẹ̀yin má ṣe ti ipasẹ̀ wa pàdánù ní ohunkóhun. Nítorí pé ìbànújẹ́ ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run a máa ṣiṣẹ́ ìrònúpìwàdà sí ìgbàlà tí kì í mú àbámọ̀ wá: ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ti ayé a máa ṣiṣẹ́ ikú. Kíyèsi i, nítorí ohun kan náà yìí tí a mú yin banújẹ́ fún bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, irú ìmúraṣíṣẹ́ tí ó mú jáde nínú yín, wíwẹ ara yín mọ́ ńkọ́, ìbànújẹ́ ńkọ́, ìpayà ńkọ́, ìfojúṣọ́nà ńkọ́, ìtara ńkọ́, ìjẹ́ni-níyà ńkọ́. Nínú ohun ààmì kọ̀ọ̀kan yìí ni ẹ̀yin ti fi ara yín hàn bí aláìlẹ́bi nínú ọ̀ràn náà.