II. Kro 7:1-3
II. Kro 7:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
BI Solomoni si ti pari adura igbà, iná bọ́ lati ọrun wá, o si jo ọrẹ sisun ati ẹbọ na run; ogo Oluwa si kún ile na. Awọn alufa kò le wọ̀ inu ile Oluwa, nitori ogo Oluwa kún ile Oluwa. Gbogbo awọn ọmọ Israeli si ri bi iná na ti bọ́ silẹ, ati ogo Oluwa sori ile na, nwọn doju wọn bò ilẹ ti a fi okuta tẹ́, nwọn si tẹriba, nwọn si yìn Oluwa, wipe, Nitoriti o ṣeun; nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai.
II. Kro 7:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Solomoni parí adura rẹ̀, iná kan ṣẹ́ láti ọ̀run, ó jó gbogbo ẹbọ sísun ati ọrẹ, ògo OLUWA sì kún inú tẹmpili. Àwọn alufaa kò sì lè wọ inú tẹmpili lọ mọ́ nítorí ògo OLUWA ti kún ibẹ̀. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí i bí iná ati ògo OLUWA ti sọ̀kalẹ̀ sórí tẹmpili, wọ́n dojúbolẹ̀, wọ́n sin Ọlọrun, wọ́n fi ọpẹ́ fún un, “Nítorí pé ó ṣeun, nítorí pé àánú rẹ̀ wà títí lae.”
II. Kro 7:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Solomoni sì ti parí àdúrà, iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó ẹbọ sísun àti ẹbọ, ògo Ọlọ́run sì kún ilé OLúWA. Àwọn àlùfáà kò sì le wo ilé OLúWA náà nítorí pé ògo OLúWA kún un. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí iná tí ó ń sọ̀kalẹ̀ àti ògo OLúWA lórí ilé OLúWA náà, wọ́n sì kúnlẹ̀ lórí eékún wọn pẹ̀lú ojú ni dídàbolẹ̀, wọ́n sì sin OLúWA, wọ́n sì fi ìyìn fún OLúWA wí pé, “Nítorí tí ó dára; àánú rẹ̀ sì dúró títí láéláé.”