II. Kro 36:1-21
II. Kro 36:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA ni awọn enia ilẹ na mu Jehoahasi, ọmọ Josiah, nwọn si fi i jọba ni ipò baba rẹ̀ ni Jerusalemu. Ẹni ọdun mẹtalelogun ni Jehoahasi, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba oṣu mẹta ni Jerusalemu. Ọba Egipti si mu u kuro ni Jerusalemu, o si bù ọgọrun fadakà ati talenti wura kan fun ilẹ na. Ọba Egipti si fi Eliakimu, arakunrin rẹ̀, jọba lori Juda ati Jerusalemu, o si pa orukọ rẹ̀ dà si Jehoiakimu; Neko si mu Jehoahasi, arakunrin rẹ̀, o si mu u lọ si Egipti. Ẹni ọdun mẹdọgbọn ni Jehoiakimu, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkanla ni Jerusalemu; o si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀, Nebukadnessari, ọba Babeli, gòke wá, o si dè e ni ẹ̀won, lati mu u lọ si Babeli. Nebukadnessari kó ninu ohun-elo ile Oluwa lọ si Babeli pẹlu, o si fi wọn sinu ãfin rẹ̀ ni Babeli. Ati iyokù iṣe Jehoiakimu ati awọn ohun-irira rẹ̀ ti o ti ṣe, ti a si ri ninu rẹ̀, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli ati Juda: Jehoiakini, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀. Ẹni ọdun mejidilogun ni Jehoiakini nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba oṣù mẹta ati ijọ mẹwa ni Jerusalemu: o si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa. Ati li amọdun, Nebukadnessari ranṣẹ, a si mu u wá si Babeli, pẹlu ohun-elo daradara ile Oluwa, o si fi Sedekiah, arakunrin rẹ̀, jọba lori Juda ati Jerusalemu. Ẹni ọdun mọkanlelogun ni Sedekiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mọkanla ni Jerusalemu. O si ṣe eyi ti o buru li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀, kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ niwaju Jeremiah, woli, ti o sọ̀rọ lati ẹnu Oluwa wá. On pẹlu si ṣọ̀tẹ si Nebukadnessari ọba, ẹniti o ti mu u fi Ọlọrun bura; ṣugbọn o wà ọrùn rẹ̀ kì, o si mu aiya rẹ̀ le lati má yipada si Oluwa Ọlọrun Israeli. Pẹlupẹlu, gbogbo awọn olori awọn alufa ati awọn enia dẹṣẹ gidigidi bi gbogbo irira awọn orilẹ-ède, nwọn si sọ ile Oluwa di ẽri, ti on ti yà si mimọ́ ni Jerusalemu. Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn si ranṣẹ si wọn lati ọwọ awọn onṣẹ rẹ̀, o ndide ni kùtukutu o si nranṣẹ, nitori ti o ni iyọ́nu si awọn enia rẹ̀, ati si ibugbe rẹ̀. Ṣugbọn nwọn fi awọn onṣẹ Ọlọrun ṣe ẹlẹya, nwọn si kẹgan ọ̀rọ rẹ̀, nwọn si fi awọn woli rẹ̀ ṣẹsin, titi ibinu Oluwa fi ru si awọn enia rẹ̀, ti kò fi si atunṣe. Nitorina li o ṣe mu ọba awọn ara Kaldea wá ba wọn, ẹniti o fi idà pa awọn ọdọmọkunrin wọn ni ile ibi-mimọ́ wọn, kò si ni iyọ́nu si ọdọmọkunrin tabi wundia, arugbo, tabi ẹniti o bà fun ogbó: on fi gbogbo wọn le e li ọwọ. Ati gbogbo ohun-elo ile Ọlọrun, nla ati kekere, ati iṣura ile Oluwa ati iṣura ọba, ati ti awọn ijoye rẹ̀; gbogbo wọn li o mu wá si Babeli. Nwọn si kun ile Ọlọrun, nwọn si wó odi Jerusalemu palẹ, nwọn si fi iná sun ãfin rẹ̀, nwọn si fọ́ gbogbo ohun-elo daradara rẹ̀ tũtu. Awọn ti o ṣikù lọwọ idà li o kó lọ si Babeli; nibiti nwọn jẹ́ iranṣẹ fun u, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ titi di ijọba awọn ara Persia: Lati mu ọ̀rọ Oluwa ṣẹ lati ẹnu Jeremiah wá, titi ilẹ na yio fi san ọdun isimi rẹ̀; ani ni gbogbo ọjọ idahoro on nṣe isimi titi ãdọrin ọdun yio fi pé.

II. Kro 36:1-21 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn ọmọ ilẹ̀ Juda bá fi Joahasi, ọmọ Josaya, jọba ní Jerusalẹmu lẹ́yìn baba rẹ̀. Joahasi jẹ́ ẹni ọdún mẹtalelogun nígbà tí ó jọba, ó wà lórí oyè fún oṣù mẹta. Ọba Ijipti ni ó lé e kúrò lórí oyè ní Jerusalẹmu, ó sì mú àwọn ọmọ Juda ní ipá láti máa san ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ati ìwọ̀n talẹnti wúrà kan, gẹ́gẹ́ bí ìṣákọ́lẹ̀. Neko, ọba Ijipti fi Eliakimu, arakunrin Joahasi jọba lórí Jerusalẹmu ati Juda, ó yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jehoiakimu, ó sì mú Joahasi lọ sí Ijipti. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni Jehoiakimu nígbà tí ó jọba. Ó wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Nebukadinesari, ọba Babiloni, gbógun tì í, ó sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é, ó fà á lọ sí Babiloni. Nebukadinesari, ọba Babiloni, kó ninu àwọn ohun èlò ilé OLUWA lọ sí Babiloni, ó kó wọn sinu ààfin rẹ̀ ní Babiloni. Àkọsílẹ̀ gbogbo nǹkan yòókù tí Jehoiakimu ṣe ati gbogbo ohun ìríra tí ó ṣe, ati àwọn àìdára rẹ̀ wà ninu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli ati ti Juda. Jehoiakini, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀. Jehoiakini jẹ́ ọmọ ọdún mẹjọ nígbà tí ó jọba. Ó wà lórí oyè fún oṣù mẹta ati ọjọ́ mẹ́wàá ní Jerusalẹmu. Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA. Nígbà tí ọdún yípo, Nebukadinesari, ọba Babiloni ranṣẹ lọ mú un wá sí Babiloni pẹlu àwọn ohun èlò olówó iyebíye tí ó wà ninu ilé OLUWA. Ó sì fi Sedekaya, arakunrin rẹ̀ jọba ní Jerusalẹmu ati Juda. Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó jọba. Ó wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA Ọlọrun rẹ̀, kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú wolii Jeremaya ẹni tí Ọlọrun rán sí i láti bá a sọ̀rọ̀. Sedekaya ṣọ̀tẹ̀ sí Nebukadinesari, bẹ́ẹ̀ sì ni Nebukadinesari ti fi ipá mú un búra ní orúkọ OLUWA pé kò ní ṣọ̀tẹ̀ sí òun. Ó ṣoríkunkun, ó sì kọ̀ láti yipada sí OLUWA Ọlọrun Israẹli. Bákan náà, àwọn alufaa tí wọ́n jẹ́ aṣaaju ati àwọn eniyan yòókù pàápàá ṣe aiṣootọ sí OLUWA, wọ́n tẹ̀lé ìwà ìríra àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká, wọ́n sì sọ ilé tí OLUWA ti yà sí mímọ́ ní Jerusalẹmu di aláìmọ́. OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn kò dẹ́kun láti máa rán wolii sí wọn, nítorí pé àánú àwọn eniyan rẹ̀ ati ibùgbé rẹ̀ ń ṣe é. Ṣugbọn, yẹ̀yẹ́ ni wọ́n ń fi àwọn iranṣẹ Ọlọrun ṣe. Wọn kò náání ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń kẹ́gàn àwọn wolii rẹ̀ títí tí OLUWA fi bínú sí wọn, débi pé kò sí àtúnṣe. Ọlọrun mú kí ọba Kalidea gbógun tì wọ́n. Ọba náà fi idà pa àwọn ọdọmọkunrin Juda ninu tẹmpili, kò ṣàánú àwọn ọdọmọkunrin tabi wundia, tabi àwọn àgbà tabi arúgbó; gbogbo wọn ni Ọlọrun fi lé e lọ́wọ́. Ọba Babiloni kó gbogbo ohun èlò ilé OLUWA, ati ńláńlá, ati kéékèèké, ati àwọn ìṣúra tí ó wà níbẹ̀, ati àwọn tí wọ́n wà ní ààfin ati ti ilé àwọn ìjòyè; ó kó gbogbo wọn patapata lọ sí Babiloni. Wọ́n jó ilé OLUWA, wọ́n wó odi Jerusalẹmu, wọ́n jó ààfin ọba, wọ́n sì ba gbogbo nǹkan olówó iyebíye ibẹ̀ jẹ́. Nebukadinesari kó gbogbo àwọn tí wọ́n kù tí wọn kò pa lẹ́rú, ati àwọn ọmọ wọn. Ó kó wọn lọ sí Babiloni, wọ́n sì ń sin òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ títí di àkókò ìjọba Pasia; kí ohun tí OLUWA ti sọ láti ẹnu wolii Jeremaya lè ṣẹ, pé, “Ilẹ̀ náà yóo di ahoro fún aadọrin ọdún kí ó lè ní gbogbo ìsinmi tí ó yẹ kí ó ti ní, ṣugbọn tí kò ní.”
II. Kro 36:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú Jehoahasi ọmọ Josiah wọn sì fi jẹ ọba ní Jerusalẹmu ni ipò baba rẹ̀. Jehoahasi sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta. Ọba Ejibiti yọ kúrò lórí ìtẹ́ ní Jerusalẹmu, ó sì bù fún un lórí Juda, ọgọ́ọ̀rún tálẹ́ǹtì fàdákà (100) àti tálẹ́ǹtì wúrà kan. Ọba Ejibiti sì mú Eliakimu, arákùnrin Joahasi, jẹ ọba lórí Juda àti Jerusalẹmu, ó sì yí orúkọ Eliakimu padà sí Jehoiakimu, ṣùgbọ́n Neko mú Joahasi arákùnrin Eliakimu lọ sí Ejibiti. Jehoiakimu sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìlá. Ó sì ṣe búburú ní ojú OLúWA Ọlọ́run rẹ̀. Nebukadnessari ọba Babeli sì mú un, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti mú un lọ sí Babeli. Nebukadnessari kó nínú ohun èlò ilé OLúWA lọ si Babeli pẹ̀lú, ó sì fi wọn sí ààfin rẹ̀ ní Babeli. Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jehoiakimu, àwọn ohun ìríra tí ó ṣe àti gbogbo ohun tí a rí nípa rẹ̀, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Israẹli àti Juda. Jehoiakini ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Jehoiakini sì jẹ́ ẹni ọdún méjì-dínlógún (18) nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ́ ọba ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́wàá ó sì ṣe búburú ní ojú OLúWA. Ní àkókò òjò, ọba Nebukadnessari ránṣẹ́ sí i ó sì mú un wá sí Babeli, pẹ̀lú ohun èlò dáradára láti ilé OLúWA, ó sì mú arákùnrin Jehoiakini, Sedekiah, jẹ ọba lórí Juda àti Jerusalẹmu. Sedekiah jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlá. Ó sì ṣe búburú ní ojú OLúWA Ọlọ́run rẹ̀, kò sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jeremiah wòlíì ẹni tí ó sọ̀rọ̀ OLúWA. Ó sì tún ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Nebukadnessari pẹ̀lú, ẹni tí ó mú kí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra. Ó sì di ọlọ́run líle, ó sì mú ọkàn rẹ̀ le láti má lè yípadà sí OLúWA, Ọlọ́run Israẹli. Síwájú sí i gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn sì di ẹni tí ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi, pẹ̀lú gbogbo ìríra àwọn orílẹ̀-èdè wọ́n sì sọ ilé OLúWA di èérí, tí ó ti yà sí mímọ́ ní Jerusalẹmu. OLúWA, Ọlọ́run àwọn baba wọn ránṣẹ́ sí wọn láti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, nítorí tí ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀ àti sí ibùgbé rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n ń kùn sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣẹ̀sín títí tí ìbínú Ọlọ́run fi ru sórí wọn, sí àwọn ènìyàn rẹ̀ kò sì ṣí àtúnṣe. Ó sì mú wá sórí wọn ọba àwọn ará Babeli tí wọ́n bá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn jà pẹ̀lú idà ní ilẹ̀ ibi mímọ́, kò sì ní ìyọ́nú sí àgbà ọkùnrin tàbí ọ̀dọ́mọdébìnrin, wúńdíá, tàbí arúgbó. Ọlọ́run sì fi gbogbo wọn lé Nebukadnessari lọ́wọ́. Ó sì mú gbogbo ohun èlò láti ilé Ọlọ́run lọ sí Babeli, ńlá àti kékeré àti ìṣúra ilé OLúWA àti ìṣúra ọba àti ìjòyè rẹ̀. Wọ́n sì fi iná sun ilé Ọlọ́run, wọ́n sì wó gbogbo ògiri ilé Jerusalẹmu, wọ́n sì jó gbogbo ààfin wọn, wọ́n sì ba gbogbo ohun èlò ibẹ̀ jẹ́. Ó sì kó èyí tí ó kù lọ sí Babeli àwọn tí ó rí ibi sá kúrò lẹ́nu idà wọ́n sì di ìránṣẹ́ fún un àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí tí ìjọba Persia fi gba agbára. Ilẹ̀ náà sì gbádùn ìsinmi rẹ̀, ní gbogbo ìgbà ìdahoro, òun sì ń sinmi títí àádọ́rin ọdún (70) fi pé ní ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ OLúWA tí a sọ láti ẹnu Jeremiah.