II. Kro 20:22-28

II. Kro 20:22-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí kọrin àti ìyìn, OLúWA rán ogun ẹ̀yìn sí àwọn ọkùnrin Ammoni àti Moabu àti òkè Seiri tí ó ń gbógun ti Juda, wọ́n sì kọlù wọ́n. Àwọn ọkùnrin Ammoni àti Moabu dìde dúró sí àwọn ọkùnrin tí ń gbé òkè Seiri láti pa wọ́n run túútúú. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sì ti pa àwọn ọkùnrin láti òkè Seiri, wọ́n sì ran ra wọn lọ́wọ́ láti pa ara wọn run. Nígbà tí àwọn ènìyàn Juda jáde sí ìhà ilé ìṣọ́ ní aginjù, wọn ń wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, òkú nìkan ni wọ́n rí tí ó ṣubú sí ilẹ̀, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí ààyè sá. Bẹ́ẹ̀ ni Jehoṣafati àti àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ láti kó ìkógun wọn, wọ́n sì rí lára wọn ọ̀pọ̀ iyebíye ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ju èyí tí wọ́n lè kó lọ. Ọ̀pọ̀ ìkógun sì wà níbẹ̀, èyí tí ó gbà wọ́n ní ọjọ́ mẹ́ta láti gbà pọ̀. Ní ọjọ́ kẹrin, wọn kó ara jọ pọ̀ ní Àfonífojì ìbùkún, níbi tí wọ́n ti ń fi ìbùkún fún OLúWA. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Àfonífojì ìbùkún títí di òní. Nígbà náà wọ́n darí pẹ̀lú Jehoṣafati, gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu padà pẹ̀lú ayọ̀ sí Jerusalẹmu, nítorí OLúWA ti fún wọn ní ìdí láti yọ̀ lórí àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n sì wọ Jerusalẹmu, wọ́n sì lọ sí ilé OLúWA pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn àti dùùrù àti ìpè.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa