Nigbati nwọn bẹ̀rẹ si ikọrin ati si iyìn, Oluwa yàn ogun-ẹhin si awọn ọmọ Ammoni, Moabu ati awọn ara òke Seiri, ti o wá si Juda, a si kọlù wọn. Awọn ọmọ Ammoni ati Moabu si dide si awọn ti ngbe òke Seiri, lati pa, ati lati run wọn tũtu: nigbati nwọn si pa awọn ti ngbe òke Seiri run tan, ẹnikini nṣe iranlọwọ lati run ẹnikeji. Nigbati Juda si de iha ile-iṣọ li aginju, nwọn wò awọn ọ̀pọlọpọ enia, si kiyesi i, okú ti o ṣubu lulẹ ni nwọn, ẹnikan kò sá asalà. Nigbati Jehoṣafati ati awọn enia rẹ̀ de lati kó ikogun wọn, nwọn ri lara wọn ọ̀pọlọpọ ọrọ̀, ati okú, ati ohun-elo iyebiye, nwọn si kójọ fun ara wọn, jù eyiti nwọn le kó lọ: nwọn si kó ikogun wọn jọ ni ijọ mẹta, nitoriti o sa papọ̀ju. Ati li ọjọ kẹrin nwọn kó ara wọn jọ li afonifoji Ibukún, nitori nibẹ ni nwọn fi ibukún fun Oluwa, nitorina ni a ṣe npe orukọ ibẹ na ni, Afonifoji Ibukún, titi di oni. Nigbana ni nwọn yipada, gbogbo awọn ọkunrin Juda ati Jerusalemu, ati Jehoṣafati niwaju wọn lati pada lọ si Jerusalemu pẹlu ayọ̀; nitori ti Oluwa ti mu wọn yọ̀ lori awọn ọta wọn. Nwọn si wá si Jerusalemu pẹlu ohun-elo orin, ati duru ati ipè si ile Oluwa.
Kà II. Kro 20
Feti si II. Kro 20
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Kro 20:22-28
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò