II. Kro 16:1-14
II. Kro 16:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI ọdun kẹrindilogoji ijọba Asa, Baaṣa, ọba Israeli, gòke wá si Juda, o si kọ́ Rama, nitori ki o má ba jẹ ki ẹnikan ki o jade, tabi ki o wọle tọ̀ Asa, ọba Juda lọ. Nigbana ni Asa mu fadakà ati wura jade lati inu iṣura ile Oluwa wá, ati ile ọba, o si ranṣẹ si Benhadadi, ọba Siria, ti ngbe Damasku, wipe, Majẹmu kan wà larin temi tirẹ, bi o ti wà lãrin baba mi ati baba rẹ; kiyesi i, mo fi fadakà ati wura ranṣẹ si ọ; lọ, bà majẹmu ti o ba Baaṣa, ọba Israeli dá jẹ, ki o le lọ kuro lọdọ mi. Benhadadi si gbọ́ ti Asa ọba, o si rán awọn olori ogun rẹ̀ si ilu Israeli wọnni, nwọn si kọlù Ijoni, ati Dani, ati Abel-Maimu, ati gbogbo ilu iṣura Naftali. O si ṣe, nigbati Baaṣa gbọ́, o ṣiwọ atikọ́ Rama, o si dá iṣẹ rẹ̀ duro. Ṣugbọn Asa ọba kó gbogbo Juda jọ; nwọn si kó okuta ati igi Rama lọ, eyiti Baaṣa nfi kọ́le; o si fi kọ́ Geba ati Mispa. Li àkoko na Hanani, ariran, wá sọdọ Asa, ọba Juda, o si wi fun u pe, Nitoriti iwọ gbẹkẹle ọba Siria, iwọ kò si gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun rẹ, nitorina ni ogun ọba Siria ṣe bọ́ lọwọ rẹ. Awọn ara Etiopia ati awọn ara Libia kì iha ise ogun nla, pẹlu ọ̀pọlọpọ kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin? ṣugbọn nitoriti iwọ gbẹkẹle Oluwa, on fi wọn le ọ lọwọ. Nitoriti oju Oluwa nlọ siwa sẹhin ni gbogbo aiye, lati fi agbara fun awọn ẹni ọlọkàn pípe si ọdọ rẹ̀. Ninu eyi ni iwọ hùwa aṣiwere: nitorina lati isisiyi lọ ogun yio ma ba ọ jà. Asa si binu si ariran na, o si fi i sinu tubu; nitoriti o binu si i niti eyi na. Asa si ni ninu awọn enia na lara li akokò na. Si kiyesi i, iṣe Asa ti iṣaju ati ti ikẹhin, wò o, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Juda ati Israeli. Ati li ọdun kọkandilogoji ijọba rẹ̀, Asa ṣe aisan li ẹsẹ rẹ̀, titi àrun rẹ̀ fi pọ̀ gidigidi: sibẹ ninu aisan rẹ̀ on kò wá Oluwa, bikòṣe awọn oniṣegun. Asa si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, o si kú li ọdun kọkanlelogoji ijọba rẹ̀. Nwọn si sìn i sinu isa-okú, ti o gbẹ́ fun ara rẹ̀ ni ilu Dafidi, nwọn si tẹ́ ẹ lori àkete ti a fi õrun-didùn kùn, ati oniruru turari ti a fi ọgbọ́n awọn alapolu pèse: nwọn si ṣe ijona nlanla fun u.
II. Kro 16:1-14 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọdún kẹrindinlogoji ìjọba Asa, ní ilẹ̀ Juda, Baaṣa ọba Israẹli gbógun ti Juda, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mọ odi Rama láti dí ojú ọ̀nà tí ó lọ sí ilẹ̀ Juda, kí ẹnikẹ́ni má baà lè lọ sí ọ̀dọ̀ Asa, ọba Juda, kí àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ má sì lè jáde. Nítorí náà, Asa kó fadaka ati wúrà láti ilé ìṣúra ilé OLUWA ati láti ààfin ranṣẹ sí Benhadadi, ọba Siria tí ó ń gbé Damasku, ó ranṣẹ sí i pé: “Jẹ́ kí àjọṣepọ̀ wà láàrin wa gẹ́gẹ́ bí ó ti wà láàrin àwọn baba wa. Fadaka ati wúrà yìí ni mo fi ta ọ́ lọ́rẹ; pa majẹmu tí ó wà láàrin ìwọ ati Baaṣa ọba Israẹli tì, kí ó baà lè kó ogun rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi.” Benhadadi gba ọ̀rọ̀ Asa, ó bá rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀ jáde láti lọ gbógun ti àwọn ìlú Israẹli. Wọ́n ṣẹgun Ijoni, Dani, Abeli Maimu ati gbogbo ìlú tí wọ́n kó ìṣúra pamọ́ sí ní ilẹ̀ Nafutali. Nígbà tí Baaṣa gbọ́ ohun tí ń ṣẹlẹ̀, ó dáwọ́ odi Rama tí ó ń mọ dúró. Asa bá kó àwọn eniyan jọ jákèjádò Juda, wọ́n lọ kó òkúta ati pákó tí Baaṣa fi ń kọ́ Rama, wọ́n lọ fi kọ́ Geba ati Misipa. Nígbà náà ni Hanani aríran, wá sọ́dọ̀ Asa, ọba Juda, ó wí fún un pé, “Nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, dípò kí o gbẹ́kẹ̀lé OLUWA Ọlọrun rẹ, àwọn ogun Siria ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ. Ṣebí ogun Etiopia ati Libia lágbára gidigidi? Ṣebí wọ́n ní ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹlẹ́ṣin? Ṣugbọn nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, ó fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn. Nítorí ojú OLUWA ń lọ síwá sẹ́yìn ní gbogbo ayé láti fi agbára rẹ̀ hàn fún àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí i. Ìwà òmùgọ̀ ni èyí tí o hù yìí; nítorí pé láti ìsinsìnyìí lọ nígbàkúùgbà ni o óo máa jagun.” Ọ̀rọ̀ yìí mú kí inú bí Asa sí wolii Hanani, ó sì kan ààbà mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ ninu túbú, nítorí inú bí i sí i fún ohun tí ó sọ. Asa ọba fi ìyà jẹ àwọn kan ninu àwọn ará ìlú ní àkókò náà. Gbogbo nǹkan tí Asa ọba ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni a kọ sinu ìwé ìtàn àwọn ọba Juda ati Israẹli. Ní ọdún kọkandinlogoji ìjọba Asa, àrùn burúkú kan mú un lẹ́sẹ̀, àrùn náà pọ̀ pupọ. Sibẹsibẹ, ninu àìsàn náà kàkà kí ó ké pe OLUWA fún ìwòsàn, ọ̀dọ̀ àwọn oníṣègùn ni ó lọ. Asa kú ní ọdún kọkanlelogoji ìjọba rẹ̀. Wọ́n sin ín sinu ibojì òkúta tí ó gbẹ́ fúnrarẹ̀ ní ìlú Dafidi. Wọ́n tẹ́ ẹ sórí àkéte, tí ó kún fún oniruuru turari tí àwọn tí wọ́n ń ṣe turari ṣe. Wọ́n sì dá iná ńlá kan láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀.
II. Kro 16:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọdún kẹrìn-dínlógójì ìjọba Asa, Baaṣa ọba Israẹli gòkè wá sí Juda ó sì kọlu Rama, láti ma bá a jẹ́ kí ẹnikẹ́ni lè jáde tàbí wọlé tọ Asa ọba Juda lọ. Nígbà náà ni Asa mú wúrà àti fàdákà jáde nínú ilé ìṣúra ilé OLúWA àti ààfin ọba ó sì ránṣẹ́ sí Beni-Hadadi ọba Siria, ẹni tí ń gbé ní Damasku, ó wí pé, “Májẹ̀mú kan wà láàrín èmi àti ìrẹ, bí ó ti wà láàrín baba mi àti baba rẹ. Ẹ wò ó, mo fi wúrà àti fàdákà ránṣẹ́ sí ọ; lọ, ba májẹ̀mú tí o bá Baaṣa ọba Israẹli dá jẹ́, kí ó lè lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.” Beni-Hadadi sì gbọ́ ti Asa ọba, ó sì rán àwọn olórí ogun rẹ̀ lọ sí àwọn ìlú Israẹli, wọ́n sì kọlu Ijoni, Dani, Abeli-Maimu, àti gbogbo ìlú ìṣúra Naftali. Nígbà tí Baaṣa gbọ́ èyí, ó sì dá kíkọ́ Rama dúró, ó sì dá iṣẹ́ rẹ̀ dúró. Nígbà náà ní ọba Asa kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda jọ, wọ́n sì kó òkúta àti igi Rama lọ èyí ti Baaṣa ń fi kọ́lé; ó sì fi kọ́ Geba àti Mispa. Ní àkókò náà wòlíì Hanani wá sí ọ̀dọ̀ Asa ọba Juda, ó sì wí fún un pé, “nítorí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, ìwọ kò sì gbẹ́kẹ̀lé OLúWA Ọlọ́run rẹ, nítorí náà ni ogún ọba Siria ṣe bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ. Àwa kì í ṣe ará Etiopia àti àwọn ará Libia àwọn alágbára ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹlẹ́ṣin? Síbẹ̀ nígbà tí ìwọ bá gbẹ́kẹ̀lé OLúWA yóò sì fi wọ́n lé ọwọ́ rẹ. Nítorí ojú OLúWA yí gbogbo ayé ká láti fi agbára fún àwọn ẹni tí ó ní ọkàn pípé sí i. Ìwọ ti ṣe ohun aṣiwèrè, láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ yóò wà lójú ogun.” Asa sì bínú pẹ̀lú sí wòlíì nítorí èyí, ó sì mú un bínú gidigidi tí ó sì fi mú un sínú túbú. Ní àkókò náà Asa sì ni díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà lára. Àwọn iṣẹ́ ìjọba Asa, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni akọ sínú ìwé ọba Juda àti Israẹli. Ní ọdún kọkàn-dínlógójì ìjọba rẹ̀, Asa sì ṣe àìsàn pẹ̀lú ààrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Bi ó tilẹ̀ jẹ pé ààrùn rẹ̀ lágbára, síbẹ̀ kódà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ OLúWA, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nìkan. Nígbà náà tí ó pé ọdún kọ́kànlélógójì rẹ̀, Asa kú, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn ìjọba baba rẹ̀, Wọ́n sì sin ín sínú isà òkú tí ó ti gbẹ́ jáde fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Wọ́n sì tẹ sí orí àkéte tí ó fi òórùn dídùn kún, àti onírúurú tùràrí tí a fi ọgbọ́n pèsè, wọ́n sì da iná ńlá nítorí rẹ̀.