II. Kro 14:11
II. Kro 14:11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Asa si ke pe Oluwa Ọlọrun rẹ̀, o si wipe, Oluwa! lọdọ rẹ bakanna ni fun ọ lati ràn alagbara enia lọwọ, tabi ẹniti kò li agbara: ràn wa lọwọ, Oluwa Ọlọrun wa; nitori ti awa gbẹkẹ le ọ, li orukọ rẹ li awa ntọ ọ̀pọlọpọ yi lọ, Oluwa, iwọ li Ọlọrun wa; máṣe jẹ ki enia ki o bori rẹ
II. Kro 14:11 Yoruba Bible (YCE)
Asa ké pe OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ó ní, “OLUWA, kò sí olùrànlọ́wọ́ tí ó dàbí rẹ nítorí pé o lè ran àwọn ọmọ ogun tí wọn kò lágbára lọ́wọ́ láti ṣẹgun àwọn tí wọ́n lágbára. Ràn wá lọ́wọ́, OLUWA Ọlọrun wa, nítorí pé ìwọ ni a gbẹ́kẹ̀lé. Ní orúkọ rẹ ni a jáde láti wá bá ogun ńlá yìí jà. OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun wa, má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣẹgun rẹ.”
II. Kro 14:11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà, Asa ké pe OLúWA Ọlọ́run baba a rẹ̀, ó sì wí pé “OLúWA kò sí ẹnìkan bí rẹ láti rán aláìlágbára lọ́wọ́ láti dójú kọ alágbára. Ràn wá lọ́wọ́, OLúWA Ọlọ́run wa, nítorí tí àwa gbẹ́kẹ̀lé ọ àti ní orúkọ rẹ ni àwa fi wá láti dojúkọ àwọn ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun yìí. OLúWA, ìwọ ni Ọlọ́run wa; má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kó ṣẹ́gun rẹ.”