I. Tim 1:5-7
I. Tim 1:5-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn opin aṣẹ na ni ifẹ lati ọkàn mimọ́ ati ẹri-ọkan rere ati igbagbọ́ aiṣẹtan wa. Lati inu eyiti awọn ẹlomiran ti yapa kuro ti nwọn si ya sapakan si ọrọ asan; Nwọn nfẹ ṣe olukọ ofin; òye ohun ti nwọn nwi kò yé wọn, tabi ti ohun ti nwọn ntẹnumọ́.
I. Tim 1:5-7 Yoruba Bible (YCE)
Ìdí tí mo fi pa àṣẹ yìí ni láti ta ìfẹ́ àtọkànwá jí ninu rẹ, pẹlu ẹ̀rí ọkàn rere ati igbagbọ tí kò lẹ́tàn. Àwọn mìíràn ti kùnà nípa irú èyí; wọ́n ti yipada sí ọ̀rọ̀ asán. Wọn á fẹ́ máa kọ́ni ní òfin, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò mọ ohun tí wọn ń sọ, ohun tí wọ́n sì ń sọ pẹlu ìdánilójú kò yé wọn.
I. Tim 1:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ète àṣẹ náà ni ìfẹ́ ti ń jáde wá láti inú ọkàn mímọ́ àti ẹ̀rí ọkàn rere àti ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn. Àwọn ẹlòmíràn ti yapa kúrò tí wọ́n sì yà sápá kan sí ọ̀rọ̀ asán. Wọ́n ń fẹ́ ṣe olùkọ́ òfin; òye ohun tí wọ́n ń wí kò yé wọn tàbí ti ohun tí wọ́n ń fi ìgboyà tẹnumọ́.