I. Tim 1:5-7

I. Tim 1:5-7 YBCV

Ṣugbọn opin aṣẹ na ni ifẹ lati ọkàn mimọ́ ati ẹri-ọkan rere ati igbagbọ́ aiṣẹtan wa. Lati inu eyiti awọn ẹlomiran ti yapa kuro ti nwọn si ya sapakan si ọrọ asan; Nwọn nfẹ ṣe olukọ ofin; òye ohun ti nwọn nwi kò yé wọn, tabi ti ohun ti nwọn ntẹnumọ́.