I. Tes 5:16-22
I. Tes 5:16-22 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo. Ẹ máa gbadura láì sinmi. Ẹ máa dúpẹ́ ninu ohun gbogbo nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọrun nípa Kristi Jesu fun yín. Ẹ má máa da omi tútù sí àwọn tí ó ní ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ lọ́kàn. Ẹ má máa fi ojú tẹmbẹlu ẹ̀bùn wolii. Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú, kí ẹ sì di èyí tí ó bá dára mú ṣinṣin. Ẹ máa takété sí ohunkohun tí ó bá burú.
I. Tes 5:16-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ mã yọ̀ nigbagbogbo. Ẹ mã gbadura li aisimi. Ẹ mã dupẹ ninu ohun gbogbo: nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun ninu Kristi Jesu fun nyin. Ẹ máṣe pa iná Ẹmí. Ẹ máṣe kẹgan isọtẹlẹ. Ẹ mã wadi ohun gbogbo daju; ẹ dì eyiti o dara mu ṣinṣin. Ẹ mã takéte si ohun gbogbo ti o jọ ibi.
I. Tes 5:16-22 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo. Ẹ máa gbadura láì sinmi. Ẹ máa dúpẹ́ ninu ohun gbogbo nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọrun nípa Kristi Jesu fun yín. Ẹ má máa da omi tútù sí àwọn tí ó ní ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ lọ́kàn. Ẹ má máa fi ojú tẹmbẹlu ẹ̀bùn wolii. Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú, kí ẹ sì di èyí tí ó bá dára mú ṣinṣin. Ẹ máa takété sí ohunkohun tí ó bá burú.
I. Tes 5:16-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo nínú ipòkípò tí o wù kí ẹ wà; nítorí pé, èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún yin nínú Kristi Jesu nítòótọ́. Ẹ má ṣe pa iná Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ má ṣe kẹ́gàn àwọn ti ń sọtẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ dán gbogbo nǹkan wò. Ẹ di èyí tí ṣe òtítọ́ mú. Ẹ yẹra fún ohunkóhun tí í ṣe ibi.