Ẹ mã yọ̀ nigbagbogbo.
Ẹ mã gbadura li aisimi.
Ẹ mã dupẹ ninu ohun gbogbo: nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun ninu Kristi Jesu fun nyin.
Ẹ máṣe pa iná Ẹmí.
Ẹ máṣe kẹgan isọtẹlẹ.
Ẹ mã wadi ohun gbogbo daju; ẹ dì eyiti o dara mu ṣinṣin.
Ẹ mã takéte si ohun gbogbo ti o jọ ibi.