I. Sam 8:4-9
I. Sam 8:4-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbogbo awọn agbà Israeli si ko ara wọn jọ, nwọn si tọ Samueli lọ si Rama, Nwọn si wi fun u pe, Kiye si i, iwọ di arugbo, awọn ọmọ rẹ kò si rin ni ìwa rẹ: njẹ fi ẹnikan jẹ ọba fun wa, ki o le ma ṣe idajọ wa, bi ti gbogbo orilẹ-ède. Ṣugbọn ohun na buru loju Samueli, nitori ti nwọn wipe, Fi ọba fun wa ki o le ma ṣe idajọ wa, Samueli si gbadura si Oluwa. Oluwa si wi fun Samueli pe, Gbọ́ ohùn awọn enia na ni gbogbo eyi ti nwọn sọ fun ọ: nitoripe iwọ ki nwọn kọ̀, ṣugbọn emi ni nwọn kọ̀ lati jẹ ọba lori wọn. Gẹgẹ bi gbogbo iṣe ti nwọn ṣe lati ọjọ ti mo ti mu nwọn jade ti Egipti wá, titi o si fi di oni, bi nwọn ti kọ̀ mi silẹ, ti nwọn si nsin awọn ọlọrun miran, bẹ̃ni nwọn ṣe si ọ pẹlu. Njẹ nitorina gbọ́ ohùn wọn: ṣugbọn lẹhin igbati iwọ ba ti jẹri si wọn tan, nigbana ni ki iwọ ki o si fi iwà ọba ti yio jẹ lori wọn hàn wọn.
I. Sam 8:4-9 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli bá kó ara wọn jọ, wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Samuẹli ní Rama; wọ́n wí fún un pé, “Wò ó, àgbà ti dé sí ọ, àwọn ọmọ rẹ kò sì tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere rẹ. Yan ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí ọba fún wa, tí yóo máa ṣe alákòóso wa bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.” Ọ̀rọ̀ náà kò dùn mọ́ Samuẹli ninu, pé àwọn eniyan náà ní kí ó fi ẹnìkan jọba lórí wọn. Samuẹli bá gbadura sí OLUWA. OLUWA dá Samuẹli lóhùn, ó ní, “Gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn eniyan náà wí fún ọ, nítorí pé kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, èmi ni wọ́n kọ̀ lọ́ba. Láti ìgbà tí mo ti kó wọn wá láti Ijipti títí di òní ni wọ́n ti kọ̀yìn sí mi, tí wọ́n sì ń bọ oriṣa. Ohun tí wọ́n ti ń ṣe sí mi ni wọ́n ń ṣe sí ọ yìí. Nítorí náà, gbọ́ tiwọn, ṣugbọn kìlọ̀ fún wọn gidigidi, kí o sì ṣe àlàyé gbogbo ohun tí ọba náà yóo máa ṣe sí wọn fún wọn dáradára.”
I. Sam 8:4-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn àgbàgbà ti Israẹli péjọpọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Samuẹli ní Rama. Wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ ti di arúgbó, àwọn ọmọ rẹ kò sì rìn ní ọ̀nà rẹ: Nísinsin yìí, yan ọba fún wa kí ó lè máa darí wa gẹ́gẹ́ bí i tí gbogbo orílẹ̀-èdè.” Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n wí pé, “Fún wa ní ọba tí yóò darí wa” Èyí kò tẹ́ Samuẹli lọ́rùn, ó sì gbàdúrà sí OLúWA. OLúWA sì sọ fún Samuẹli pé: “Gbọ́ ohùn àwọn ènìyàn náà, ní gbogbo èyí tí wọ́n sọ fún ọ; nítorí kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n Èmi ni wọ́n kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba lórí wọn. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde wá láti Ejibiti títí di ọjọ́ òní, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ń sin ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí ọ. Nísinsin yìí, gbọ́ tiwọn; ṣùgbọ́n kìlọ̀ fún wọn dáradára, kí o sì jẹ́ kí wọ́n mọ irú ohun tí ọba tí yóò jẹ́ lórí wọn yóò ṣe.”