SAMUẸLI KINNI 8

8
Àwọn Ọmọ Israẹli Bèèrè fún Ọba
1Nígbà tí àgbà dé sí Samuẹli, ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli. 2Joẹli ni orúkọ àkọ́bí, èyí àbúrò sì ń jẹ́ Abija. Beeriṣeba ni wọ́n ti ń ṣe adájọ́. 3Ṣugbọn wọn kò tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere baba wọn. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń dájọ́ èké.
4Gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli bá kó ara wọn jọ, wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Samuẹli ní Rama; 5wọ́n wí fún un pé, “Wò ó, àgbà ti dé sí ọ, àwọn ọmọ rẹ kò sì tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere rẹ. Yan ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí ọba fún wa, tí yóo máa ṣe alákòóso wa bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.” 6Ọ̀rọ̀ náà kò dùn mọ́ Samuẹli ninu, pé àwọn eniyan náà ní kí ó fi ẹnìkan jọba lórí wọn. Samuẹli bá gbadura sí OLUWA. 7OLUWA dá Samuẹli lóhùn, ó ní, “Gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn eniyan náà wí fún ọ, nítorí pé kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, èmi ni wọ́n kọ̀ lọ́ba. 8Láti ìgbà tí mo ti kó wọn wá láti Ijipti títí di òní ni wọ́n ti kọ̀yìn sí mi, tí wọ́n sì ń bọ oriṣa. Ohun tí wọ́n ti ń ṣe sí mi ni wọ́n ń ṣe sí ọ yìí. 9Nítorí náà, gbọ́ tiwọn, ṣugbọn kìlọ̀ fún wọn gidigidi, kí o sì ṣe àlàyé gbogbo ohun tí ọba náà yóo máa ṣe sí wọn fún wọn dáradára.”#Diut 17:14
10Samuẹli bá sọ gbogbo ohun tí OLUWA bá a sọ fún àwọn tí wọ́n ní kí ó fi ẹnìkan jọba lórí àwọn. 11Ó ṣe àlàyé fún wọn pé, “Bí ọba yín yóo ti máa ṣe yín nìyí: Yóo sọ àwọn ọmọkunrin yín di ọmọ ogun, àwọn kan ninu wọn yóo máa wa kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn kan yóo wà ninu ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń fi ẹsẹ̀ rìn, àwọn kan yóo máa gun ẹṣin níwájú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. 12Yóo fi àwọn kan ṣe ọ̀gágun fún ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun, àwọn kan yóo máa ṣe ọ̀gágun fún araadọta ọmọ ogun. Àwọn kan yóo máa ro oko rẹ̀, àwọn kan yóo sì máa kórè àwọn ohun ọ̀gbìn rẹ̀. Àwọn kan yóo máa rọ ohun ìjà fún un, ati àwọn ohun èlò kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. 13Àwọn ọmọbinrin yín ni yóo máa ṣe turari fún un, wọn óo sì máa se oúnjẹ fún un. 14Yóo gba ilẹ̀ oko yín tí ó dára jùlọ ati ọgbà àjàrà ati ti olifi yín, yóo sì fi fún àwọn iranṣẹ rẹ̀. 15Yóo gba ìdámẹ́wàá ọkà yín ati ti ọgbà àjàrà yín fún àwọn ẹmẹ̀wà ati àwọn iranṣẹ rẹ̀. 16Yóo gba àwọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin yín, ati àwọn mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín tí wọ́n dára jùlọ, yóo máa kó wọn ṣiṣẹ́. 17Yóo gba ìdámẹ́wàá agbo aguntan yín, ẹ̀yin gan-an yóo sì di ẹrú rẹ̀. 18Nígbà tí ó bá yá, ẹ̀yin gan-an ni ẹ óo tún máa pariwo ọba yín tí ẹ yàn fún ara yín, ṣugbọn OLUWA kò ní da yín lóhùn.”
19Ṣugbọn àwọn eniyan náà kọ̀, wọn kò gba ohun tí Samuẹli wí gbọ́. Wọ́n ní, “Rárá o! A ṣá fẹ́ ní ọba ni. 20Kí àwa náà lè dàbí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, kí ọba wa lè máa ṣe àkóso wa, kí ó máa ṣiwaju wa lójú ogun, kí ó sì máa jà fún wa.” 21Nígbà tí Samuẹli gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n wí, ó lọ sọ fún OLUWA. 22OLUWA sọ fún Samuẹli pé, “Ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, kí o sì yan ọba fún wọn.” Samuẹli bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí olukuluku pada lọ sí ìlú rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

SAMUẸLI KINNI 8: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀