I. Sam 23:16-18
I. Sam 23:16-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jonatani ọmọ Saulu si dide, o si tọ Dafidi lọ ninu igbo na, o si gba a ni iyanju nipa ti Ọlọrun. On si wi fun u pe, Máṣe bẹru: nitori ọwọ́ Saulu baba mi kì yio tẹ̀ ọ: iwọ ni yio jọba lori Israeli, emi ni yio si ṣe ibikeji rẹ; Saulu baba mi mọ̀ bẹ̃ pẹlu. Awọn mejeji si ṣe adehun niwaju Oluwa; Dafidi si joko ninu igbo na. Jonatani si lọ si ile rẹ̀.
I. Sam 23:16-18 Yoruba Bible (YCE)
Jonatani ọmọ Saulu wá a lọ sibẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbà á níyànjú. Ó sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, nítorí pé ọwọ́ Saulu, baba mi, kò ní tẹ̀ ọ́. O óo jọba lórí Israẹli, n óo sì jẹ́ igbákejì rẹ.” Àwọn mejeeji dá majẹmu níwájú OLUWA; Dafidi dúró ní Horeṣi, Jonatani sì pada sílé.
I. Sam 23:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jonatani ọmọ Saulu sì dìde, ó sì tọ Dafidi lọ nínú igbó Horeṣi, ó sì gbà á ní ìyànjú nípa ti Ọlọ́run. Òun sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù, nítorí tí ọwọ́ Saulu baba mi kì yóò tẹ̀ ọ́: ìwọ ni yóò jẹ ọba lórí Israẹli, èmi ni yóò sì ṣe ibìkejì rẹ; Saulu baba mi mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.” Àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn níwájú OLúWA; Dafidi sì jókòó nínú igbó Horeṣi. Jonatani sì lọ sí ilé rẹ̀.