SAMUẸLI KINNI 23

23
Dafidi Gba Ìlú Keila Sílẹ̀
1Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé àwọn ará Filistia ń gbógun ti àwọn ará Keila, wọ́n sì ń jí ọkà wọn kó ní ibi ìpakà, 2ó bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ṣé kí n gbógun ti àwọn ará Filistia?”
OLUWA dáhùn pé, “Gbógun tì wọ́n kí o sì gba àwọn ará Keila sílẹ̀.”
3Àwọn ọkunrin tí ó wà lọ́dọ̀ Dafidi sì sọ fún un pé, “Ní Juda tí a wà níhìn-ín, inú ewu ni a wà, báwo ni yóo ti rí nígbà tí a bá tún lọ gbógun ti àwọn ará Filistia ní Keila?” 4Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ OLUWA lẹ́ẹ̀kan sí i pé, bóyá kí òun lọ tabi kí òun má lọ. OLUWA sì dáhùn pé, “Lọ sí Keila nítorí n óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ará Filistia.” 5Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bá lọ gbógun ti àwọn ará Filistia ní Keila, wọ́n pa ọpọlọpọ ninu wọn, wọ́n sì kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe gba àwọn ará Keila sílẹ̀.
6Nígbà tí Abiatari, ọmọ Ahimeleki sá tọ Dafidi lọ ní Keila, ó mú aṣọ efodu kan lọ́wọ́.
7Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi wà ní Keila, ó sọ pé, “Ọlọ́run ti fi Dafidi lé mi lọ́wọ́, nítorí ó ti ti ara rẹ̀ mọ́ inú ìlú olódi tí ó ní ìlẹ̀kùn, tí ó sì lágbára.” 8Saulu bá pe gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ láti gbógun ti Keila kí wọ́n sì ká Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ mọ́ ìlú náà.
9Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé Saulu ń gbèrò ibi, ó pe Abiatari alufaa kí ó mú aṣọ efodu wá, láti ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Ọlọrun. 10Dafidi ní, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli, èmi iranṣẹ rẹ gbọ́ pé Saulu ti pinnu láti wá gbógun ti Keila ati láti pa á run nítorí mi. 11Ǹjẹ́ àwọn alàgbà Keila yóo fà mí lé Saulu lọ́wọ́? Ṣe Saulu yóo wá gẹ́gẹ́ bí mo ti gbọ́? Jọ̀wọ́, OLUWA Ọlọrun Israẹli, fún mi ní èsì.”
OLUWA sì dáhùn pé, “Saulu yóo wá.”
12Dafidi tún bèèrè pé, “Ǹjẹ́ àwọn alàgbà Keila yóo fà mí lé e lọ́wọ́?”
OLUWA dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, wọn yóo fà ọ́ lé e lọ́wọ́.”
13Nítorí náà, Dafidi ati ẹgbẹta (600) àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ kúrò ní Keila lẹsẹkẹsẹ. Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi ti kúrò ní Keila, kò lọ gbógun ti Keila mọ́.
Dafidi Ń Gbé Orí Òkè
14Dafidi bá ń lọ gbé orí òkè kan tí ó ṣe é farapamọ́ sí ní aṣálẹ̀ Sifi. Saulu ń wá a lojoojumọ láti pa á, ṣugbọn Ọlọrun kò fi Dafidi lé e lọ́wọ́. 15Ẹ̀rù ba Dafidi nítorí pé Saulu ń wá ọ̀nà láti pa á.
Dafidi ń gbé aṣálẹ̀ Sifi ni Horeṣi. 16Jonatani ọmọ Saulu wá a lọ sibẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbà á níyànjú. 17Ó sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, nítorí pé ọwọ́ Saulu, baba mi, kò ní tẹ̀ ọ́. O óo jọba lórí Israẹli, n óo sì jẹ́ igbákejì rẹ.” 18Àwọn mejeeji dá majẹmu níwájú OLUWA; Dafidi dúró ní Horeṣi, Jonatani sì pada sílé.#1 Sam 18:3
19Àwọn ará Sifi kan lọ sọ́dọ̀ Saulu ní Gibea, wọ́n sọ fún un pé, “Dafidi sá pamọ́ sáàrin wa ní Horeṣi ní orí òkè Hakila tí ó wà ní ìhà gúsù Jeṣimoni. 20Nítorí náà, wá sọ́dọ̀ wa nígbà tí o bá fẹ́, a óo sì fà á lé ọ lọ́wọ́.”#O. Daf 54:Àkọlé.
21Saulu dáhùn pé, “OLUWA yóo bukun yín nítorí pé ẹ káàánú mi. 22Ẹ lọ nisinsinyii kí ẹ sì tún ṣe ìwádìí dáradára nípa ibi tí ó wà, ati ẹni tí ó rí i níbẹ̀; nítorí mo gbọ́ pé alárèékérekè ẹ̀dá ni Dafidi. 23Ẹ mọ gbogbo ibi tíí máa ń sá pamọ́ sí dájúdájú, kí ẹ sì wá ròyìn fún mi. N óo ba yín lọ; bí ó bá wà níbẹ̀, n óo wá a kàn, bí ó bá tilẹ̀ wà láàrin ẹgbẹẹgbẹrun eniyan ilẹ̀ Juda.”
24Wọ́n bá pada sí Sifi ṣáájú Saulu. Ṣugbọn Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ ti wà ní aṣálẹ̀ Maoni tí ó wà ní Araba lápá ìhà gúsù Jeṣimoni. 25Saulu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ láti wá Dafidi. Ṣugbọn Dafidi gbọ́ nípa rẹ̀, ó sì lọ sá pamọ́ sí ibi òkúta kan tí ó wà ní aṣálẹ̀ Maoni. Nígbà tí Saulu gbọ́, ó lépa Dafidi lọ sí aṣálẹ̀ Maoni. 26Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ wà ní apá kan òkè náà, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì wà ní apá keji. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ń múra láti sá fún Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ nítorí pé wọ́n ń rọ̀gbà yí wọn ká láti mú wọn. 27Nígbà náà ni oníṣẹ́ kan wá sọ fún Saulu pé, “Pada wá kíákíá, nítorí pé àwọn ará Filistia ti gbógun ti ilẹ̀ wa.” 28Nítorí náà, Saulu pada lẹ́yìn Dafidi, ó sì lọ bá àwọn ará Filistia jà. Nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọ́n ṣe ń pe òkè náà ní Àpáta Àsálà. 29Láti ibẹ̀, Dafidi lọ farapamọ́ sí Engedi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

SAMUẸLI KINNI 23: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀