I. Sam 23:13-14
I. Sam 23:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti wọn to ẹgbẹta enia si dide, nwọn lọ kuro ni Keila, nwọn si lọ si ibikibi ti nwọn le lọ. A si wi fun Saulu pe, Dafidi ti sa kuro ni Keila; ko si lọ si Keila mọ. Dafidi si ngbe ni aginju, nibiti o ti sa pamọ si, o si ngbe nibi oke-nla kan li aginju Sifi. Saulu si nwá a lojojumọ, ṣugbọn Ọlọrun ko fi le e lọwọ.
I. Sam 23:13-14 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, Dafidi ati ẹgbẹta (600) àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ kúrò ní Keila lẹsẹkẹsẹ. Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi ti kúrò ní Keila, kò lọ gbógun ti Keila mọ́. Dafidi bá ń lọ gbé orí òkè kan tí ó ṣe é farapamọ́ sí ní aṣálẹ̀ Sifi. Saulu ń wá a lojoojumọ láti pa á, ṣugbọn Ọlọrun kò fi Dafidi lé e lọ́wọ́.
I. Sam 23:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n tó ẹgbẹ̀ta ènìyàn sì dìde, wọ́n lọ kúrò ní Keila, wọ́n sì lọ sí ibikíbi tí wọ́n lè rìn lọ. A sì wí fún Saulu pé, “Dafidi ti sá kúrò ní Keila; kò sì lọ sí Keila mọ́.” Dafidi sì ń gbé ní aginjù, níbi tí ó ti sápamọ́ sí, ó sì ń gbé níbi òkè ńlá kan ní aginjù Sifi. Saulu sì ń wá a lójoojúmọ́, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò fi lé e lọ́wọ́.