I. Sam 23:1-29

I. Sam 23:1-29 Bibeli Mimọ (YBCV)

NWỌN si wi fun Dafidi pe, Sa wõ awọn ara Filistia mba ara Keila jagun, nwọn si jà ilẹ ipakà wọnni li ole. Dafidi si bere lọdọ Oluwa pe, Ki emi ki o lọ kọlu awọn ara Filistia wọnyi bi? Oluwa si wi fun Dafidi pe. Lọ, ki o si kọlu awọn ara Filistia ki o si gbà Keila silẹ. Awọn ọmọkunrin ti o wà lọdọ Dafidi si wi fun u pe, Wõ, awa mbẹ̀ru nihinyi ni Juda; njẹ yio ti ri nigbati awa ba de Keila lati fi oju ko ogun awọn ara Filistia? Dafidi si tun bere lọdọ Oluwa. Oluwa si da a lohùn, o si wipe, Dide, ki o sọkalẹ lọ si Keila, nitoripe emi o fi awọn ara Filistia na le ọ lọwọ. Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ si Keila, nwọn si ba awọn ara Filistia jà, nwọn si ko ohun ọsìn wọn, nwọn si fi iparun nla pa wọn. Dafidi si gbà awọn ara Keila silẹ. O si ṣe, nigbati Abiatari ọmọ Ahimeleki fi sa tọ Dafidi lọ ni Keila, o sọkalẹ ton ti efodu kan lọwọ rẹ̀, A si sọ fun Saulu pe, Dafidi wa si Keila. Saulu si wipe, Ọlọrun ti fi i le mi lọwọ; nitoripe a ti dí i mọ tan, nitori o wọ inu ilu ti o ni ilẹkun ati ikere. Saulu si pe gbogbo awọn enia na jọ si ogun, lati sọkalẹ lọ si Keila, lati ká Dafidi mọ ati awọn ọmọkunrin rẹ̀. Dafidi si mọ̀ pe Saulu ti gbèro buburu si on; o si wi fun Abiatari alufa na pe, Mu efodu na wá nihinyi. Dafidi si wipe Oluwa Ọlọrun Israeli, lõtọ ni iranṣẹ rẹ ti gbọ́ pe Saulu nwá ọ̀na lati wá si Keila, lati wá fọ ilu na nitori mi. Awọn agba ilu Keila yio fi mi le e lọwọ bi? Saulu yio ha sọkalẹ, gẹgẹ bi iranṣẹ rẹ ti gbọ́ bi? Oluwa Ọlọrun Israeli, emi bẹ̀ ọ, wi fun iranṣẹ rẹ. Oluwa si wipe, Yio sọkalẹ wá. Dafidi si wipe, Awọn agbà ilu Keila yio fi emi ati awọn ọmọkunrin mi le Saulu lọwọ bi? Oluwa si wipe, Nwọn o fi ọ le wọn lọwọ. Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti wọn to ẹgbẹta enia si dide, nwọn lọ kuro ni Keila, nwọn si lọ si ibikibi ti nwọn le lọ. A si wi fun Saulu pe, Dafidi ti sa kuro ni Keila; ko si lọ si Keila mọ. Dafidi si ngbe ni aginju, nibiti o ti sa pamọ si, o si ngbe nibi oke-nla kan li aginju Sifi. Saulu si nwá a lojojumọ, ṣugbọn Ọlọrun ko fi le e lọwọ. Dafidi si ri pe, Saulu ti jade lati wá ẹmi on kiri: Dafidi si wà li aginju Sifi ninu igbo kan. Jonatani ọmọ Saulu si dide, o si tọ Dafidi lọ ninu igbo na, o si gba a ni iyanju nipa ti Ọlọrun. On si wi fun u pe, Máṣe bẹru: nitori ọwọ́ Saulu baba mi kì yio tẹ̀ ọ: iwọ ni yio jọba lori Israeli, emi ni yio si ṣe ibikeji rẹ; Saulu baba mi mọ̀ bẹ̃ pẹlu. Awọn mejeji si ṣe adehun niwaju Oluwa; Dafidi si joko ninu igbo na. Jonatani si lọ si ile rẹ̀. Awọn ara Sifi si goke tọ Saulu wá si Gibea, nwọn si wipe, Ṣe Dafidi ti fi ara rẹ̀ pamọ sọdọ wa ni ibi ti o to sa pamọ si ni igbo, ni oke Hakila, ti o wà niha gusu ti Jeṣimoni? Njẹ nisisiyi, Ọba, sọkalẹ wá gẹgẹ bi gbogbo ifẹ ti o wà li ọkàn rẹ lati sọkalẹ; ipa ti awa ni lati fi i le ọba lọwọ. Saulu si wipe, Alabukun fun li ẹnyin nipa ti Oluwa; nitoripe ẹnyin ti kãnu fun mi. Lọ, emi bẹ̀ nyin, ẹ tun mura, ki ẹ si mọ̀, ki ẹ si ri ibi ti ẹsẹ rẹ̀ gbe wà, ati ẹniti o ri i nibẹ: nitoriti ati sọ fun mi pe, ọgbọ́n li o nlò jọjọ. Ẹ si wò, ki ẹ si mọ̀ ibi isapamọ ti ima sapamọ si, ki ẹ si tun pada tọ mi wá, nitori ki emi ki o le mọ̀ daju; emi o si ba nyin lọ: yio si ṣe, bi o ba wà ni ilẹ Israeli, emi o si wá a li awari ninu gbogbo ẹgbẹrun Juda. Nwọn si dide, nwọn si ṣaju Saulu lọ si Sifi: ṣugbọn Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ wà li aginju Maoni, ni pẹtẹlẹ niha gusu ti Jeṣimoni. Saulu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ iwá a. Nwọn si sọ fun Dafidi: o si sọkalẹ wá si ibi okuta kan, o si joko li aginju ti Maoni. Saulu si gbọ́, o si lepa Dafidi li aginju Maoni. Saulu si nrin li apakan oke kan, Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ li apa keji oke na: Dafidi si yara lati sa kuro niwaju Saulu; nitoripe Saulu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti rọ̀gba yi Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ka lati mu wọn. Ṣugbọn onṣẹ kan si tọ Saulu wá, o si wipe, iwọ yara ki o si wá, nitoriti awọn Filistini ti gbe ogun tì ilẹ wa. Saulu si pada kuro ni lilepa Dafidi, o si lọ ipade awọn Filistini: nitorina ni nwọn si se npe ibẹ̀ na ni Selahammalekoti, (ni itumọ rẹ̀, okuta ipinyà.) Dafidi ti goke lati ibẹ lọ, o si joko nibi ti o sapamọ si ni Engedi.

I. Sam 23:1-29 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé àwọn ará Filistia ń gbógun ti àwọn ará Keila, wọ́n sì ń jí ọkà wọn kó ní ibi ìpakà, ó bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ṣé kí n gbógun ti àwọn ará Filistia?” OLUWA dáhùn pé, “Gbógun tì wọ́n kí o sì gba àwọn ará Keila sílẹ̀.” Àwọn ọkunrin tí ó wà lọ́dọ̀ Dafidi sì sọ fún un pé, “Ní Juda tí a wà níhìn-ín, inú ewu ni a wà, báwo ni yóo ti rí nígbà tí a bá tún lọ gbógun ti àwọn ará Filistia ní Keila?” Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ OLUWA lẹ́ẹ̀kan sí i pé, bóyá kí òun lọ tabi kí òun má lọ. OLUWA sì dáhùn pé, “Lọ sí Keila nítorí n óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ará Filistia.” Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bá lọ gbógun ti àwọn ará Filistia ní Keila, wọ́n pa ọpọlọpọ ninu wọn, wọ́n sì kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe gba àwọn ará Keila sílẹ̀. Nígbà tí Abiatari, ọmọ Ahimeleki sá tọ Dafidi lọ ní Keila, ó mú aṣọ efodu kan lọ́wọ́. Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi wà ní Keila, ó sọ pé, “Ọlọ́run ti fi Dafidi lé mi lọ́wọ́, nítorí ó ti ti ara rẹ̀ mọ́ inú ìlú olódi tí ó ní ìlẹ̀kùn, tí ó sì lágbára.” Saulu bá pe gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ láti gbógun ti Keila kí wọ́n sì ká Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ mọ́ ìlú náà. Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé Saulu ń gbèrò ibi, ó pe Abiatari alufaa kí ó mú aṣọ efodu wá, láti ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Ọlọrun. Dafidi ní, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli, èmi iranṣẹ rẹ gbọ́ pé Saulu ti pinnu láti wá gbógun ti Keila ati láti pa á run nítorí mi. Ǹjẹ́ àwọn alàgbà Keila yóo fà mí lé Saulu lọ́wọ́? Ṣe Saulu yóo wá gẹ́gẹ́ bí mo ti gbọ́? Jọ̀wọ́, OLUWA Ọlọrun Israẹli, fún mi ní èsì.” OLUWA sì dáhùn pé, “Saulu yóo wá.” Dafidi tún bèèrè pé, “Ǹjẹ́ àwọn alàgbà Keila yóo fà mí lé e lọ́wọ́?” OLUWA dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, wọn yóo fà ọ́ lé e lọ́wọ́.” Nítorí náà, Dafidi ati ẹgbẹta (600) àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ kúrò ní Keila lẹsẹkẹsẹ. Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi ti kúrò ní Keila, kò lọ gbógun ti Keila mọ́. Dafidi bá ń lọ gbé orí òkè kan tí ó ṣe é farapamọ́ sí ní aṣálẹ̀ Sifi. Saulu ń wá a lojoojumọ láti pa á, ṣugbọn Ọlọrun kò fi Dafidi lé e lọ́wọ́. Ẹ̀rù ba Dafidi nítorí pé Saulu ń wá ọ̀nà láti pa á. Dafidi ń gbé aṣálẹ̀ Sifi ni Horeṣi. Jonatani ọmọ Saulu wá a lọ sibẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbà á níyànjú. Ó sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, nítorí pé ọwọ́ Saulu, baba mi, kò ní tẹ̀ ọ́. O óo jọba lórí Israẹli, n óo sì jẹ́ igbákejì rẹ.” Àwọn mejeeji dá majẹmu níwájú OLUWA; Dafidi dúró ní Horeṣi, Jonatani sì pada sílé. Àwọn ará Sifi kan lọ sọ́dọ̀ Saulu ní Gibea, wọ́n sọ fún un pé, “Dafidi sá pamọ́ sáàrin wa ní Horeṣi ní orí òkè Hakila tí ó wà ní ìhà gúsù Jeṣimoni. Nítorí náà, wá sọ́dọ̀ wa nígbà tí o bá fẹ́, a óo sì fà á lé ọ lọ́wọ́.” Saulu dáhùn pé, “OLUWA yóo bukun yín nítorí pé ẹ káàánú mi. Ẹ lọ nisinsinyii kí ẹ sì tún ṣe ìwádìí dáradára nípa ibi tí ó wà, ati ẹni tí ó rí i níbẹ̀; nítorí mo gbọ́ pé alárèékérekè ẹ̀dá ni Dafidi. Ẹ mọ gbogbo ibi tíí máa ń sá pamọ́ sí dájúdájú, kí ẹ sì wá ròyìn fún mi. N óo ba yín lọ; bí ó bá wà níbẹ̀, n óo wá a kàn, bí ó bá tilẹ̀ wà láàrin ẹgbẹẹgbẹrun eniyan ilẹ̀ Juda.” Wọ́n bá pada sí Sifi ṣáájú Saulu. Ṣugbọn Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ ti wà ní aṣálẹ̀ Maoni tí ó wà ní Araba lápá ìhà gúsù Jeṣimoni. Saulu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ láti wá Dafidi. Ṣugbọn Dafidi gbọ́ nípa rẹ̀, ó sì lọ sá pamọ́ sí ibi òkúta kan tí ó wà ní aṣálẹ̀ Maoni. Nígbà tí Saulu gbọ́, ó lépa Dafidi lọ sí aṣálẹ̀ Maoni. Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ wà ní apá kan òkè náà, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì wà ní apá keji. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ń múra láti sá fún Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ nítorí pé wọ́n ń rọ̀gbà yí wọn ká láti mú wọn. Nígbà náà ni oníṣẹ́ kan wá sọ fún Saulu pé, “Pada wá kíákíá, nítorí pé àwọn ará Filistia ti gbógun ti ilẹ̀ wa.” Nítorí náà, Saulu pada lẹ́yìn Dafidi, ó sì lọ bá àwọn ará Filistia jà. Nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọ́n ṣe ń pe òkè náà ní Àpáta Àsálà. Láti ibẹ̀, Dafidi lọ farapamọ́ sí Engedi.

I. Sam 23:1-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Wọ́n sì wí fún Dafidi pé, “Sá wò ó, àwọn ará Filistini ń bá ará Keila jagun, wọ́n sì ja àwọn ilẹ̀ ìpakà lólè.” Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ OLúWA pé, “Ṣé kí èmi ó lọ kọlu àwọn ará Filistini wọ̀nyí bí?” OLúWA sì wí fún Dafidi pé, “Lọ kí o sì kọlu àwọn ará Filistini kí o sì gba Keila sílẹ̀.” Àwọn ọmọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Dafidi sì wí fún un pé, “Wò ó, àwa ń bẹ̀rù níhìn-ín yìí ní Juda; ǹjẹ́ yóò ti rí nígbà ti àwa bá dé Keila láti fi ojú ko ogun àwọn ara Filistini?” Dafidi sì tún béèrè lọ́dọ̀ OLúWA. OLúWA sì dá a lóhùn, ó sì wí pé, “Dìde, kí o sọ̀kalẹ̀ lọ sí Keila, nítorí pé èmi ó fi àwọn ará Filistini náà lé ọ lọ́wọ́.” Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Keila, wọ́n sì bá àwọn ará Filistini jà, wọ́n sì kó ohun ọ̀sìn wọn, wọ́n sì fi ìparun ńlá pa wọ́n. Dafidi sì gba àwọn ará Keila sílẹ̀. Ó sì ṣe, nígbà tí Abiatari ọmọ Ahimeleki fi sá tọ Dafidi lọ ní Keila, ó sọ̀kalẹ̀ òun pẹ̀lú efodu kan lọ́wọ́ rẹ̀. A sì sọ fún Saulu pé Dafidi wá sí Keila. Saulu sì wí pé, “Ọlọ́run ti fi í lé mi lọ́wọ́; nítorí tí ó ti sé ara rẹ̀ mọ́ ní ti wíwá tí ó wá sí ìlú tí ó ní ìlẹ̀kùn àti kẹrẹ.” Saulu sì pe gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ sí ogun, láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Keila, láti ká Dafidi mọ́ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Dafidi sì mọ̀ pé Saulu ti gbèrò búburú sí òun; ó sì wí fún Abiatari àlùfáà náà pé, “Mú efodu náà wá níhìn-ín-yìí!” Dafidi sì wí pé, “OLúWA Ọlọ́run Israẹli, Lóòótọ́ ni ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ pé Saulu ń wá ọ̀nà láti wá sí Keila, láti wá fọ́ ìlú náà nítorí mi. Àwọn àgbà ìlú Keila yóò fi mí lé e lọ́wọ́ bí? Saulu yóò ha sọ̀kalẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ bí?” OLúWA Ọlọ́run Israẹli, èmi bẹ̀ ọ́, wí fún ìránṣẹ́ rẹ. OLúWA sì wí pé, “Yóò sọ̀kalẹ̀ wá.” Dafidi sì wí pé, “Àwọn àgbà ìlú Keila yóò fi èmi àti àwọn ọmọkùnrin mi lé Saulu lọ́wọ́ bí?” OLúWA sì wí pé, “Wọn ó fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́.” Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n tó ẹgbẹ̀ta ènìyàn sì dìde, wọ́n lọ kúrò ní Keila, wọ́n sì lọ sí ibikíbi tí wọ́n lè rìn lọ. A sì wí fún Saulu pé, “Dafidi ti sá kúrò ní Keila; kò sì lọ sí Keila mọ́.” Dafidi sì ń gbé ní aginjù, níbi tí ó ti sápamọ́ sí, ó sì ń gbé níbi òkè ńlá kan ní aginjù Sifi. Saulu sì ń wá a lójoojúmọ́, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò fi lé e lọ́wọ́. Nígbà tí Dafidi wà ní Horeṣi ní aginjù Sifi, Dafidi sì rí i pé, Saulu ti jáde láti wá ẹ̀mí òun kiri. Jonatani ọmọ Saulu sì dìde, ó sì tọ Dafidi lọ nínú igbó Horeṣi, ó sì gbà á ní ìyànjú nípa ti Ọlọ́run. Òun sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù, nítorí tí ọwọ́ Saulu baba mi kì yóò tẹ̀ ọ́: ìwọ ni yóò jẹ ọba lórí Israẹli, èmi ni yóò sì ṣe ibìkejì rẹ; Saulu baba mi mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.” Àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn níwájú OLúWA; Dafidi sì jókòó nínú igbó Horeṣi. Jonatani sì lọ sí ilé rẹ̀. Àwọn ará Sifi sì gòkè tọ Saulu wá sí Gibeah, wọ́n sì wí pé, “Ṣé Dafidi ti fi ara rẹ̀ pamọ́ sọ́dọ̀ wa ní ibi gíga ìsápamọ́sí ní Horeṣi, ní òkè Hakila, tí ó wà níhà gúúsù ti Jeṣimoni. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ọba, sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bi gbogbo ìfẹ́ tí ó wà ní ọkàn rẹ láti sọ̀kalẹ̀: ipa tí àwa ní láti fi lé ọba lọ́wọ́.” Saulu sì wí pé, “Alábùkún fún ni ẹ̀yin nípa OLúWA; nítorí pé ẹ̀yin ti káàánú fún mi. Lọ, èmi bẹ̀ yín, ẹ tún múra, kí ẹ sì mọ̀ ki ẹ si rí ibi tí ẹsẹ̀ rẹ̀ gbé wà, àti ẹni tí ó rí níbẹ̀: nítorí tí a ti sọ fún mi pé, ọgbọ́n ni ó ń lò jọjọ. Ẹ sì wò, kí ẹ sì mọ ibi ìsápamọ́ tí ó máa ń sápamọ́ sí, kí ẹ sì tún padà tọ̀ mí wá, kí èmi lè mọ̀ dájú; èmi ó sì bá yín lọ: yóò sì ṣe bí ó bá wà ní ilẹ̀ Israẹli, èmi ó sì wá a ní àwárí nínú gbogbo ẹgbẹ̀rún Juda!” Wọ́n sì dìde, wọ́n sì ṣáájú Saulu lọ sí Sifi: ṣùgbọ́n Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wà ní aginjù Maoni, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ níhà gúúsù ti Jeṣimoni. Saulu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ ń wá a. Wọ́n sì sọ fún Dafidi: ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí ibi òkúta kan, ó sì jókòó ní aginjù ti Maoni. Saulu sì gbọ́, ó sì lépa Dafidi ní aginjù Maoni. Saulu sì ń rin apá kan òkè kan, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní apá kejì òkè náà. Dafidi sì yára láti sá kúrò níwájú Saulu; nítorí pé Saulu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ti rọ̀gbà yí Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ká láti mú wọn. Ṣùgbọ́n oníṣẹ́ kan sì tọ Saulu wá ó sì wí pé, “Ìwọ yára kí o sì wá, nítorí tí àwọn Filistini ti gbé ogun ti ilẹ̀ wa.” Saulu sì padà kúrò ní lílépa Dafidi, ó sì lọ pàdé àwọn Filistini nítorí náà ni wọ́n sì ṣe ń pe ibẹ̀ náà ní Selahamalekoti (èyí tí ó túmọ̀ sí “Òkúta Ìpinyà”). Dafidi sì gòkè láti ibẹ̀ lọ, ó sì jókòó níbi tí ó sápamọ́ sí ní En-Gedi.