I. Sam 23:1-2
I. Sam 23:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
NWỌN si wi fun Dafidi pe, Sa wõ awọn ara Filistia mba ara Keila jagun, nwọn si jà ilẹ ipakà wọnni li ole. Dafidi si bere lọdọ Oluwa pe, Ki emi ki o lọ kọlu awọn ara Filistia wọnyi bi? Oluwa si wi fun Dafidi pe. Lọ, ki o si kọlu awọn ara Filistia ki o si gbà Keila silẹ.
I. Sam 23:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé àwọn ará Filistia ń gbógun ti àwọn ará Keila, wọ́n sì ń jí ọkà wọn kó ní ibi ìpakà, ó bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ṣé kí n gbógun ti àwọn ará Filistia?” OLUWA dáhùn pé, “Gbógun tì wọ́n kí o sì gba àwọn ará Keila sílẹ̀.”
I. Sam 23:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wọ́n sì wí fún Dafidi pé, “Sá wò ó, àwọn ará Filistini ń bá ará Keila jagun, wọ́n sì ja àwọn ilẹ̀ ìpakà lólè.” Dafidi sì béèrè lọ́dọ̀ OLúWA pé, “Ṣé kí èmi ó lọ kọlu àwọn ará Filistini wọ̀nyí bí?” OLúWA sì wí fún Dafidi pé, “Lọ kí o sì kọlu àwọn ará Filistini kí o sì gba Keila sílẹ̀.”