I. Sam 19:4-6
I. Sam 19:4-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jonatani si sọ̀rọ Dafidi ni rere fun Saulu baba rẹ̀, o si wi fun u pe, Ki a máṣe jẹ ki ọba ki o ṣẹ̀ si iranṣẹ rẹ̀, si Dafidi; nitori kò ṣẹ̀ ọ, ati nitoripe iṣẹ rẹ̀ dara gidigidi fun ọ. Nitoriti o mu ẹmi rẹ̀ lọwọ rẹ̀, o si pa Filistini na, Oluwa si ṣiṣẹ igbala nla fun gbogbo Israeli: iwọ ri i, o si yọ̀: njẹ, nitori kini iwọ o ṣe dẹṣẹ̀ si ẹjẹ alaiṣẹ, ti iwọ o fi pa Dafidi laiṣẹ? Saulu si gbọ́ ohùn Jonatani: Saulu si bura pe, Bi Oluwa ti wà lãye a ki yio pa a.
I. Sam 19:4-6 Yoruba Bible (YCE)
Jonatani sọ̀rọ̀ Dafidi ní rere níwájú Saulu, ó wí pé, “Kabiyesi, má ṣe nǹkankan burúkú sí iranṣẹ rẹ, Dafidi, nítorí kò ṣe ibi kan sí ọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo nǹkan tí ń ṣe ni ó ń jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún ọ. Ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wéwu láti pa Goliati, OLUWA sì ṣẹ́ ogun ńlá fún Israẹli. Nígbà tí o rí i inú rẹ dùn. Kí ló dé tí o fi ń wá ọ̀nà láti pa Dafidi láìṣẹ̀?” Saulu gbọ́rọ̀ sí Jonatani lẹ́nu, ó sì búra ní orúkọ OLUWA pé, “Bí OLUWA ti ń bẹ, n kò ní pa á.”
I. Sam 19:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Jonatani sọ̀rọ̀ rere nípa Dafidi fún Saulu baba rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Má ṣe jẹ́ kí ọba kí ó ṣe ohun tí kò dára fún Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀; nítorí tí kò ṣẹ̀ ọ́, ohun tí ó sì ṣe pé ọ púpọ̀. Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu nígbà tí ó pa Filistini. OLúWA ṣẹ́ ogun ńlá fún gbogbo Israẹli, ìwọ rí i inú rẹ dùn. Ǹjẹ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe dẹ́ṣẹ̀ sí Dafidi aláìṣẹ̀, tí ìwọ yóò fi pa á láìnídìí?” Saulu fetísí Jonatani, ó sì búra báyìí, “Níwọ́n ìgbà tí OLúWA bá ti ń bẹ láààyè, a kì yóò pa Dafidi.”