I. Sam 15:17-26

I. Sam 15:17-26 Bibeli Mimọ (YBCV)

Samueli si wipe, Iwọ kò ha kere loju ara rẹ nigbati a fi ọ ṣe olori ẹya Israeli, ti Oluwa fi àmi ororo sọ ọ di ọba Israeli? Oluwa si rán ọ ni iṣẹ, o si wipe, Lọ, ki o si pa awọn ẹlẹṣẹ ara Amaleki run, ki o si ba wọn jà titi o fi run wọn. Eha si ti ṣe ti iwọ kò fi gbọ́ ohùn Oluwa ṣugbọn iwọ si sare si ikogun, ti iwọ si ṣe buburu li oju Oluwa. Saulu si wi fun Samueli pe, Nitotọ, emi gbà ohùn Oluwa gbọ́, emi si ti lọ li ọ̀na ti Oluwa ran mi, emi si ti mu Agagi ọba Amaleki wá, emi si ti pa ara Amaleki run. Ṣugbọn awọn enia na ti mu ninu ikogun, agutan ati malu, pàtaki nkan wọnni ti a ba pa run, lati fi rubọ si Oluwa Ọlọrun rẹ ni Gilgali. Samueli si wipe, Oluwa ha ni inu-didun si ọrẹ sisun ati ẹbọ bi pe ki a gbà ohùn Oluwa gbọ́? kiye si i, igbọran sàn jù ẹbọ lọ, ifetisilẹ̀ si sàn jù ọra àgbo lọ. Nitoripe iṣọtẹ dabi ẹ̀ṣẹ afọṣẹ, ati agidi gẹgẹ bi ìwa buburu ati ibọriṣa. Nitoripe iwọ kọ̀ ọ̀rọ Oluwa, on si kọ̀ ọ li ọba. Saulu si wi fun Samueli pe, Emi ti ṣẹ̀: nitoriti emi ti re ofin Oluwa kọja, ati ọ̀rọ rẹ̀: nitori emi bẹ̀ru awọn enia, emi si gbà ohùn wọn gbọ́. Ṣugbọn nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, dari ẹ̀ṣẹ mi jì mi, ki o sì yipada pẹlu mi, ki emi ki o le tẹriba niwaju Oluwa. Samueli si wi fun Saulu pe, emi kì yio tun yipada pẹlu rẹ mọ nitoriti iwọ ti kọ̀ ọ̀rọ Oluwa, Oluwa si ti kọ̀ iwọ lati ma jẹ ọba lori Israeli.

I. Sam 15:17-26 Yoruba Bible (YCE)

Samuẹli ní, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò jámọ́ nǹkankan lójú ara rẹ, sibẹsibẹ ìwọ ni olórí gbogbo ẹ̀yà Israẹli. Ìwọ ni OLUWA fi òróró yàn ní ọba wọn. Ó sì rán ọ jáde pẹlu àṣẹ pé kí o pa gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ará Amaleki run. Ó ní kí o gbógun tì wọ́n títí o óo fi pa wọ́n run patapata. Kí ló dé tí o kò fi pa àṣẹ OLUWA mọ? Kí ló dé tí o fi kó ìkógun, tí o sì ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA?” Saulu dá a lóhùn pé, “Mo ti pa òfin OLUWA mọ́, mo jáde lọ bí o ti wí fún mi pé kí n jáde lọ, mo mú Agagi ọba pada bọ̀, mo sì pa gbogbo àwọn ará Amaleki run. Ṣugbọn àwọn eniyan mi ni wọ́n kó ìkógun aguntan ati àwọn mààlúù tí ó dára jùlọ lára àwọn ohun tí a ti yà sọ́tọ̀ fún ìparun láti fi wọ́n rúbọ sí OLUWA Ọlọrun rẹ ní Giligali.” Samuẹli bá bi í pé, “Èwo ló dùn mọ́ OLUWA jù, ìgbọràn ni, tabi ọrẹ ati ẹbọ sísun?” Ó ní, “Gbọ́! Ìgbọràn dára ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì dára ju ọ̀rá àgbò lọ. Ẹni tí ń ṣe oríkunkun sí OLUWA ati ẹni tí ó ṣẹ́ṣó, bákan náà ni wọ́n rí; ẹ̀ṣẹ̀ ìgbéraga ati ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà kò sì yàtọ̀. Nítorí pé, o kọ òfin OLUWA, OLUWA ti kọ ìwọ náà ní ọba.” Saulu wí fún Samuẹli pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo ti dẹ́ṣẹ̀. Mo ti ṣe àìgbọràn sí òfin OLUWA ati sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí pé mo bẹ̀rù àwọn eniyan mi, mo sì ṣe ohun tí wọ́n fẹ́. Nítorí náà, mo bẹ̀ ọ́, dáríjì mí, kí o sì bá mi pada, kí n lọ sin OLUWA níbẹ̀.” Samuẹli dá a lóhùn pé, “N kò ní bá ọ pada lọ. O ti kọ òfin OLUWA sílẹ̀, OLUWA sì ti kọ ìwọ náà ní ọba Israẹli.”

I. Sam 15:17-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Samuẹli sì wí pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ fi ìgbà kan kéré lójú ara rẹ, ǹjẹ́ ìwọ kò ha di olórí ẹ̀yà Israẹli? OLúWA fi ààmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli. OLúWA sì rán ọ níṣẹ́ wí pé, ‘Lọ, kí o sì pa àwọn ènìyàn búburú ará Amaleki run pátápátá; gbóguntì wọ́n títí ìwọ yóò fi run wọ́n.’ Èéṣe tí ìwọ kò fi gbọ́ ti OLúWA? Èéṣe tí ìwọ fi sáré sí ìkógun tí o sì ṣe búburú níwájú OLúWA?” Saulu sì wí fún Samuẹli pé, “Ṣùgbọ́n èmi ti ṣe ìgbọ́ràn sí OLúWA, èmi sì ti lọ ní ọ̀nà tí OLúWA rán mi. Mo sì ti pa àwọn ará Amaleki run pátápátá, mo sì ti mú Agagi ọba wọn padà wá. Àwọn ọmọ-ogun ti mú àgùntàn àti màlúù lára ìkógun èyí tí ó dára láti fi fún OLúWA láti fi rú ẹbọ sí OLúWA Ọlọ́run rẹ ní Gilgali.” Ṣùgbọ́n Samuẹli dáhùn pé, “OLúWA ha ní inú dídùn sí ẹbọ sísun àti ẹbọ ju kí a gba ohùn OLúWA gbọ́? Ìgbọ́ràn sàn ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ. Nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀ dàbí ẹ̀ṣẹ̀ àfọ̀ṣẹ, àti ìgbéraga bí ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà. Nítorí tí ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ OLúWA, Òun sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba.” Nígbà náà ni Saulu wí fún Samuẹli pé, “Èmi ti ṣẹ̀. Mo ti rú òfin OLúWA àti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èmi sì bẹ̀rù àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni èmi sì gba ohùn wọn gbọ́. Mo bẹ̀ ọ́ nísinsin yìí, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì, kí ó sì yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè sin OLúWA.” Ṣùgbọ́n Samuẹli wí fún un pé, “Èmi kò ní bá ọ padà. Ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ OLúWA sílẹ̀, OLúWA sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba lórí Israẹli!”