1 Samuẹli 15:17-26

1 Samuẹli 15:17-26 YCB

Samuẹli sì wí pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ fi ìgbà kan kéré lójú ara rẹ, ǹjẹ́ ìwọ kò ha di olórí ẹ̀yà Israẹli? OLúWA fi ààmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli. OLúWA sì rán ọ níṣẹ́ wí pé, ‘Lọ, kí o sì pa àwọn ènìyàn búburú ará Amaleki run pátápátá; gbóguntì wọ́n títí ìwọ yóò fi run wọ́n.’ Èéṣe tí ìwọ kò fi gbọ́ ti OLúWA? Èéṣe tí ìwọ fi sáré sí ìkógun tí o sì ṣe búburú níwájú OLúWA?” Saulu sì wí fún Samuẹli pé, “Ṣùgbọ́n èmi ti ṣe ìgbọ́ràn sí OLúWA, èmi sì ti lọ ní ọ̀nà tí OLúWA rán mi. Mo sì ti pa àwọn ará Amaleki run pátápátá, mo sì ti mú Agagi ọba wọn padà wá. Àwọn ọmọ-ogun ti mú àgùntàn àti màlúù lára ìkógun èyí tí ó dára láti fi fún OLúWA láti fi rú ẹbọ sí OLúWA Ọlọ́run rẹ ní Gilgali.” Ṣùgbọ́n Samuẹli dáhùn pé, “OLúWA ha ní inú dídùn sí ẹbọ sísun àti ẹbọ ju kí a gba ohùn OLúWA gbọ́? Ìgbọ́ràn sàn ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ. Nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀ dàbí ẹ̀ṣẹ̀ àfọ̀ṣẹ, àti ìgbéraga bí ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà. Nítorí tí ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ OLúWA, Òun sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba.” Nígbà náà ni Saulu wí fún Samuẹli pé, “Èmi ti ṣẹ̀. Mo ti rú òfin OLúWA àti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èmi sì bẹ̀rù àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni èmi sì gba ohùn wọn gbọ́. Mo bẹ̀ ọ́ nísinsin yìí, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì, kí ó sì yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè sin OLúWA.” Ṣùgbọ́n Samuẹli wí fún un pé, “Èmi kò ní bá ọ padà. Ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ OLúWA sílẹ̀, OLúWA sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba lórí Israẹli!”