I. Sam 13:7-14
I. Sam 13:7-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Omiran ninu awọn Heberu goke odo Jordani si ilẹ Gadi ati Gileadi. Bi o ṣe ti Saulu, on wà ni Gilgali sibẹ, gbogbo enia na si nwariri lẹhin rẹ̀. O si duro ni ijọ meje, de akoko ti Samueli dá fun u; ṣugbọn Samueli kò wá si Gilgali, awọn enia si tuka kuro li ọdọ rẹ̀. Saulu si wipe, Mu ẹbọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ na fun mi wá, o si ru ẹbọ sisun na. O si ṣe, bi o ti ṣe ẹbọ ọrẹ ati ẹbọ sisun wọnni pari, si kiye si i, Samueli de; Saulu si jade lati lọ pade rẹ̀, ki o le ki i. Samueli si bi i pe, Kini iwọ ṣe yi? Saulu si dahùn pe, Nitoriti emi ri pe awọn enia na ntuka kuro lọdọ mi, iwọ kò si wá li akoko ọjọ ti o dá, awọn Filistini si ko ara wọn jọ ni Mikmaṣi. Nitorina li emi ṣe wipe, Nisisiyi li awọn Filistini yio sọkalẹ tọ mi wá si Gilgali, bẹ̃li emi ko iti tù Oluwa loju; emi si tì ara mi si i, mo si ru ẹbọ sisun na. Samueli si wi fun Saulu pe, iwọ kò hu iwà ọlọgbọ́n: iwọ ko pa ofin Oluwa Ọlọrun rẹ mọ, ti on ti pa li aṣẹ fun ọ: nitori nisisiyi li Oluwa iba fi idi ijọba rẹ kalẹ̀ lori Israeli lailai. Ṣugbọn nisisiyi ijọba rẹ kì yio duro pẹ: Oluwa ti wá fun ara rẹ̀ ọkunrin ti o wù u li ọkàn rẹ̀, Oluwa paṣẹ fun u ki o ṣe olori fun awọn enia rẹ̀, nitoripe iwọ kò pa aṣẹ ti Oluwa fi fun ọ mọ.
I. Sam 13:7-14 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn mìíràn ninu wọn ré odò Jọdani kọjá sí agbègbè Gadi ati Gileadi. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà pẹlu Saulu sì wà ninu ìbẹ̀rù ńlá. Ọjọ́ meje ni ó fi dúró de Samuẹli, bí Samuẹli ti wí. Ṣugbọn Samuẹli kò wá sí Giligali. Àwọn eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí sá kúrò lẹ́yìn Saulu. Nítorí náà, Saulu ní kí wọ́n gbé ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia wá fún òun, ó sì rú ẹbọ. Bí ó ti parí rírú ẹbọ sísun náà tán ni Samuẹli dé. Saulu lọ pàdé rẹ̀, ó sì kí i káàbọ̀. Ṣugbọn Samuẹli wí fún un pé, “Kí lo dánwò yìí?” Saulu bá dá a lóhùn pé, “Àwọn eniyan náà ti bẹ̀rẹ̀ sí sá kúrò lẹ́yìn mi, o kò sì dé ní àkókò tí o dá. Àwọn ará Filistia sì ti kó ara wọn jọ ní Mikimaṣi. Mo wá rò ó wí pé, àwọn ará Filistia tí ń bọ̀ wá gbógun tì mí ní Giligali níhìn-ín, n kò sì tíì wá ojurere OLUWA. Ni mo bá rú ẹbọ sísun.” Samuẹli bá wí fún un pé, “Ìwà òmùgọ̀ patapata gbáà ni èyí. O kò pa òfin tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ mọ́. Bí ó bá jẹ́ pé o gbọ́ tirẹ̀ ni, nisinsinyii ni OLUWA ìbá fìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Israẹli títí lae. Ṣugbọn nisinsinyii, ìjọba rẹ kò ní jẹ́ títí lae, nítorí pé, o ti ṣe àìgbọràn sí OLUWA. Ó ti wá ẹni tí ó fẹ́, ó sì ti yàn án láti jẹ́ olórí fún àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé, o kò pa òfin OLUWA rẹ mọ́.”
I. Sam 13:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn Heberu mìíràn tilẹ̀ kọjá a Jordani sí ilẹ̀ Gadi àti Gileadi. Saulu wà ní Gilgali síbẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì ń wárìrì fún ìbẹ̀rù. Ó sì dúró di ọjọ́ méje, àkókò tí Samuẹli dá; ṣùgbọ́n Samuẹli kò wá sí Gilgali, àwọn ènìyàn Saulu sì bẹ̀rẹ̀ sí ní túká. Saulu sì wí pé, “Ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá fún mi.” Saulu sì rú ẹbọ sísun náà. Bí ó sì ti ń parí rírú ẹbọ sísun náà, Samuẹli sì dé, Saulu sì jáde láti lọ kí i. Samuẹli sì wí pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí.” Saulu sì dáhùn pé, “Nígbà tí mo rí pé àwọn ènìyàn náà ń túká, àti tí ìwọ kò sì wá ní àkókò ọjọ́ tí ìwọ dá, tí àwọn Filistini sì kó ara wọ́n jọ ní Mikmasi, mo rò pé, ‘Àwọn Filistini yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ mí wá ní Gilgali nísinsin yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ì tí ì wá ojúrere OLúWA.’ Báyìí ni mo mú ara mi ní ipá láti rú ẹbọ sísun náà.” Samuẹli sì wí fún un pé, “Ìwọ hu ìwà aṣiwèrè, ìwọ kò sì pa òfin tí OLúWA Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́; bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun ìbá fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ lórí Israẹli láéláé. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba rẹ kì yóò dúró pẹ́, OLúWA ti wá ọkùnrin tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì ti yàn án láti ṣe olórí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ìwọ kò pa òfin OLúWA mọ́.”