I. Sam 13

13
Àwọn Ọmọ Israẹli Gbógun ti Àwọn Ará Filistia
1SAULU jọba li ọdun kan; nigbati o si jọba ọdun meji lori Israeli,
2Saulu si yan ẹgbẹ̃dogun ọmọkunrin fun ara rẹ̀ ni Israeli; ẹgbã si wà lọdọ Saulu ni Mikmaṣi ati li oke-nla Beteli; ẹgbẹrun si wà lọdọ Jonatani ni Gibea ti Benjamini; o si rán awọn enia ti o kù olukuluku si agọ rẹ̀.
3Jonatani si pa ẹgbẹ ogun awọn Filistini ti o wà ninu ile olodi ni Geba, awọn Filistini si gbọ́. Saulu fun ipè yi gbogbo ilẹ na ka, wipe, Jẹ ki awọn Heberu gbọ́.
4Gbogbo Israeli si gbọ́ pe Saulu pa ẹgbẹ ogun awọn Filistini, Israeli si di irira fun awọn Filistini. Awọn enia na si pejọ lẹhin Saulu lati lọ si Gilgali.
5Awọn Filistini kó ara wọn jọ lati ba Israeli jà, ẹgbã-mẹ̃dogun kẹkẹ, ẹgbãta ọkunrin ẹlẹṣin, enia si pọ̀ bi yanrin leti okun; nwọn si goke, nwọn do ni Mikmaṣi ni iha ila õrun Bet-Afeni.
6Awọn ọkunrin Israeli si ri pe, nwọn wà ninu ipọnju (nitoripe awọn enia na wà ninu ìhamọ) nigbana ni awọn enia na fi ara pamọ ninu iho, ati ninu panti, ninu apata, ni ibi giga, ati ninu kanga gbigbẹ.
7Omiran ninu awọn Heberu goke odo Jordani si ilẹ Gadi ati Gileadi. Bi o ṣe ti Saulu, on wà ni Gilgali sibẹ, gbogbo enia na si nwariri lẹhin rẹ̀.
8O si duro ni ijọ meje, de akoko ti Samueli dá fun u; ṣugbọn Samueli kò wá si Gilgali, awọn enia si tuka kuro li ọdọ rẹ̀.
9Saulu si wipe, Mu ẹbọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ na fun mi wá, o si ru ẹbọ sisun na.
10O si ṣe, bi o ti ṣe ẹbọ ọrẹ ati ẹbọ sisun wọnni pari, si kiye si i, Samueli de; Saulu si jade lati lọ pade rẹ̀, ki o le ki i.
11Samueli si bi i pe, Kini iwọ ṣe yi? Saulu si dahùn pe, Nitoriti emi ri pe awọn enia na ntuka kuro lọdọ mi, iwọ kò si wá li akoko ọjọ ti o dá, awọn Filistini si ko ara wọn jọ ni Mikmaṣi.
12Nitorina li emi ṣe wipe, Nisisiyi li awọn Filistini yio sọkalẹ tọ mi wá si Gilgali, bẹ̃li emi ko iti tù Oluwa loju; emi si tì ara mi si i, mo si ru ẹbọ sisun na.
13Samueli si wi fun Saulu pe, iwọ kò hu iwà ọlọgbọ́n: iwọ ko pa ofin Oluwa Ọlọrun rẹ mọ, ti on ti pa li aṣẹ fun ọ: nitori nisisiyi li Oluwa iba fi idi ijọba rẹ kalẹ̀ lori Israeli lailai.
14Ṣugbọn nisisiyi ijọba rẹ kì yio duro pẹ: Oluwa ti wá fun ara rẹ̀ ọkunrin ti o wù u li ọkàn rẹ̀, Oluwa paṣẹ fun u ki o ṣe olori fun awọn enia rẹ̀, nitoripe iwọ kò pa aṣẹ ti Oluwa fi fun ọ mọ.
15Samueli si dide, o si lọ lati Gilgali si Gibea ti Benjamini. Saulu si ka awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀, o jẹ iwọ̀n ẹgbẹta ọkunrin.
16Saulu, ati Jonatani ọmọ rẹ̀, ati awọn enia na ti o wà lọdọ wọn si joko ni Gibea ti Benjamini, ṣugbọn awọn Filistini do ni Mikmaṣi.
17Ẹgbẹ awọn onisùmọ̀mi mẹta jade ni ibudo awọn Filistini: ẹgbẹ kan gbà ọ̀na ti Ofra, si ilẹ Ṣuali.
18Ẹgbẹ kan si gba ọ̀na Bet-horoni: ati ẹgbẹ kan si gbà ọ̀na agbegbe nì ti o kọju si afonifoji Seboimu ti o wà ni iha iju.
19Kò si alagbẹdẹ ninu gbogbo ilẹ Israeli: nitori ti awọn Filistini wipe, Ki awọn Heberu ki o má ba rọ idà tabi ọ̀kọ.
20Ṣugbọn gbogbo Israeli a ma tọ̀ awọn Filistini lọ, olukuluku lati pọ́n doje rẹ̀, ati ọ̀kọ rẹ̀, ati ãke rẹ̀, ati ọ̀ṣọ rẹ̀.
21Ṣugbọn nwọn ni ayùn fun ọ̀ṣọ, ati fun ọ̀kọ, ati fun òya-irin ti ilẹ, ati fun ãke, ati lati pọn irin ọpa oluṣọ malu.
22Bẹ̃li o si ṣe li ọjọ ijà, ti a kò ri idà, tabi ọ̀kọ lọwọ ẹnikẹni ninu awọn enia ti o wà lọdọ Saulu ati Jonatani; lọdọ Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ li a ri.
23Awọn ọmọ-ogun Filistini jade lọ si ikọja Mikmaṣi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Sam 13: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀