I. Sam 13:13-14
I. Sam 13:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Samueli si wi fun Saulu pe, iwọ kò hu iwà ọlọgbọ́n: iwọ ko pa ofin Oluwa Ọlọrun rẹ mọ, ti on ti pa li aṣẹ fun ọ: nitori nisisiyi li Oluwa iba fi idi ijọba rẹ kalẹ̀ lori Israeli lailai. Ṣugbọn nisisiyi ijọba rẹ kì yio duro pẹ: Oluwa ti wá fun ara rẹ̀ ọkunrin ti o wù u li ọkàn rẹ̀, Oluwa paṣẹ fun u ki o ṣe olori fun awọn enia rẹ̀, nitoripe iwọ kò pa aṣẹ ti Oluwa fi fun ọ mọ.
I. Sam 13:13-14 Yoruba Bible (YCE)
Samuẹli bá wí fún un pé, “Ìwà òmùgọ̀ patapata gbáà ni èyí. O kò pa òfin tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ mọ́. Bí ó bá jẹ́ pé o gbọ́ tirẹ̀ ni, nisinsinyii ni OLUWA ìbá fìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Israẹli títí lae. Ṣugbọn nisinsinyii, ìjọba rẹ kò ní jẹ́ títí lae, nítorí pé, o ti ṣe àìgbọràn sí OLUWA. Ó ti wá ẹni tí ó fẹ́, ó sì ti yàn án láti jẹ́ olórí fún àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé, o kò pa òfin OLUWA rẹ mọ́.”
I. Sam 13:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Samuẹli sì wí fún un pé, “Ìwọ hu ìwà aṣiwèrè, ìwọ kò sì pa òfin tí OLúWA Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́; bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun ìbá fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ lórí Israẹli láéláé. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba rẹ kì yóò dúró pẹ́, OLúWA ti wá ọkùnrin tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì ti yàn án láti ṣe olórí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ìwọ kò pa òfin OLúWA mọ́.”