I. Sam 10:20-24
I. Sam 10:20-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Samueli si mu ki gbogbo ẹya Israeli sunmọ tosi, a si mu ẹya Benjamini. On si mu ki ẹya Benjamini sunmọ tosi nipa idile wọn, a mu idile Matri, a si mu Saulu ọmọ Kiṣi: nigbati nwọn si wá a kiri, nwọn kò si ri i. Nitorina nwọn si tun bere lọdọ Oluwa sibẹ bi ọkunrin na yio wá ibẹ̀. Oluwa si dahùn wipe, Wõ, o pa ara rẹ̀ mọ lãrin ohun-elò. Nwọn sare, nwọn si mu u lati ibẹ̀ wá: nigbati o si duro lãrin awọn enia na, o si ga jù gbogbo wọn lọ lati ejika rẹ̀ soke. Samueli si wi fun gbogbo awọn enia na pe, Ẹnyin kò ri ẹniti Oluwa yàn fun ara rẹ̀, pe, ko si ẹniti o dabi rẹ̀ ninu gbogbo enia na? Gbogbo enia si ho ye, nwọn si wipe, Ki Ọba ki o pẹ!
I. Sam 10:20-24 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà náà ni, Samuẹli mú kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tò kọjá níwájú OLUWA, gègé sì mú ẹ̀yà Bẹnjamini. Lẹ́yìn náà Samuẹli mú kí àwọn ìdílé ìdílé tí ó wà ninu ẹ̀yà Bẹnjamini tò kọjá, gègé sì mú ìdílé Matiri. Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọkunrin inú ìdílé Matiri bẹ̀rẹ̀ sí tò kọjá, gègé sì mú Saulu ọmọ Kiṣi. Ṣugbọn wọn kò rí i nígbà tí wọ́n wá a. Wọ́n bi OLUWA pé, “Àbí ọkunrin náà kò wá ni?” OLUWA dá wọn lóhùn pé, “Ó ti farapamọ́ sí ààrin àwọn ẹrù.” Wọ́n sáré lọ mú un jáde láti ibẹ̀. Nígbà tí ó dúró láàrin wọn, kò sí ẹni tí ó ga ju èjìká rẹ̀ lọ ninu wọn. Samuẹli bá wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹni tí OLUWA yàn nìyí. Kò sí ẹnikẹ́ni láàrin wa tí ó dàbí rẹ̀.” Gbogbo àwọn eniyan náà kígbe sókè pé, “Kí ọba kí ó pẹ́.”
I. Sam 10:20-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí Samuẹli mú gbogbo ẹ̀yà Israẹli súnmọ́ tòsí, ó yan ẹ̀yà Benjamini. Ó kó ẹ̀yà Benjamini síwájú ní ìdílé ìdílé, a sì yan ìdílé Matiri. Ní ìparí a sì yan Saulu ọmọ Kiṣi. Ṣùgbọ́n ní ìgbà tí wọ́n wá a, a kò rí i, Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ìwádìí lọ́wọ́ OLúWA pé, “Ṣé ọkùnrin náà ti wá sí bí ni?” OLúWA sì sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ ni ó ti fi ara rẹ̀ pamọ́ láàrín àwọn ẹrù.” Wọ́n sáré, wọ́n sì mú un jáde wá. Bí ó ti dúró láàrín àwọn ènìyàn, ó sì ga ju gbogbo àwọn tí ó kù lọ láti èjìká rẹ̀ sókè. Samuẹli sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé, “Ṣé ẹ ti ri ọkùnrin tí OLúWA ti yàn? Kò sí ẹnìkan bí i rẹ̀ láàrín gbogbo àwọn ènìyàn.” Nígbà náà àwọn ènìyàn kígbe pé, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn!”