Nígbà náà ni, Samuẹli mú kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tò kọjá níwájú OLUWA, gègé sì mú ẹ̀yà Bẹnjamini. Lẹ́yìn náà Samuẹli mú kí àwọn ìdílé ìdílé tí ó wà ninu ẹ̀yà Bẹnjamini tò kọjá, gègé sì mú ìdílé Matiri. Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọkunrin inú ìdílé Matiri bẹ̀rẹ̀ sí tò kọjá, gègé sì mú Saulu ọmọ Kiṣi. Ṣugbọn wọn kò rí i nígbà tí wọ́n wá a. Wọ́n bi OLUWA pé, “Àbí ọkunrin náà kò wá ni?” OLUWA dá wọn lóhùn pé, “Ó ti farapamọ́ sí ààrin àwọn ẹrù.” Wọ́n sáré lọ mú un jáde láti ibẹ̀. Nígbà tí ó dúró láàrin wọn, kò sí ẹni tí ó ga ju èjìká rẹ̀ lọ ninu wọn. Samuẹli bá wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹni tí OLUWA yàn nìyí. Kò sí ẹnikẹ́ni láàrin wa tí ó dàbí rẹ̀.” Gbogbo àwọn eniyan náà kígbe sókè pé, “Kí ọba kí ó pẹ́.”
Kà SAMUẸLI KINNI 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: SAMUẸLI KINNI 10:20-24
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò