I. Pet 3:15-22
I. Pet 3:15-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ẹ bọ̀wọ fun Kristi bi Oluwa lọkan nyin: ki ẹ si mura tan nigbagbogbo lati dá olukuluku lohùn ti mbere ireti ti o mbẹ ninu nyin, ṣugbọn pẹlu ọkàn tutù ati ìbẹru. Ki ẹ mã ni ẹri-ọkàn rere, bi nwọn ti nsọ̀rọ nyin ni ibi, ki oju ki o le ti awọn ti nkẹgan iwa rere nyin ninu Kristi. Nitori o san, bi o bá jẹ ifẹ Ọlọrun, ki ẹ jìya fun rere iṣe jù fun buburu iṣe lọ. Nitoriti Kristi pẹlu jìya lẹ̃kan nitori ẹ̀ṣẹ wa, olõtọ fun awọn alaiṣõtọ, ki o le mu wa de ọdọ Ọlọrun, ẹniti a pa ninu ara, ṣugbọn ti a sọ di ãye ninu ẹmí: Ninu eyiti o lọ pẹlu, ti o si wãsu fun awọn ẹmí ninu tubu: Awọn ti o ṣe alaigbọran nigbakan, nigbati sũru Ọlọrun duro pẹ ni sã kan ni ọjọ Noa, nigbati nwọn fi nkàn ọkọ̀ ninu eyiti à gba ọkàn diẹ là nipa omi, eyini ni ẹni mẹjọ; Apẹrẹ eyiti ngbà nyin là nisisiyi pẹlu, ani baptismu, kì iṣe ìwẹ ẽri ti ara nù, bikoṣe idahùn ọkàn rere sipa Ọlọrun, nipa ajinde Jesu Kristi: Ẹniti o ti lọ si ọrun, ti o si mbẹ li ọwọ́ ọtún Ọlọrun; awọn angẹli, ati awọn ọlọlá, ati awọn alagbara si ntẹriba fun.
I. Pet 3:15-22 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn ẹ fi ààyè fún Kristi ninu ọkàn yín bí Oluwa. Ẹ múra nígbà gbogbo láti dáhùn bí ẹnikẹ́ni bá bi yín ní ìbéèrè nípa ìrètí tí ẹ ní. Ṣugbọn kí ẹ dáhùn pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́. Ẹ ní ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́, tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá ń sọ ọ̀rọ̀ yín ní àìdára, ojú yóo ti àwọn tí wọn ń sọ̀rọ̀ àbùkù nípa yín, nígbà tí wọn bá rí ìgbé-ayé yín gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ. Nítorí ó sàn fun yín tí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun pé kí ẹ jìyà, nítorí pé ẹ̀ ń ṣe rere, jù pé ẹ̀ ń ṣe ibi lọ. Nítorí Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ wa; olódodo ni, ó kú fún alaiṣododo, kí ó lè mú wa wá sọ́dọ̀ Ọlọrun. A pa á ní ti ara, ṣugbọn ó wà láàyè ní ti ẹ̀mí. Nípa ẹ̀mí, ó lọ waasu fún àwọn ẹ̀mí tí ó wà lẹ́wọ̀n. Àwọn wọnyi ni ẹ̀mí àwọn ẹni tí kò gbàgbọ́ nígbà kan rí, nígbà ayé Noa, nígbà tí Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ mú sùúrù tí Noa fi kan ọkọ̀ tán. Ninu ọkọ̀ yìí ni àwọn eniyan díẹ̀ wà, àwọn mẹjọ, tí a fi gbà wọ́n là ninu ìkún omi. Èyí jẹ́ àkàwé ìrìbọmi tí ó ń gba eniyan là nisinsinyii. Kì í ṣe láti wẹ ìdọ̀tí kúrò lára, bíkòṣe ọ̀nà tí ẹ̀bẹ̀ eniyan fi lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọrun nípa ẹ̀rí ọkàn rere, nípa ajinde Jesu Kristi, ẹni tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, tí ó ti kọjá lọ sọ́run, lẹ́yìn tí àwọn angẹli ati àwọn aláṣẹ ati àwọn alágbára ojú ọ̀run ti wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.
I. Pet 3:15-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kristi bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń béèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù. Kí ẹ máa ni ẹ̀rí ọkàn rere bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín ní ibi, kí ojú lè ti àwọn tí ń kẹ́gàn ìwà rere yín nínú Kristi. Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣíṣe búburú lọ. Nítorí tí Kristi pẹ̀lú jìyà lẹ́ẹ̀kan nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòótọ́ fún àwọn aláìṣòótọ́, kí a lè mú wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí: Nínú èyí tí ó lọ pẹ̀lú tí ó sì wàásù fún àwọn ẹ̀mí nínú túbú: àwọn tí ó ṣe aláìgbọ́ràn nígbà kan, nígbà tí sùúrù Ọlọ́run dúró pẹ́ ní sá à kan ní ọjọ́ Noa, nígbà tí wọ́n fi kan ọkọ̀ nínú èyí tí a gba ọkàn díẹ̀ là nípa omi, èyí ni ẹni mẹ́jọ. Àpẹẹrẹ èyí ti ń gbà yín là nísinsin yìí pẹ̀lú, àní ìtẹ̀bọmi, kì í ṣe wíwẹ́ èérí ti ara nù, bí kò ṣe ìdáhùn ẹ̀rí ọkàn rere si Ọlọ́run, nípa àjíǹde Jesu Kristi. Ẹni tí ó lọ sí ọ̀run, tí ó sì ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run: pẹ̀lú àwọn angẹli, àwọn aláṣẹ, àti àwọn alágbára sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.