I. Pet 3:1-4
I. Pet 3:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
BẸ̃ gẹgẹ, ẹnyin aya, ẹ mã tẹriba fun awọn ọkọ nyin; pe, bi ẹnikẹni bá tilẹ nṣe aigbọran si ọ̀rọ na, ki a lè jere wọn li aisọrọ nipa ìwa awọn aya wọn, Nigbati nwọn ba nwò ìwa rere ti on ti ẹ̀ru nyin: Ọṣọ́ ẹniti ki o má jẹ ọṣọ́ ode, ti irun didì, ati ti wura lilo, tabi ti aṣọ wiwọ̀; Ṣugbọn ki o jẹ ti ẹniti o farasin li ọkàn, ninu ọ̀ṣọ́ aidibajẹ ti ẹmí irẹlẹ ati ẹmí tutù, eyiti iṣe iyebiye niwaju Ọlọrun.
I. Pet 3:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Bákan náà ni kí ẹ̀yin aya máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọkọ yín. Ìdí rẹ̀ ni pé bí a bá rí ninu àwọn ọkọ tí kò jẹ́ onigbagbọ, wọ́n lè yipada nípa ìwà ẹ̀yin aya wọn láìjẹ́ pé ẹ bá wọn sọ gbolohun kan nípa ẹ̀sìn igbagbọ, nígbà tí wọ́n bá ṣe akiyesi ìwà mímọ́ ati ìwà ọmọlúwàbí yín. Ẹwà yín kò gbọdọ̀ jẹ́ ti òde ara nìkan bíi ti irun-dídì, ati nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà tí ẹ kó sára ati aṣọ-ìgbà. Ṣugbọn kí ẹwà yín jẹ́ ti ọkàn tí kò hàn sóde, ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́. Èyí ni ẹwà tí kò lè ṣá, èyí tí ó ṣe iyebíye lójú Ọlọrun.
I. Pet 3:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín; pé, bí ẹnikẹ́ni ba tilẹ̀ ń ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láì sọ̀rọ̀ nípa ìwà àwọn aya wọn. Nígbà tí wọ́n bá ń wo ìwà rere pẹ̀lú ẹ̀rù yín: Kí ọ̀ṣọ́ yín má ṣe jẹ́ ọ̀ṣọ́ òde, tí irun dídì, àti wúrà lílò, tàbí ti aṣọ wíwọ̀; Ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó fi ara sin ní ọkàn, nínú ọ̀ṣọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run.