I. A. Ọba 8:22-53

I. A. Ọba 8:22-53 Bibeli Mimọ (YBCV)

Solomoni si duro niwaju pẹpẹ Oluwa, loju gbogbo ijọ enia Israeli, o si nà ọwọ́ rẹ̀ mejeji soke ọrun: O si wipe, Oluwa Ọlọrun Israeli, kò si Ọlọrun ti o dabi rẹ loke ọrun, tabi ni isalẹ ilẹ, ti ipa majẹmu ati ãnu mọ pẹlu awọn iranṣẹ rẹ ti nfi gbogbo ọkàn wọn rin niwaju rẹ: Ẹniti o ti ba iranṣẹ rẹ Dafidi, baba mi pa ohun ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ: iwọ fi ẹnu rẹ sọ pẹlu, o si ti fi ọwọ́ rẹ mu u ṣẹ, gẹgẹ bi o ti ri loni. Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun Israeli, ba iranṣẹ rẹ Dafidi, baba mi pa ohun ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ́ wipe, A kì yio fẹ ọkunrin kan kù li oju mi lati joko lori itẹ Israeli; kiki bi awọn ọmọ rẹ ba le kiyesi ọ̀na wọn, ki nwọn ki o mã rìn niwaju mi gẹgẹ bi iwọ ti rìn niwaju mi. Njẹ nisisiyi, Ọlọrun Israeli, jẹ ki a mu ọ̀rọ rẹ ṣẹ, emi bẹ̀ ọ, ti iwọ ti sọ fun iranṣẹ rẹ, Dafidi baba mi. Ṣugbọn nitõtọ Ọlọrun yio ha mã gbe aiye bi? wò o, ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà ọ; ambọ̀sì ile yi ti mo kọ́? Sibẹ̀ iwọ ṣe afiyèsi adura iranṣẹ rẹ, ati si ẹbẹ rẹ̀, Oluwa Ọlọrun mi, lati tẹtisilẹ si ẹkun ati si adura, ti iranṣẹ rẹ ngbà niwaju rẹ loni: Ki oju rẹ lè ṣi si ile yi li ọsan ati li oru, ani si ibi ti iwọ ti wipe: Orukọ mi yio wà nibẹ: ki iwọ ki o lè tẹtisilẹ si adura ti iranṣẹ rẹ yio gbà si ibi yi. Ki o si tẹtisilẹ si ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ ati ti Israeli, enia rẹ, ti nwọn o gbadura siha ibi yi: ki o si gbọ́ li ọrun, ibugbe rẹ! gbọ́, ki o si darijì. Bi ẹnikan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀, ti a si fi ibura le e lati mu u bura, bi ibura na ba si de iwaju pẹpẹ rẹ ni ile yi: Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si ṣe, ki o si dajọ awọn iranṣẹ rẹ, ni didẹbi fun enia buburu, lati mu ọ̀na rẹ̀ wá si ori rẹ̀; ati ni didare fun olõtọ, lati fun u gẹgẹ bi ododo rẹ̀. Nigbati a ba lù Israeli, enia rẹ bòlẹ niwaju awọn ọ̀ta, nitoriti nwọn dẹṣẹ si ọ, ti nwọn ba si yipada si ọ, ti nwọn si jẹwọ orukọ rẹ, ti nwọn si gbadura, ti nwọn si bẹ̀bẹ lọdọ rẹ ni ile yi: Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si dari ẹ̀ṣẹ Israeli, enia rẹ jì, ki o si mu wọn pada wá si ilẹ ti iwọ ti fi fun awọn baba wọn. Nigbati a ba sé ọrun mọ, ti kò si òjo, nitoriti nwọn ti dẹṣẹ si ọ: bi nwọn ba gbadura si iha ibi yi, ti nwọn si jẹwọ orukọ rẹ, bi nwọn ba si yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wọn, nigbati iwọ ba pọ́n wọn li oju. Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si dari ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ jì, ati ti Israeli, enia rẹ, nigbati o kọ́ wọn li ọ̀na rere ninu eyiti nwọn iba mã rin, ki o si rọ̀ òjo si ilẹ rẹ, ti iwọ ti fi fun enia rẹ ni ilẹ-ini. Bi iyàn ba mu ni ilẹ, bi ajakalẹ-arùn ni, tabi ìrẹdanu, tabi bibu, tabi bi ẽṣu tabi bi kòkorò ti njẹrun ba wà; bi ọtá wọn ba dó tì wọn ni ilẹ ilu wọn; ajakalẹ-arùn gbogbo, arùn-ki-arun gbogbo. Adura ki adura, ati ẹ̀bẹ ki ẹ̀bẹ, ti a ba ti ọdọ ẹnikan tabi lati ọdọ gbogbo Israeli, enia rẹ gbà, ti olukuluku yio mọ̀ ibanujẹ ọkàn ara rẹ̀, bi o ba si tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ mejeji si iha ile yi! Nigbana ni ki iwọ ki o gbọ́ li ọrun, ibugbe rẹ, ki o si darijì, ki o si ṣe ki o si fun olukulùku enia gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀, ọkàn ẹniti iwọ mọ̀; nitoriti iwọ, iwọ nikanṣoṣo li o mọ̀ ọkàn gbogbo awọn ọmọ enia; Ki nwọn ki o lè mã bẹ̀ru rẹ ni gbogbo ọjọ ti nwọn wà ni ilẹ ti iwọ fi fun awọn baba wa. Pẹlupẹlu, niti alejò, ti kì iṣe ti inu Israeli enia rẹ, ṣugbọn ti o ti ilẹ okerè jade wá nitori orukọ rẹ. Nitoriti nwọn o gbọ́ orukọ nla rẹ, ati ọwọ́ agbára rẹ, ati ninà apa rẹ; nigbati on o wá, ti yio si gbadura si iha ile yi; Iwọ gbọ́ li ọrun, ibùgbe rẹ, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti alejò na yio ke pè ọ si: ki gbogbo aiye ki o lè mọ̀ orukọ rẹ, ki nwọn ki o lè mã bẹ̀ru rẹ, gẹgẹ bi Israeli, enia rẹ, ki nwọn ki o si lè mọ̀ pe: orukọ rẹ li a fi npè ile yi ti mo kọ́. Bi enia rẹ ba jade lọ si ogun si ọtá wọn, li ọ̀na ti iwọ o rán wọn, bi nwọn ba si gbadura si Oluwa siha ilu ti iwọ ti yàn, ati siha ile ti mo kọ́ fun orukọ rẹ. Nigbana ni ki o gbọ́ adura wọn, ati ẹ̀bẹ wọn li ọrun, ki o si mu ọràn wọn duro. Bi nwọn ba ṣẹ̀ si ọ, nitoriti kò si enia kan ti kì iṣẹ̀, bi iwọ ba si binu si wọn, ti o si fi wọn le ọwọ́ ọta, tobẹ̃ ti a si kó wọn lọ ni igbèkun si ilẹ ọta, jijìna tabi nitosi; Bi nwọn ba rò inu ara wọn wò ni ilẹ nibiti a gbe kó wọn ni igbèkun lọ, ti nwọn ba si ronupiwàda, ti nwọn ba si bẹ̀ ọ ni ilẹ awọn ti o kó wọn ni igbèkun lọ, wipe, Awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣe ohun ti kò tọ, awa ti ṣe buburu; Bi nwọn ba si fi gbogbo àiya ati gbogbo ọkàn wọn yipada si ọ ni ilẹ awọn ọta wọn, ti o kó wọn ni igbèkun lọ, ti nwọn si gbadura si ọ siha ilẹ wọn, ti iwọ ti fi fun awọn baba wọn, ilu ti iwọ ti yàn, ati ile ti emi kọ́ fun orukọ rẹ: Nigbana ni ki iwọ ki o gbọ́ adura wọn ati ẹ̀bẹ wọn li ọrun ibugbe rẹ, ki o si mu ọ̀ran wọn duro: Ki o si darijì awọn enia rẹ ti o ti dẹṣẹ si ọ, ati gbogbo irekọja wọn ninu eyiti nwọn ṣẹ̀ si ọ, ki o si fun wọn ni ãnu niwaju awọn ti o kó wọn ni igbèkun lọ, ki nwọn ki o le ṣãnu fun wọn. Nitori enia rẹ ati ini rẹ ni nwọn, ti iwọ mu ti Egipti jade wá, lati inu ileru irin: Ki oju rẹ ki o le ṣi si ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ, ati si ẹ̀bẹ Israeli enia rẹ, lati tẹtisilẹ si wọn ninu ohun gbogbo ti nwọn o ke pè ọ si. Nitoriti iwọ ti yà wọn kuro ninu gbogbo orilẹ-ède aiye, lati mã jẹ ini rẹ, bi iwọ ti sọ lati ọwọ Mose iranṣẹ rẹ, nigbati iwọ mu awọn baba wa ti Egipti jade wá, Oluwa Ọlọrun.

I. A. Ọba 8:22-53 Yoruba Bible (YCE)

Solomoni dúró níwájú pẹpẹ níwájú àwùjọ àwọn ọmọ Israẹli, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ mejeeji sókè. Ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura, ó ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kò sí Ọlọrun kan tí ó dàbí rẹ̀ lókè ọ̀run tabi ní ayé yìí, tíí máa pa majẹmu rẹ̀ mọ́, tíí sì máa fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí ń fi tọkàntọkàn gbọ́ràn sí i lẹ́nu. O ti mú ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi, ṣẹ. O ṣe ìlérí fún un nítòótọ́, o sì mú un ṣẹ lónìí. Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun Israẹli, mo bẹ̀ ọ́, mú àwọn ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi ṣẹ, pé, arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba ní Israẹli títí lae, bí wọ́n bá ṣọ́ra ní ọ̀nà wọn, tí wọ́n sì bá mi rìn bí ìwọ ti bá mi rìn. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli, mú ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi ṣẹ. “Ṣugbọn, ǹjẹ́ ìwọ Ọlọrun lè gbé inú ayé yìí? Nítorí pé bí gbogbo ọ̀run ti tóbi tó, kò gbà ọ́; kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ilé ìsìn tí mo kọ́ fún ọ? OLUWA Ọlọrun mi, fi etí sí adura èmi iranṣẹ rẹ, kí o sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ̀ níwájú rẹ lónìí. Kí ojú rẹ lè máa wà lára ilé ìsìn yìí tọ̀sán-tòru, níbi tí o sọ pé o óo yà sọ́tọ̀ fún orúkọ rẹ. Kí o lè gbọ́ adura tí iranṣẹ rẹ ń gbà sí ibí yìí. Máa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ iranṣẹ rẹ ati adura àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, nígbà tí wọ́n bá kọjú sí ilé yìí, tí wọ́n sì gbadura, máa gbọ́ tiwa láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì máa dáríjì wá. “Bí ẹnìkan bá ṣẹ ọmọnikeji rẹ̀ tí wọ́n sì ní kí ó wá búra, tí ó bá wá tí ó sì búra níwájú pẹpẹ rẹ ninu ilé ìsìn yìí, OLUWA, gbọ́ lọ́run lọ́hùn-ún, kí o sì ṣe ìdájọ́ àwọn iranṣẹ rẹ. Jẹ ẹni tí ó bá jẹ̀bi ní ìyà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; dá ẹni tí ó bá jàre láre, kí o sì san ẹ̀san òdodo rẹ̀ fún un. “Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹgun àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, nítorí pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí ọ́, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bá tún yipada sí ọ, tí wọ́n jẹ́wọ́ orúkọ rẹ ninu ilé yìí, tí wọ́n gbadura sí ọ, tí wọ́n bẹ̀bẹ̀, gbọ́ adura wọn lọ́run lọ́hùn-ún, dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, kí o sì mú wọn pada wá sórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wọn. “Nígbà tí o kò bá jẹ́ kí òjò rọ̀, nítorí pé wọ́n ṣẹ̀ ọ́, tí wọ́n bá ronupiwada tí wọ́n sì kọjú sí ilé ìsìn yìí, tí wọ́n gbadura sí ọ, nígbà tí o bá jẹ wọ́n níyà, gbọ́ adura wọn lọ́run lọ́hùn-ún, dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji Israẹli, iranṣẹ rẹ, àní, àwọn eniyan rẹ, kí o sì kọ́ wọn ní ọ̀nà rere tí wọn yóo máa tọ̀; lẹ́yìn náà, rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ tí o fi fún àwọn eniyan rẹ bí ohun ìní. “Nígbà tí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ yìí, tabi tí àjàkálẹ̀ àrùn wà, tabi ìrẹ̀dànù èso, tabi tí ọ̀wọ́ eṣú, tabi tí àwọn kòkòrò bá jẹ ohun ọ̀gbìn oko run, tabi tí àwọn ọ̀tá bá dó ti èyíkéyìí ninu ìlú àwọn eniyan rẹ, tabi tí àìsàn, tabi àrùnkárùn kan bá wà láàrin wọn, gbọ́ adura tí wọ́n bá gbà, ati ẹ̀bẹ̀ tí ẹnikẹ́ni tabi gbogbo Israẹli, àwọn eniyan rẹ, bá bẹ̀, nítorí ìpọ́njú ọkàn olukuluku wọn. Tí wọ́n bá gbé ọwọ́ wọn sókè, tí wọ́n sì kọjú sí ilé ìsìn yìí, gbọ́ adura wọn láti ibùgbé rẹ lọ́run, dáríjì wọ́n, dá wọn lóhùn, kí o sì san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀, (nítorí ìwọ nìkan ni o mọ èrò ọkàn ọmọ eniyan); kí wọ́n lè máa bẹ̀rù rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n óo gbé lórí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá wọn. “Bákan náà, nígbà tí àlejò kan, tí kì í ṣe ọmọ Israẹli, bá wá láti ilẹ̀ òkèèrè nítorí orúkọ rẹ, (nítorí wọn óo gbọ́ òkìkí rẹ, ati iṣẹ́ ìyanu tí o ti ṣe fún àwọn eniyan rẹ); tí ó bá wá sìn ọ́, tí ó bá kọjú sí ilé yìí, tí ó gbadura, gbọ́ adura rẹ̀ láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì ṣe gbogbo ohun tí ó bá bèèrè fún un, kí gbogbo aráyé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọ́n sì lè bẹ̀rù rẹ bí àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan rẹ tí ń ṣe, wọn yóo sì mọ̀ pé ilé ìsìn rẹ ni ilé tí mo kọ́ yìí. “Nígbà tí àwọn eniyan rẹ bá lọ dojú kọ àwọn ọ̀tá wọn lójú ogun, níbikíbi tí o bá rán wọn lọ, tí wọ́n bá kọjú sí ìlú tí o yàn yìí, ati ilé ìsìn tí mo kọ́ fún ọ, tí wọ́n sì gbadura, gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run wá, kí o sì tì wọ́n lẹ́yìn. “Nígbà tí àwọn eniyan rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, (nítorí pé kò sí ẹni tí kì í dẹ́ṣẹ̀), tí o bá bínú sí wọn, tí o sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá ṣẹgun wọn, tí wọ́n sì kó wọn lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ mìíràn, kì báà jẹ́ ibi tí ó jìnnà tabi tòsí, bí wọ́n bá ronupiwada ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ọ, tí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá, ati ìwà burúkú tí wọ́n hù, tí wọ́n bá ronupiwada tọkàntọkàn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn tí ó kó wọn lẹ́rú, tí wọ́n bá kọjú sí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá wọn, ati ìlú tí o yàn yìí, ati ilé ìsìn tí mo kọ́ ní orúkọ rẹ, tí wọ́n bá gbadura sí ọ; gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì tì wọ́n lẹ́yìn. Dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, ati gbogbo àìdára tí wọ́n ṣe, kí o sì jẹ́ kí àwọn tí wọ́n kó wọn lẹ́rú ṣàánú wọn. Eniyan rẹ sá ni wọ́n, ìwọ ni o sì ni wọ́n, ìwọ ni o kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó gbóná janjan bí iná ìléru. “OLUWA Ọlọrun, fi ojurere wo àwa iranṣẹ rẹ, àní àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, kí o sì gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́. OLUWA Ọlọrun, ìwọ ni o yà wọ́n sọ́tọ̀ láàrin gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé, pé kí wọ́n jẹ́ ìní rẹ, gẹ́gẹ́ bí o ti sọ fún wọn láti ẹnu Mose, iranṣẹ rẹ, nígbà tí ó kó àwọn baba ńlá wa jáde ní ilẹ̀ Ijipti.”

I. A. Ọba 8:22-53 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Solomoni sì dúró níwájú pẹpẹ OLúWA, níwájú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sókè ọ̀run. Ó sì wí pé: “OLúWA Ọlọ́run Israẹli, kò sí Ọlọ́run tí ó dàbí rẹ lókè ọ̀run tàbí ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ìwọ tí ó pa májẹ̀mú àti àánú mọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí ń fi gbogbo ọkàn wọn rìn níwájú rẹ. O sì ti pa ìlérí rẹ mọ́ fún ìránṣẹ́ rẹ Dafidi baba mi; pẹ̀lú ẹnu rẹ ni ìwọ ṣe ìlérí, o sì mú u ṣẹ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ, bí ó ti rí lónìí. “Ǹjẹ́ báyìí OLúWA Ọlọ́run Israẹli, bá ìránṣẹ́ rẹ̀ Dafidi baba mi pa ohun tí ìwọ ti ṣe ìlérí fún un mọ́ wí pé, ìwọ kì yóò kùnà láti ní ènìyàn kan láti jókòó níwájú mi lórí ìtẹ́ Israẹli, kìkì bí àwọn ọmọ rẹ bá lè kíyèsi ohun tí wọ́n ń ṣe láti máa rìn níwájú mi bí ìwọ ti rìn. Ǹjẹ́ báyìí, Ọlọ́run Israẹli, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tí o ti ṣe ìlérí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Dafidi baba mi wá sí ìmúṣẹ. “Ṣùgbọ́n nítòótọ́, Ọlọ́run yóò máa gbé ayé bí? Ọ̀run àti ọ̀run àwọn ọ̀run kò le gbà ọ́. Kí a má sọ pé ilé yìí tí mo kọ́ fún ọ! Síbẹ̀ ṣe ìfetísílẹ̀ àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ fún àánú, OLúWA Ọlọ́run mi. Gbọ́ ẹkún àti àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ń gbà níwájú rẹ lónìí. Jẹ́ kí ojú rẹ ṣí sí ilé yìí ní òru àti ní ọ̀sán, ibí yìí tí ìwọ ti wí pé, orúkọ mi yóò wà níbẹ̀, nítorí ìwọ yóò gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ gbà sí ibí yìí. Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ àti ti Israẹli, ènìyàn rẹ nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí ibí yìí. Gbọ́ láti ọ̀run wá láti ibùgbé rẹ, àti nígbà tí o bá gbọ́, dáríjì. “Nígbà tí ẹnìkan bá ṣẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀, tí a sì fi wá lé e láti mú un búra, bí ìbúra náà bá sì dé iwájú pẹpẹ rẹ ní ilé yìí, nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì ṣe. Kí o sì ṣèdájọ́ láàrín àwọn ìránṣẹ́ rẹ, dá ènìyàn búburú lẹ́bi, kí o sì mú wá sí orí òun tìkára rẹ̀ ohun tí ó ti ṣe, dá olóòtítọ́ láre, kí a sì fi ẹsẹ̀ àìlẹ́bi rẹ̀ múlẹ̀. “Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹ́gun Israẹli, ènìyàn rẹ, nítorí tí wọ́n ti ṣẹ̀ sí ọ, tí wọ́n bá yípadà sí ọ, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n sì gbàdúrà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ nínú ilé yìí nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli, ènìyàn rẹ̀ jì í, kí o sì mú wọn padà wá sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fún àwọn baba wọn. “Nígbà tí ọ̀run bá sé mọ́, tí kò sí òjò, nítorí tí àwọn ènìyàn rẹ ti ṣẹ̀ sí ọ, bí wọ́n bá gbàdúrà sí ìhà ibí yìí, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn nítorí tí ìwọ ti pọ́n wọn lójú, nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ jì wọ́n, à ní Israẹli, ènìyàn rẹ. Kọ́ wọn ní ọ̀nà tí ó tọ́ láti máa rìn, kí o sì rọ òjò sí ilẹ̀ tí ìwọ ti fi fún ènìyàn rẹ fún ìní. “Nígbà tí ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn bá wá sí ilẹ̀ náà, tàbí ìrẹ̀dànù tàbí ìmúwòdù, eṣú tàbí kòkòrò tí ń jẹ ni run, tàbí nígbà tí àwọn ọ̀tá bá dó tì wọ́n nínú àwọn ìlú wọn, irú ìpọ́njú tàbí ààrùnkárùn tó lè wá, nígbà tí àdúrà tàbí ẹ̀bẹ̀ bá ti ọ̀dọ̀ ẹnìkan láti ọ̀dọ̀ gbogbo Israẹli wá, tí olúkúlùkù sì mọ ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀, bí ó bá sì tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì sí ìhà ilé yìí, nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ. Dáríjì, kí o sì ṣe sí olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó ti ṣe, níwọ̀n ìgbà tí ìwọ mọ ọkàn rẹ̀, nítorí ìwọ nìkan ṣoṣo ni ó mọ ọkàn gbogbo ènìyàn, Nítorí wọn yóò bẹ̀rù rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọn yóò wà ní ilẹ̀ tí ìwọ fi fún àwọn baba wa. “Ní ti àwọn àlejò tí kì í ṣe Israẹli ènìyàn rẹ, ṣùgbọ́n tí ó ti ilẹ̀ òkèèrè jáde wá nítorí orúkọ rẹ, nítorí tí àwọn ènìyàn yóò gbọ́ orúkọ ńlá rẹ, àti ọwọ́ agbára rẹ, àti nínà apá rẹ, nígbà tí ó bá sì wá, tí ó sì gbàdúrà sí ìhà ilé yìí, nígbà náà ni kí o gbọ́ láti ọ̀run wá, ní ibùgbé rẹ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí àlejò náà yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ, kí gbogbo ènìyàn ní ayé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọn kí ó sì máa bẹ̀rù rẹ, gẹ́gẹ́ bí Israẹli, ènìyàn rẹ ti ṣe, kí wọn kí ó sì le mọ̀ pé orúkọ rẹ ni a fi pe ilé yìí tí mo kọ́. “Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ bá jáde lọ sí ogun sí àwọn ọ̀tá wọn, níbikíbi tí ìwọ bá rán wọn, nígbà tí wọ́n bá gbàdúrà sí OLúWA sí ìhà ìlú tí ìwọ ti yàn àti síhà ilé tí mo ti kọ́ fún orúkọ rẹ, nígbà náà ni kí o gbọ́ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì mú ọ̀rọ̀ wọn dúró. “Nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ sí ọ, nítorí kò sí ẹnìkan tí kì í ṣẹ̀, tí ìwọ sì bínú sí wọn, tí ìwọ sì fi wọ́n lé ọ̀tá lọ́wọ́, tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ wọn, jíjìnnà tàbí nítòsí; bí wọ́n bá ní ìyípadà ọkàn ní ilẹ̀ níbi tí a kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n bá sì ronúpìwàdà, tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ sí ọ ní ilẹ̀ àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, wí pé, ‘Àwa ti ṣẹ̀, àwa ti ṣe ohun tí kò tọ́, àwa ti ṣe búburú’; bí wọ́n bá sì fi gbogbo àyà àti gbogbo ọkàn wọn yípadà sí ọ, ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ sí ìhà ilẹ̀ wọn tí ìwọ ti fi fún àwọn baba wọn, Ìlú tí ìwọ ti yàn, àti ilé tí èmi kọ́ fún orúkọ rẹ; Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn ní ọ̀run, ní ibùgbé rẹ, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró. Kí o sì dáríjì àwọn ènìyàn rẹ, tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ; dárí gbogbo ìrékọjá wọn tí wọ́n ṣe sí ọ jì, kí o sì bá àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ wí, kí wọn kí ó lè ṣàánú fún wọn; nítorí ènìyàn rẹ àti ìní rẹ ni wọ́n, àwọn ẹni tí ìwọ ti mú ti Ejibiti jáde wá, láti inú irin ìléru. “Jẹ́ kí ojú rẹ ṣí sí ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, àti sí ẹ̀bẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ Israẹli, kí o sì tẹ́tí sílẹ̀ sí wọn nígbà tí wọ́n bá kégbe sí ọ. Nítorí tí ìwọ ti yà wọ́n kúrò nínú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, láti máa jẹ́ ìní rẹ, bí ìwọ ti sọ láti ọwọ́ Mose ìránṣẹ́ rẹ, nígbà tí ìwọ OLúWA Olódùmarè, mú àwọn baba wa ti Ejibiti jáde wá.”