ÀWỌN ỌBA KINNI 8:22-53

ÀWỌN ỌBA KINNI 8:22-53 YCE

Solomoni dúró níwájú pẹpẹ níwájú àwùjọ àwọn ọmọ Israẹli, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ mejeeji sókè. Ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura, ó ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kò sí Ọlọrun kan tí ó dàbí rẹ̀ lókè ọ̀run tabi ní ayé yìí, tíí máa pa majẹmu rẹ̀ mọ́, tíí sì máa fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí ń fi tọkàntọkàn gbọ́ràn sí i lẹ́nu. O ti mú ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi, ṣẹ. O ṣe ìlérí fún un nítòótọ́, o sì mú un ṣẹ lónìí. Ǹjẹ́ nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun Israẹli, mo bẹ̀ ọ́, mú àwọn ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi ṣẹ, pé, arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba ní Israẹli títí lae, bí wọ́n bá ṣọ́ra ní ọ̀nà wọn, tí wọ́n sì bá mi rìn bí ìwọ ti bá mi rìn. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli, mú ìlérí tí o ṣe fún iranṣẹ rẹ, Dafidi, baba mi ṣẹ. “Ṣugbọn, ǹjẹ́ ìwọ Ọlọrun lè gbé inú ayé yìí? Nítorí pé bí gbogbo ọ̀run ti tóbi tó, kò gbà ọ́; kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ilé ìsìn tí mo kọ́ fún ọ? OLUWA Ọlọrun mi, fi etí sí adura èmi iranṣẹ rẹ, kí o sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ̀ níwájú rẹ lónìí. Kí ojú rẹ lè máa wà lára ilé ìsìn yìí tọ̀sán-tòru, níbi tí o sọ pé o óo yà sọ́tọ̀ fún orúkọ rẹ. Kí o lè gbọ́ adura tí iranṣẹ rẹ ń gbà sí ibí yìí. Máa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ iranṣẹ rẹ ati adura àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, nígbà tí wọ́n bá kọjú sí ilé yìí, tí wọ́n sì gbadura, máa gbọ́ tiwa láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì máa dáríjì wá. “Bí ẹnìkan bá ṣẹ ọmọnikeji rẹ̀ tí wọ́n sì ní kí ó wá búra, tí ó bá wá tí ó sì búra níwájú pẹpẹ rẹ ninu ilé ìsìn yìí, OLUWA, gbọ́ lọ́run lọ́hùn-ún, kí o sì ṣe ìdájọ́ àwọn iranṣẹ rẹ. Jẹ ẹni tí ó bá jẹ̀bi ní ìyà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; dá ẹni tí ó bá jàre láre, kí o sì san ẹ̀san òdodo rẹ̀ fún un. “Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹgun àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, nítorí pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí ọ́, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bá tún yipada sí ọ, tí wọ́n jẹ́wọ́ orúkọ rẹ ninu ilé yìí, tí wọ́n gbadura sí ọ, tí wọ́n bẹ̀bẹ̀, gbọ́ adura wọn lọ́run lọ́hùn-ún, dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, kí o sì mú wọn pada wá sórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wọn. “Nígbà tí o kò bá jẹ́ kí òjò rọ̀, nítorí pé wọ́n ṣẹ̀ ọ́, tí wọ́n bá ronupiwada tí wọ́n sì kọjú sí ilé ìsìn yìí, tí wọ́n gbadura sí ọ, nígbà tí o bá jẹ wọ́n níyà, gbọ́ adura wọn lọ́run lọ́hùn-ún, dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji Israẹli, iranṣẹ rẹ, àní, àwọn eniyan rẹ, kí o sì kọ́ wọn ní ọ̀nà rere tí wọn yóo máa tọ̀; lẹ́yìn náà, rọ òjò sórí ilẹ̀ rẹ tí o fi fún àwọn eniyan rẹ bí ohun ìní. “Nígbà tí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ yìí, tabi tí àjàkálẹ̀ àrùn wà, tabi ìrẹ̀dànù èso, tabi tí ọ̀wọ́ eṣú, tabi tí àwọn kòkòrò bá jẹ ohun ọ̀gbìn oko run, tabi tí àwọn ọ̀tá bá dó ti èyíkéyìí ninu ìlú àwọn eniyan rẹ, tabi tí àìsàn, tabi àrùnkárùn kan bá wà láàrin wọn, gbọ́ adura tí wọ́n bá gbà, ati ẹ̀bẹ̀ tí ẹnikẹ́ni tabi gbogbo Israẹli, àwọn eniyan rẹ, bá bẹ̀, nítorí ìpọ́njú ọkàn olukuluku wọn. Tí wọ́n bá gbé ọwọ́ wọn sókè, tí wọ́n sì kọjú sí ilé ìsìn yìí, gbọ́ adura wọn láti ibùgbé rẹ lọ́run, dáríjì wọ́n, dá wọn lóhùn, kí o sì san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀, (nítorí ìwọ nìkan ni o mọ èrò ọkàn ọmọ eniyan); kí wọ́n lè máa bẹ̀rù rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n óo gbé lórí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá wọn. “Bákan náà, nígbà tí àlejò kan, tí kì í ṣe ọmọ Israẹli, bá wá láti ilẹ̀ òkèèrè nítorí orúkọ rẹ, (nítorí wọn óo gbọ́ òkìkí rẹ, ati iṣẹ́ ìyanu tí o ti ṣe fún àwọn eniyan rẹ); tí ó bá wá sìn ọ́, tí ó bá kọjú sí ilé yìí, tí ó gbadura, gbọ́ adura rẹ̀ láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì ṣe gbogbo ohun tí ó bá bèèrè fún un, kí gbogbo aráyé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọ́n sì lè bẹ̀rù rẹ bí àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan rẹ tí ń ṣe, wọn yóo sì mọ̀ pé ilé ìsìn rẹ ni ilé tí mo kọ́ yìí. “Nígbà tí àwọn eniyan rẹ bá lọ dojú kọ àwọn ọ̀tá wọn lójú ogun, níbikíbi tí o bá rán wọn lọ, tí wọ́n bá kọjú sí ìlú tí o yàn yìí, ati ilé ìsìn tí mo kọ́ fún ọ, tí wọ́n sì gbadura, gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run wá, kí o sì tì wọ́n lẹ́yìn. “Nígbà tí àwọn eniyan rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, (nítorí pé kò sí ẹni tí kì í dẹ́ṣẹ̀), tí o bá bínú sí wọn, tí o sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá ṣẹgun wọn, tí wọ́n sì kó wọn lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ mìíràn, kì báà jẹ́ ibi tí ó jìnnà tabi tòsí, bí wọ́n bá ronupiwada ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ọ, tí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá, ati ìwà burúkú tí wọ́n hù, tí wọ́n bá ronupiwada tọkàntọkàn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn tí ó kó wọn lẹ́rú, tí wọ́n bá kọjú sí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá wọn, ati ìlú tí o yàn yìí, ati ilé ìsìn tí mo kọ́ ní orúkọ rẹ, tí wọ́n bá gbadura sí ọ; gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì tì wọ́n lẹ́yìn. Dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, ati gbogbo àìdára tí wọ́n ṣe, kí o sì jẹ́ kí àwọn tí wọ́n kó wọn lẹ́rú ṣàánú wọn. Eniyan rẹ sá ni wọ́n, ìwọ ni o sì ni wọ́n, ìwọ ni o kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó gbóná janjan bí iná ìléru. “OLUWA Ọlọrun, fi ojurere wo àwa iranṣẹ rẹ, àní àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, kí o sì gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́. OLUWA Ọlọrun, ìwọ ni o yà wọ́n sọ́tọ̀ láàrin gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé, pé kí wọ́n jẹ́ ìní rẹ, gẹ́gẹ́ bí o ti sọ fún wọn láti ẹnu Mose, iranṣẹ rẹ, nígbà tí ó kó àwọn baba ńlá wa jáde ní ilẹ̀ Ijipti.”

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú ÀWỌN ỌBA KINNI 8:22-53