I. A. Ọba 5:1-18

I. A. Ọba 5:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

HIRAMU, ọba Tire, si rán awọn iranṣẹ rẹ̀ si Solomoni; nitoriti o ti gbọ́ pe, a ti fi ororo yàn a li ọba ni ipò baba rẹ̀: nitori Hiramu ti fẹràn Dafidi li ọjọ rẹ̀ gbogbo. Solomoni si ranṣẹ si Hiramu wipe, Iwọ mọ̀ bi Dafidi, baba mi, kò ti le kọ́ ile fun orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀ nitori ogun ti o wà yi i ka kiri, titi Oluwa fi fi wọn sabẹ atẹlẹsẹ rẹ̀. Ṣugbọn nisisiyi Oluwa Ọlọrun mi ti fun mi ni isimi niha gbogbo, bẹ̃ni kò si si ọta tabi ibi kan ti o ṣẹ̀. Si kiye si i, mo gbèro lati kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa Ọlọrun mi, gẹgẹ bi Oluwa ti sọ fun Dafidi, baba mi pe, Ọmọ rẹ, ti emi o gbe kà ori itẹ́ rẹ ni ipò rẹ, on ni yio kọ́ ile na fun orukọ mi. Njẹ nisisiyi, paṣẹ ki nwọn ki o ke igi kedari fun mi lati Lebanoni wá, awọn ọmọ ọdọ mi yio si wà pẹlu awọn ọmọ ọdọ rẹ, iwọ ni emi o si sanwo ọyà awọn ọmọ ọdọ rẹ fun, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti iwọ o wi: nitoriti iwọ mọ̀ pe, kò si ẹnikan ninu wa ti o mọ̀ bi a ti ike igi bi awọn ara Sidoni. O si ṣe, nigbati Hiramu gbọ́ ọ̀rọ Solomoni, o yọ̀ pipọ, o si wipe, Olubukún li Oluwa loni, ti o fun Dafidi ni ọmọ ọlọgbọ́n lori awọn enia pupọ yi. Hiramu si ranṣẹ si Solomoni pe, Emi ti gbọ́ eyi ti iwọ ránṣẹ si mi, emi o ṣe gbogbo ifẹ rẹ niti igi kedari ati niti igi firi. Awọn ọmọ ọdọ mi yio mu igi na sọkalẹ lati Lebanoni wá si okun: emi o si fi wọn ṣọwọ si ọ ni fifó li omi okun titi de ibi ti iwọ o nà ika si fun mi, emi o si mu ki nwọn ki o ko wọn sibẹ, iwọ o si ko wọn lọ: iwọ o si ṣe ifẹ mi, lati fi onjẹ fun ile mi. Bẹ̃ni Hiramu fun Solomoni ni igi kedari ati igi firi gẹgẹ bi gbogbo ifẹ rẹ̀. Solomoni si fun Hiramu ni ẹgbãwa oṣuwọ̀n ọkà ni onjẹ fun ile rẹ̀, ati ogún oṣuwọ̀n ororo daradara; bẹ̃ni Solomoni nfi fun Hiramu li ọdọdun. Oluwa si fun Solomoni li ọgbọ́n gẹgẹ bi o ti wi fun u: alafia si wà lãrin Hiramu ati Solomoni; awọn mejeji si ṣe adehùn. Solomoni ọba, si ṣà asìnrú enia jọ ni gbogbo Israeli; awọn asìnrú na jẹ ẹgbã mẹdogun enia. O si ràn wọn lọ si Lebanoni, ẹgbarun loṣoṣu, li ọwọ̀-ọwọ́; nwọn wà ni Lebanoni loṣu kan, nwọn a si gbe ile li oṣu meji: Adoniramu li o si ṣe olori awọn alasìnru na. Solomoni si ni ẹgbã marundilogoji enia ti nru ẹrù, ọkẹ mẹrin gbẹnagbẹna lori oke; Laikà awọn ijoye ninu awọn ti a fi ṣe olori iṣẹ Solomoni, ẹgbẹrindilogun o le ọgọrun enia, ti o nṣe alaṣẹ awọn enia ti nṣisẹ na. Ọba si paṣẹ, nwọn si mu okuta wá, okuta iyebiye, ati okuta gbígbẹ lati fi ipilẹ ile na le ilẹ. Awọn akọle Solomoni, ati awọn akọle Hiramu si gbẹ́ wọn, ati awọn ara Gebali: nwọn si pèse igi ati okuta lati kọ́ ile na.

I. A. Ọba 5:1-18 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí Hiramu, ọba Tire, gbọ́ pé Solomoni ni ó gun orí oyè lẹ́yìn baba rẹ̀, ó rán oníṣẹ́ sí i; nítorí ọ̀rẹ́ ni òun ati Dafidi, wọ́n sì fẹ́ràn ara wọn. Solomoni náà ranṣẹ pada sí Hiramu, ó ní, “Ìwọ náà mọ̀ pé Dafidi, baba mi, kò lè kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun rẹ̀ nítorí gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ni ó fi bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ tí wọ́n yí i ká jagun, títí tí OLUWA fi fún un ní ìṣẹ́gun lórí wọn. Ṣugbọn nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun mi ti fún mi ní alaafia ní gbogbo agbègbè tí ó yí mi ká. N kò ní ọ̀tá kankan rárá, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àjálù. Nisinsinyii, mo ti ṣe ìpinnu láti kọ́ ilé fún OLUWA Ọlọrun mi, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀ sí Dafidi, baba mi, pé ọmọ rẹ̀, tí yóo gun orí oyè lẹ́yìn rẹ̀, ni yóo kọ́ ilé ìsìn fún òun. Nítorí náà, pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ, kí wọ́n bá mi gé igi kedari ní Lẹbanoni. Àwọn iranṣẹ mi yóo bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀, n óo sì san iyekíye tí o bá bèèrè fún owó iṣẹ́ wọn. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ti mọ̀, àwọn iranṣẹ mi kò mọ̀ bí a tií gé igi ìkọ́lé bí àwọn ará Sidoni.” Inú ọba Hiramu dùn pupọ nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ Solomoni fún un. Ó ní, “Ẹni ìyìn ni OLUWA lónìí, nítorí pé ó fún Dafidi ní ọlọ́gbọ́n ọmọ, láti jọba lórí orílẹ̀-èdè ńlá yìí.” Ó ranṣẹ pada sí Solomoni, ó ní, “Mo gbọ́ iṣẹ́ tí o rán sí mi, n óo sì ṣe ohun tí o ní kí n ṣe fún ọ nípa igi kedari ati igi sipirẹsi. Àwọn iranṣẹ mi yóo gé igi náà ní Lẹbanoni, wọn yóo kó wọn wá sí etí òkun. Wọn óo dì wọ́n ní ìdì kọ̀ọ̀kan kí wọ́n lè tù wọ́n gba ojú òkun lọ sí ibikíbi tí o bá fẹ́. Wọn óo tú wọn kalẹ̀ níbẹ̀, wọn óo sì kó wọn fún àwọn iranṣẹ rẹ. Ohun tí mo fẹ́ kí o mójútó ni oúnjẹ tí èmi ati ìdílé mi óo máa jẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Hiramu ṣe tọ́jú gbogbo igi kedari ati igi sipirẹsi tí Solomoni nílò fún un. Ní ọdọọdún, Solomoni a máa fún Hiramu ní ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùnwọ̀n kori ọkà, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùnwọ̀n kori òróró dáradára fún ìtọ́jú oúnjẹ fún Hiramu ati àwọn eniyan rẹ̀. OLUWA fún Solomoni ní ọgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, alaafia sì wà láàrin òun ati Hiramu, àwọn mejeeji sì bá ara wọn dá majẹmu. Solomoni ọba ṣa ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) eniyan jọ lára àwọn ọmọ Israẹli, láti ṣe iṣẹ́ tipátipá. Ó fi Adoniramu ṣe alabojuto wọn. Ó pín wọn sí ọ̀nà mẹta: ẹgbaarun (10,000) ọkunrin ní ìpín kọ̀ọ̀kan. Ìpín kọ̀ọ̀kan a máa ṣiṣẹ́ fún oṣù kan ní Lẹbanoni, wọn á sì pada sílé fún oṣù meji. Solomoni sì tún ní ọ̀kẹ́ mẹrin (80,000) ọkunrin tí ń fọ́ òkúta ní agbègbè olókè; ati ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹgbaarun (70,000) ọkunrin tí ń ru òkúta tí wọ́n bá fọ́. Ó yan ẹẹdẹgbaaji ó lé ọọdunrun (3,300) ọkunrin, láti máa bojútó iṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Solomoni ọba, wọ́n fọ́ òkúta ńláńlá, wọ́n sì gbẹ́ wọn fún mímọ ìpìlẹ̀ ilé OLUWA náà. Àwọn òṣìṣẹ́ Solomoni ati ti Hiramu, ati àwọn ọkunrin mìíràn láti ìlú Gebali ni wọ́n gbẹ́ òkúta, tí wọ́n sì la igi fún kíkọ́ ilé OLUWA.

I. A. Ọba 5:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí Hiramu ọba Tire sì gbọ́ pé, a ti fi òróró yan Solomoni ní ọba ní ipò Dafidi baba rẹ̀, ó sì rán àwọn ikọ̀ rẹ̀ sí Solomoni, nítorí ó ti fẹ́ràn Dafidi ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo. Solomoni sì ránṣẹ́ yìí padà sí Hiramu pé: “Ìwọ mọ̀ pé Dafidi baba mi kò le kọ́ ilé fún orúkọ OLúWA Ọlọ́run rẹ̀, nítorí ogun tí ó wà yí i káàkiri, títí OLúWA fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí OLúWA Ọlọ́run mi ti fún mi ní ìsinmi ní ibi gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni kò sì sí ọ̀tá tàbí ìjàǹbá kan tí ó ṣe. Nítorí náà mo gbèrò láti kọ́ ilé fún orúkọ OLúWA Ọlọ́run mi, bí OLúWA ti sọ fún Dafidi baba mi, nígbà tí ó wí pé, ‘Ọmọ rẹ tí èmi yóò gbé ka orí ìtẹ́ rẹ ní ipò rẹ ni yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi.’ “Nítorí náà ni kí o pàṣẹ pé kí wọn kí ó gé igi kedari Lebanoni fún mi wá. Àwọn ènìyàn mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú tìrẹ, Èmi yóò sì san owó ọ̀yà tí ìwọ bá ránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn rẹ. Ìwọ mọ̀ pé, a kò ní ẹnìkan nínú wa tí ó mọ bí a ti ń gé igi bí àwọn ará Sidoni.” Nígbà tí Hiramu sì gbọ́ iṣẹ́ Solomoni, inú rẹ̀ sì dùn gidigidi, ó sì wí pé, “Ògo ni fún OLúWA lónìí, nítorí tí ó ti fún Dafidi ní ọlọ́gbọ́n ọmọ láti ṣàkóso àwọn ìlú ńlá yìí.” Hiramu sì ránṣẹ́ sí Solomoni pé: “Èmi ti gbọ́ iṣẹ́ tí ìwọ rán sí mi, èmi yóò sì ṣe gbogbo èyí tí o fẹ́ ní pípèsè igi kedari àti ní ti igi firi. Àwọn ènìyàn mi yóò mú igi náà sọ̀kalẹ̀ láti Lebanoni wá sí Òkun, èmi ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọ ní fífò lójú omi Òkun títí dé ibi tí ìwọ ó na ìka sí fún mi. Níbẹ̀ ni èmi yóò ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ìwọ yóò sì kó wọn lọ. Ìwọ yóò sì gba ìfẹ́ mi nípa pípèsè oúnjẹ fún ilé mi.” Báyìí ni Hiramu sì pèsè igi kedari àti igi firi tí Solomoni ń fẹ́ fún un, Solomoni sì fún Hiramu ní ẹgbàáwàá (20,000) òṣùwọ̀n ọkà oúnjẹ fún ilé rẹ̀, àti ogún (20) òṣùwọ̀n òróró dáradára. Solomoni sì ń tẹ̀síwájú láti ṣe èyí fún Hiramu lọ́dọọdún. OLúWA sì fún Solomoni ní ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún un. Ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà sì wà láàrín Hiramu àti Solomoni, àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn. Solomoni ọba sì ṣa asìnrú ènìyàn jọ ní gbogbo Israẹli; àwọn tí ń sìnrú náà jẹ́ ẹgbàá-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ènìyàn (30,000). Ó sì rán wọn lọ sí Lebanoni, ẹgbàárùn-ún (10,000) lóṣooṣù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lo oṣù kan ní Lebanoni, wọn a sì gbé ilé ní oṣù méjì. Adoniramu ni ó ṣe olórí àwọn asìnrú náà. Solomoni sì ní ẹgbàá-márùn-dínlógójì (70,000) ènìyàn tí ń ru ẹrù àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) gbẹ́nàgbẹ́nà lórí òkè, àti àwọn ìjòyè nínú àwọn tí a fi ṣe olórí iṣẹ́ Solomoni jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún ó-lé-ọgọ́rùn-ún (3,300) ènìyàn, tí ó ń ṣe aláṣẹ àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ náà. Ọba sì pàṣẹ, wọ́n sì mú òkúta wá, òkúta iyebíye, àti òkúta gbígbẹ́ láti fi ìpìlẹ̀ ilé náà lé ilẹ̀. Àwọn oníṣọ̀nà Solomoni àti Hiramu àti àwọn òṣìṣẹ́ láti Gebali sì gbẹ́ wọn, wọ́n sì pèsè igi àti òkúta láti fi kọ́ ilé náà.