ÀWỌN ỌBA KINNI 5

5
Solomoni Palẹ̀mọ́ láti Kọ́ Tẹmpili
(2Kron 2:1-18)
1Nígbà tí Hiramu, ọba Tire, gbọ́ pé Solomoni ni ó gun orí oyè lẹ́yìn baba rẹ̀, ó rán oníṣẹ́ sí i; nítorí ọ̀rẹ́ ni òun ati Dafidi, wọ́n sì fẹ́ràn ara wọn. 2Solomoni náà ranṣẹ pada sí Hiramu, 3ó ní, “Ìwọ náà mọ̀ pé Dafidi, baba mi, kò lè kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun rẹ̀ nítorí gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ni ó fi bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ tí wọ́n yí i ká jagun, títí tí OLUWA fi fún un ní ìṣẹ́gun lórí wọn. 4Ṣugbọn nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun mi ti fún mi ní alaafia ní gbogbo agbègbè tí ó yí mi ká. N kò ní ọ̀tá kankan rárá, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àjálù. 5Nisinsinyii, mo ti ṣe ìpinnu láti kọ́ ilé fún OLUWA Ọlọrun mi, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀ sí Dafidi, baba mi, pé ọmọ rẹ̀, tí yóo gun orí oyè lẹ́yìn rẹ̀, ni yóo kọ́ ilé ìsìn fún òun.#2Sam 7:12-13; 1Kron 17:11-12 6Nítorí náà, pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ, kí wọ́n bá mi gé igi kedari ní Lẹbanoni. Àwọn iranṣẹ mi yóo bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀, n óo sì san iyekíye tí o bá bèèrè fún owó iṣẹ́ wọn. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ti mọ̀, àwọn iranṣẹ mi kò mọ̀ bí a tií gé igi ìkọ́lé bí àwọn ará Sidoni.”
7Inú ọba Hiramu dùn pupọ nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ Solomoni fún un. Ó ní, “Ẹni ìyìn ni OLUWA lónìí, nítorí pé ó fún Dafidi ní ọlọ́gbọ́n ọmọ, láti jọba lórí orílẹ̀-èdè ńlá yìí.” 8Ó ranṣẹ pada sí Solomoni, ó ní, “Mo gbọ́ iṣẹ́ tí o rán sí mi, n óo sì ṣe ohun tí o ní kí n ṣe fún ọ nípa igi kedari ati igi sipirẹsi. 9Àwọn iranṣẹ mi yóo gé igi náà ní Lẹbanoni, wọn yóo kó wọn wá sí etí òkun. Wọn óo dì wọ́n ní ìdì kọ̀ọ̀kan kí wọ́n lè tù wọ́n gba ojú òkun lọ sí ibikíbi tí o bá fẹ́. Wọn óo tú wọn kalẹ̀ níbẹ̀, wọn óo sì kó wọn fún àwọn iranṣẹ rẹ. Ohun tí mo fẹ́ kí o mójútó ni oúnjẹ tí èmi ati ìdílé mi óo máa jẹ.”
10Bẹ́ẹ̀ ni Hiramu ṣe tọ́jú gbogbo igi kedari ati igi sipirẹsi tí Solomoni nílò fún un. 11Ní ọdọọdún, Solomoni a máa fún Hiramu ní ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùnwọ̀n kori ọkà, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùnwọ̀n kori òróró dáradára fún ìtọ́jú oúnjẹ fún Hiramu ati àwọn eniyan rẹ̀.
12OLUWA fún Solomoni ní ọgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, alaafia sì wà láàrin òun ati Hiramu, àwọn mejeeji sì bá ara wọn dá majẹmu.
13Solomoni ọba ṣa ẹgbaa mẹẹdogun (30,000) eniyan jọ lára àwọn ọmọ Israẹli, láti ṣe iṣẹ́ tipátipá. 14Ó fi Adoniramu ṣe alabojuto wọn. Ó pín wọn sí ọ̀nà mẹta: ẹgbaarun (10,000) ọkunrin ní ìpín kọ̀ọ̀kan. Ìpín kọ̀ọ̀kan a máa ṣiṣẹ́ fún oṣù kan ní Lẹbanoni, wọn á sì pada sílé fún oṣù meji.#1A. Ọba 12:18 15Solomoni sì tún ní ọ̀kẹ́ mẹrin (80,000) ọkunrin tí ń fọ́ òkúta ní agbègbè olókè; ati ọ̀kẹ́ mẹta ó lé ẹgbaarun (70,000) ọkunrin tí ń ru òkúta tí wọ́n bá fọ́. 16Ó yan ẹẹdẹgbaaji ó lé ọọdunrun (3,300) ọkunrin, láti máa bojútó iṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́. 17Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Solomoni ọba, wọ́n fọ́ òkúta ńláńlá, wọ́n sì gbẹ́ wọn fún mímọ ìpìlẹ̀ ilé OLUWA náà. 18Àwọn òṣìṣẹ́ Solomoni ati ti Hiramu, ati àwọn ọkunrin mìíràn láti ìlú Gebali ni wọ́n gbẹ́ òkúta, tí wọ́n sì la igi fún kíkọ́ ilé OLUWA.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÀWỌN ỌBA KINNI 5: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀